Ohun Tí O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ilé Ìṣọ́ Jan. 15
“Lójú gbogbo ìtàjẹ̀sílẹ̀ tó ń ṣẹlẹ̀ báyìí, ǹjẹ́ o ronú pé ibi ti borí ire? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Gbọ́ ohun tí Bíbélì sọ nípa Ọlọ́run. [Ka Sáàmù 83:18b.] Níwọ̀n bí Ọlọ́run ti jẹ́ Ẹni Gíga Jù Lọ lórí ilẹ̀ ayé, ṣé lóòótọ́ ni ibi lè borí? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́ yìí pèsè ìdáhùn tí ń tẹ́ni lọ́rùn sí ìbéèrè yẹn.”
Ilé Ìṣọ́ Feb. 1
“Ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí ló ń ṣàníyàn nítorí àìníṣẹ́lọ́wọ́, ìnira tí àwọn mìíràn sì ń rí lẹ́nu iṣẹ́ kì í ṣe kékeré rárá. Ǹjẹ́ o rò pé ó ṣeé ṣe láti ní ìfọ̀kànbalẹ̀ àti ayọ̀ lẹ́nu iṣẹ́? [Jẹ́ kí ó fèsì. Lẹ́yìn náà ka Aísáyà 65:21-23.] Ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́ yìí sọ̀rọ̀ nípa àkókò kan nígbà tí gbogbo èèyàn yóò máa ṣe iṣẹ́ tó lérè nínú.”
Jí! Feb. 8
“Kò tíì sí ìgbà kankan nínú ìtàn tí ààbò àwa èèyàn wà nínú ewu tó ti àkókò yìí. Ohun kan tó tún ń ba àwọn èèyàn lẹ́rù báyìí ni ìṣòro bí wọ́n ṣe máa ń jí àwọn nǹkan ìdánimọ̀ ẹni. Ǹjẹ́ o ti gbọ́ nípa ìyẹn? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Bíbélì ṣèlérí pé lọ́jọ́ kan, ayé wa yìí máa bọ́ lọ́wọ́ gbogbo àwọn ohun tí kò jẹ́ ká ní ìfọ̀kànbalẹ̀. [Ka Aísáyà 11:9.] Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé bí èyí yóò ṣe rí bẹ́ẹ̀.”
“Ìtẹ̀jáde Jí! yìí sọ̀rọ̀ nípa nǹkan ìbànújẹ́ kan tó ń ṣẹlẹ̀ lákòókò wa yìí, ìyẹn ni kí àwọn ọmọdé máa ṣe iṣẹ́ aṣẹ́wó. Lílo àwọn ọmọdé lọ́nà tó ń bani nínú jẹ́ yìí jẹ́ ohun kan tí Bíbélì ṣèlérí pé ó máa tó dópin. [Ka Òwe 2:21, 22.] Ìwé ìròyìn yìí sọ ohun tó ń mú kí àwọn èèyàn máa ṣe àwọn ọmọdé níṣekúṣe bẹ́ẹ̀ àti bí òpin yóò ṣe dé bá a.”