Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ile Iṣọ Jan. 15
“Ibo lo rò pé àwọn tọkọtaya ti lè rí àmọ̀ràn tí kì í bà á tì? [Jẹ́ kó fèsì.] Kíyè sí ẹni tí ẹsẹ Bíbélì yìí sọ pé ó dá ìgbéyàwó sílẹ̀. [Ka Jẹ́nẹ́sísì 2:22.] Ọlọ́run tún sọ ọwọ́ tó yẹ kí ọkọ àti aya máa fi mú ojúṣe wọn ní àyè pàtàkì tó fi wọ́n sí. Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé wà nínú ìwé ìròyìn yìí.”
Ile Iṣọ Feb. 1
“Ṣó o rò pé àdúgbò wa yìí á dùn gbé jù báyìí lọ bí gbogbo èèyàn bá lè máa ṣe ohun tí ẹsẹ Bíbélì yìí sọ? [Ka Éfésù 4:25, kó o wá jẹ́ kó fèsì.] Ọ̀pọ̀ èèyàn ló rò pé kò sóhun tó burú nínú kéèyàn máa parọ́ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé àwọn àǹfààní tó wà nínú kéèyàn máa sọ òtítọ́ ní gbogbo ìgbà.”
Jí! Jan.-Mar.
“Ǹjẹ́ o ti ṣàkíyèsí pé ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni aláfẹnujẹ́ kì í tẹ̀ lé ẹ̀kọ́ Jésù? [Jẹ́ kó fèsì.] Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ ni kì í ṣe ohun tí Jésù sọ níbí yìí. [Ka Jòh. 13:35.] Àpilẹ̀kọ yìí jíròrò ìyàtọ̀ tó wà nínú ẹ̀kọ́ Jésù àti èrò ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni aláfẹnujẹ́.” Fi àpilẹ̀kọ tó wà lójú ìwé 26 hàn án.
“Ẹ jọ̀ọ́, kí lèrò yín lórí ohun tí Jésù sọ nínú ẹsẹ Bíbélì yìí? [Ka Jòh. 18:36.] Kí nìdí tí Jésù ò fi gbà pé ìjà ló yẹ kéèyàn máa fi yanjú èdèkòyédè? [Jẹ́ kó fèsì.] Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé ìdí táwọn Kristẹni fi gbọ́dọ̀ jìnnà sí ìwà jàgídíjàgan kí wọ́n má sì ṣe lọ́wọ́ sí rògbòdìyàn ọ̀rọ̀ òṣèlú tó gbòde kan lónìí.” Fi àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ ní ojú ìwé 26 hàn án.