Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ile Iṣọ Feb. 15
“Bí wọ́n bá ní kó o yan ẹni tó o fẹ́ kó ṣàkóso ayé, ta lo máa yàn? [Jẹ́ kó fèsì.] Ilé Ìṣọ́ yìí jíròrò àwọn nǹkan tá a fi lè dá Mèsáyà mọ̀, ìyẹn ẹni tí Ọlọ́run yàn láti ṣàkóso ayé. Ó tún ṣàlàyé ohun tí ìṣàkóso rẹ̀ máa túmọ̀ sí fáráyé.” Ka Aísáyà 9:6, 7.
Ile Iṣọ Mar. 1
“Èyí tó pọ̀ láàárín àwa èèyàn ló gbà pé ó yẹ ká nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì wa bí Jésù ṣe pa á láṣẹ nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí. [Ka Jòhánù 13:34, 35.] Bó bá wá rí bẹ́ẹ̀, ibo la ti lè rí àwọn tó ń fi ẹ̀kọ́ tí Jésù kọ́ni yìí ṣèwà hù nígbèésí ayé wọn? [Jẹ́ kó fèsì.] Ìwé ìròyìn yìí jíròrò bá a ṣe lè dá ojúlówó Kristẹni mọ̀ lóde òní.”
Jí Jan.–Mar.
“Ṣó o ti ronú rí nípa bí ọjọ́ iwájú ẹ̀dá èèyàn ṣe máa rí? [Jẹ́ kó fèsì.] Bíbélì fún wa láwọn ẹ̀rí tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ tá a fi lè gbà gbọ́ pé ọ̀la ń bọ́ wá dùn bí oyin. [Ka Dáníẹ́lì 2:44.] Ìwé ìròyìn yìí jẹ́ ká mọ ohun tí Ọlọ́run máa ṣe nípasẹ̀ Ìjọba rẹ̀ fáwọn tó bá ṣègbọràn sí i.”
“Ǹjẹ́ o mọ̀ pé ó ti pẹ́ gan-an tí Bíbélì ti sọ̀rọ̀ nípa àjàkálẹ̀ àrùn tó gbalé gbòde lásìkò wa yìí? [Ka Lúùkù 21:11. Kó o wá jẹ́ kó fèsì.] Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ pé àjàkálẹ̀ àrùn á máa jà láwọn ọjọ́ ìkẹyìn jẹ́ ká mọ̀ pé dájúdájú, ewu ńbẹ. Síbẹ̀, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ìrètí ṣì wà.” Fi àpilẹ̀kọ tó wà lójú ìwé 20 sí 21 hàn án.