Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ile Iṣọ Jan. 15
“Láti bí ọdún mélòó kan sẹ́yìn báyìí, àwọn èèyàn ti túbọ̀ ń fẹ́ láti mọ̀ nípa àwọn áńgẹ́lì. Ṣé ìwọ náà ti ń wá bó o ṣe máa mọ irú ẹni tí wọ́n jẹ́ àti ipa tí wọ́n ń kó nínú ìgbésí ayé wa? [Jẹ́ kó fèsì. Lẹ́yìn náà ka Sáàmù 34:7.] Ìwé ìròyìn yìí jíròrò ohun tí Bíbélì sọ nípa ohun táwọn áńgẹ́lì ti ṣe rí, ohun tí wọ́n ń ṣe lọ́wọ́ àtohun tí wọ́n máa ṣe lọ́jọ́ iwájú.”
Jí! Jan.–Mar.
“Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé lórí gbogbo ọ̀ràn làwọn èèyàn ti nímọ̀ràn tí wọ́n lè fúnni. Mélòó nínú ìmọ̀ràn yẹn lo rò pé ó yẹ kéèyàn gbẹ́kẹ̀ lé? [Jẹ́ kó fèsì. Lẹ́yìn náà, ka 2 Tímótì 3:16.] Jí! yìí jẹ́ ká mọ ìdí tí Bíbélì fi jẹ́ ibi tó dára jù lọ tá a ti lè rí ìmọ̀ràn tó ṣeé múlò.” Fi àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ lójú ìwé 22 hàn án.
Ile Iṣọ Feb. 1
“Gbogbo wa la mọ̀ pé owó la fi ń ṣayé. Ṣùgbọ́n ǹjẹ́ o rò pé kò ní dáa ká ṣọ́ra fún ewu tí ẹsẹ Bíbélì yìí mẹ́nu bà? [Ka 1 Tímótì 6:10, kó o sì jẹ́ kó fèsì.] Ilé Ìṣọ́ yìí ràn wá lọ́wọ́ láti mọ díẹ̀ lára àwọn ọ̀fìn tó wà nínú kéèyàn ní ọrọ̀ ó sì tún jíròrò ọ̀nà tá a lè gbà tá ò fi ní jìn sáwọn ọ̀fìn náà.”