Ohun Tí O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ilé Ìṣọ́ Jan. 15
“Nítorí pé ó wọ́pọ̀ pé àwọn ènìyàn kì í mú ìlérí wọn ṣẹ lóde òní, ọ̀pọ̀ ènìyàn kì í fẹ́ gbẹ́kẹ̀ lé ẹnikẹ́ni mọ́. Ǹjẹ́ o rò pé ẹnì kankan wà tá a lè gbẹ́kẹ̀ lé ìlérí rẹ̀? [Jẹ́ kí ó fèsì. Lẹ́yìn náà ka Jóṣúà 23:14.] Ìwé ìròyìn yìí fi bí a ṣe lè gbẹ́kẹ̀ lé àwọn ìlérí Ọlọ́run tó wà nínú Bíbélì hàn.”
Ilé Ìṣọ́ Feb. 1
“Ọ̀pọ̀ jù lọ wa la máa ń sapá láti bójú tó ìlera wa. Àmọ́ àwọn ìwádìí tí wọ́n ṣe lẹ́nu àìpẹ́ yìí fi hàn pé bí ipò tẹ̀mí wa bá ṣe rí náà tún máa ń nípa lórí bí ìlera wa ṣe máa dára tó. Ǹjẹ́ o rò pé ó lè rí bẹ́ẹ̀ lóòótọ́? [Jẹ́ kí ó fèsì. Lẹ́yìn náà ka Mátíù 5:3.] Ilé Ìṣọ́ yìí ṣàlàyé nípa bá a ṣe lè bójú tó àìní wa nípa tẹ̀mí.”
Jí! Feb. 8
“Ọwọ́ ọ̀pọ̀ ènìyàn dí lónìí tó bẹ́ẹ̀ tí wọn kì í ráyè sinmi tó bó ṣe yẹ. Bóyá ìwọ náà yóò gbà pé ọ̀rọ̀ gidi lọ̀rọ̀ yìí tí wọ́n ti kọ sílẹ̀ ní ohun tó ju ẹgbẹ̀ẹ́dógún [3,000] ọdún sẹ́yìn. [Ka Oníwàásù 4:6. Lẹ́yìn náà jẹ́ kí ó fèsì.] Ìtẹ̀jáde Jí! yìí ṣàlàyé púpọ̀ nípa bá a ṣe lè mọ̀ bóyá oorun tí à ń sùn tó tàbí kò tó àti bá a ṣe lè bójú tó ìṣòro àìsùn dáadáa.”
“Bí orúkọ Ọlọ́run ṣe rí rèé lédè Hébérù. [Fi hàn án lójú ewé 16.] Àwọn èèyàn kan gbà pé kò yẹ ká máa pe orúkọ náà jáde lẹ́nu. Àwọn mìíràn sì máa ń lò ó fàlàlà. Ìtẹ̀jáde Ji! yìí yiiri apá méjèèjì yìí wò. Ó sì tún ṣàlàyé bá a ṣe lè fi orúkọ Ọlọ́run mọ́ ọ̀n.” Ka Sáàmù 83:18.