ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 2/03 ojú ìwé 8
  • Ohun Tí O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ohun Tí O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2007
  • Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
  • Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2008
  • Ohun Tí O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2004
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
km 2/03 ojú ìwé 8

Ohun Tí O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn

Ilé Ìṣọ́ Feb. 15

“Àwọn èèyàn kan máa ń wò ó pé bóyá ni Ọlọ́run tiẹ̀ wà lóòótọ́. Àwọn kan sọ pé Ọlọ́run wà àmọ́ pé ó jìnnà sí àwọn. Ǹjẹ́ o ti ronú nípa kókó yìí rí? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Wo ìdí tí mímọ irú ẹni tí Ọlọ́run jẹ́ dáadáa fi ṣe pàtàkì gan-an. [Ka Jòhánù 17:3.] Lórí kókó yìí, wàá rí i pé àwọn àpilẹ̀kọ tó ṣáájú nínú ìtẹ̀jáde yìí á gbádùn mọ́ ọ gan-an.”

Ilé Ìṣọ́ Mar. 1

“A óò fẹ́ láti mọ èrò rẹ lórí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó gbàfiyèsí yìí. [Ka Mátíù 5:10.] Báwo ni wọ́n ṣe lè máa ṣe inúnibíni sí ẹnì kan kí onítọ̀hún sì máa yọ̀? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Àwọn àpilẹ̀kọ méjì àkọ́kọ́ nínú ìwé ìròyìn yìí sọ nípa àwọn kan tí wọ́n láyọ̀ láìka ohun tí wọ́n là kọjá sí. Wàá fẹ́ láti kà nípa bí wọ́n ṣe ṣe é.”

Jí! Mar. 8

“Ǹjẹ́ o rò pé ète Ọlọ́run ni pé kí àwọn ẹ̀dá èèyàn, títí kan àwọn ọmọdé, máà rí oúnjẹ tó dára tó jẹ? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Wo ìlérí tó ń tuni nínú yìí tá a rí nínú Bíbélì. [Ka Sáàmù 72:16.] Ìtẹ̀jáde Jí! yìí jíròrò àwọn ohun tó ń fa ìṣòro àìsí oúnjẹ tó dára tó, àti ní pàtàkì, ìlérí Ọlọ́run láti fòpin sí i láìpẹ́.”

“Ǹjẹ́ o gbà pé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìgbésí ayé kún fún ìṣòro, a ṣì ní ìdí láti máa dúpẹ́. [Jẹ́ kí ó fèsì.] Ìdí kan tó fi yẹ ká máa ṣọpẹ́ ni ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà dá ara wa. [Ka Sáàmù 139:14.] O ò rí i pé ó yẹ ká kún fún ọpẹ́ pé a ní àwọn ẹ̀ya ara tá a nílò láti mọyì ìgbésí ayé, gẹ́gẹ́ bí ìtẹ̀jáde Jí! yìí ti ṣàlàyé!”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́