Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ile Iṣọ Feb. 1
“Ipa wo lo rò pé ẹsẹ Bíbélì yìí máa ní lórí àwọn ìdílé tó bá fàwọn ìlànà tó wà nínú ẹ̀ sílò? [Ka Éfésù 4:31. Lẹ́yìn náà jẹ́ kó fèsì.] Àwọn àbá látinú Bíbélì tá a lè fi yanjú èdèkòyédè nínú ìdílé tó sì máa mú kí ìdílé láyọ̀ ló wà nínú àpilẹ̀kọ yìí.” Fi àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ lójú ìwé 18 hàn án.
Ile Iṣọ Mar. 1
“Jọ̀wọ́, màá fẹ́ gbọ́ ohun tó o ní í sọ nípa ẹsẹ Ìwé Mímọ́ táwọn èèyàn mọ̀ bí ẹni mowó yìí. [Ka Jòhánù 3:16.] Ṣé ó ti ṣe ẹ́ rí bíi kó o béèrè pé báwo ni ikú ọkùnrin kan ṣoṣo ṣe lè mú káwọn tó kù wà láàyè títí láé? [Jẹ́ kó fèsì.] Ìwé ìròyìn yìí ṣe àwọn àlàyé tó ṣe kedere lórí àǹfààní tá a lè rí látinú ikú Jésù.”
Jí! Jan.–Mar.
“Láyé àtijọ́, àwọn èèyàn máa ń jẹ́ kí Bíbélì tọ́ àwọn sọ́nà. Ṣùgbọ́n lóde òní ọ̀pọ̀ ní kò dá àwọn lójú pé ìrànlọ́wọ́ wà nínú Bíbélì. Kí lèrò ẹ? [Jẹ́ kó fèsì, kó o wá ka 2 Tímótì 3:16.] Àwọn ẹ̀rí tí kò ṣeé já ní koro pé Ọlọ́run ló mí sí Bíbélì wà nínú àpilẹ̀kọ tó wà lójú ìwé 12 nínú Jí! yìí.”
“Ìrírí ti fi hàn pé àwọn obìnrin ti jìyà nítorí ìwà ipá àti bí àwọn èèyàn ṣe ń tẹ̀ wọ́n mẹ́rẹ̀. Kí lo rò pó fà á? [Jẹ́ kó fèsì.] Gbọ́ àṣẹ tó wà nínú Bíbélì nípa bó ṣe yẹ káwọn ọkọ máa bá àwọn aya wọn lò. [Ka 1 Pétérù 3:7.] Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé ohun tí Bíbélì sọ nípa ojú tí Ọlọ́run àti Kristi fi ń wo àwọn obìnrin.”