Ìgbàgbọ́ Tó Lágbára Lèyí!
1. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń kó ìdààmú báni wo ni Jésù sọ tẹ́lẹ̀?
1 Àwọn àpọ́sítélì fetí sílẹ̀ dáadáa bí Jésù ti ń sọ̀rọ̀ nípa wíwàníhìn-ín rẹ̀ àti ìparí ètò àwọn nǹkan. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń kó ìdààmú báni máa tó dé bá aráyé, irú bí ogun, àìtó oúnjẹ, ìmìtìtì ilẹ̀ àti àjàkálẹ̀ àrùn. Jésù wá sọ pé àwọn èèyàn máa kórìíra àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun, wọ́n máa rí ìpọ́njú wọ́n á sì pa wọ́n. Àwọn wòlíì èké máa wà, wọ́n sì máa ṣi ọ̀pọ̀lọpọ̀ lọ́nà. Ìfẹ́ ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa di tútù.
2. Kí nìdí tó fi jẹ́ ohun tó ṣàrà ọ̀tọ̀ pé à ń wàásù kárí ayé?
2 Bí àwọn àpọ́sítélì ṣe ń gbọ́ àwọn ohun tí Jésù sọ yìí, ó ti ní láti yà wọ́n lẹ́nu gan-an nígbà tí Jésù wá sọ pé, ìwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ní gbogbo ilẹ̀ ayé tá à ń gbé máa wáyé. (Mát. 24:3-14) À ń rí báwọn àsọtẹ́lẹ̀ wọ̀nyí ṣe ń ní ìmúṣẹ lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀ lóde òní. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn àkókò líle koko la wà yìí, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń fìtara wàásù ìhìn rere náà. Bí ìfẹ́ ti ń jó rẹ̀yìn nínú ayé, bẹ́ẹ̀ ni iná ìfẹ́ tiwa ń jó ròkè lala. Láìka pé “gbogbo orílẹ̀-èdè” ló kórìíra wa sí, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo orílẹ̀-èdè la ti ń wàásù.
3. Kí lohun tó fún ẹ níṣìírí nínú ìròyìn iṣẹ́ ìsìn kárí ayé?
3 Ẹ ò rí i bí inú wa ti dùn tó láti ṣàyẹ̀wò ìgbòkègbodò àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fún ti ọdún iṣẹ́ ìsìn tó kọjá bó ṣe wà nínú àtẹ tó wà lójú ìwé 3 sí 6! Ó ti tó ọdún mẹ́rìndínlógún léraléra báyìí tá a ti máa ń lo ohun tó ju bílíọ̀nù kan wákàtí lọ lẹ́nu iṣẹ́ wíwàásù àti sísọni dọmọ ẹ̀yìn. Ìgbàgbọ́ tó lágbára gan-an mà lèyí o! Bá a bá fi ìròyìn yìí wéra pẹ̀lú ti ọdún iṣẹ́ ìsìn tó ṣáájú èyí, iye àwọn aṣáájú-ọ̀nà fi nǹkan bí ìdá mẹ́fà nínú ọgọ́rùn-ún pọ̀ sí i, ó lé ní ìdá mẹ́ta nínú ọgọ́rùn-ún tí iye àwọn akéde fi lé sí i, ó lé ní ìdá mẹ́rin nínú ọgọ́rùn-ún tí iye ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tá a darí fi gbé pẹ́ẹ́lí sí i, nígbà tí iye àwọn tó ṣèrìbọmi pàápàá lé ní ìdá ogún nínú ọgọ́rùn-ún. Ohun amóríyá ló jẹ́ láti rí i pé, ju ti ìgbàkigbà rí lọ nínú ìtàn, iye èèyàn tó ń fi tọkàntọkàn jọ́sìn Jèhófà ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ̀nù méje báyìí! Bó o ti ń yẹ àtẹ náà wò, kí lohun tó o rí tó fún ẹ níṣìírí jù lọ?
4. Àwọn ìṣòro wo ni ọkùnrin kan borí rẹ̀ kó tó lè ṣèrìbọmi?
4 Òótọ́ ni pé bí ìròyìn yìí ṣe gbé pẹ́ẹ́lí mórí ẹni wú, àmọ́ ẹ máà jẹ́ ká gbàgbé pé àwọn èèyàn tó ti fẹ̀rí hàn pé àwọ́n nígbàgbọ́ lẹ́nìkọ̀ọ̀kan ni ìròyìn náà ń ṣojú fún. Àpẹẹrẹ kan rèé: Orílẹ̀-èdè Bolivia ni Guillermo dàgbà sí. Ọdún 1935 ni wọ́n bí i, látìgbà tó sì ti wà lọ́mọ ọdún mẹ́sàn-án ló ti máa ń ṣiṣẹ́ nínu oko tí wọ́n gbin ewé tí wọ́n fi ń ṣe kokéènì sí. Látìgbà yẹn ló sì ti máa ń jẹ ewé ọ̀hún kó má bàa rẹ̀ ẹ́ tẹnutẹnu torí iṣẹ́ alágbára tó ń ṣe. Ìgbà tó yá, ó bẹ̀rẹ̀ sí mu ọtí lámujù, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí mu sìgá. Bó ti bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ohun tí Jèhófà fẹ́ kó ṣe, Guillermo fi sìgá mímu sílẹ̀, kò sì mu ọtí lámujù mọ́. Olórí ìṣòro rẹ̀ wá ni bó ṣe máa jáwọ́ nínú àṣà jíjẹ ewé tó ní èròjà kokéènì nínú tó ti mọ́ ọn lára. Ó gbàdúrà láìsinmi, ó sì bọ́ lọ́wọ́ àṣà yìí. Lẹ́yìn tó fi gbogbo ìwàkíwà tó kún ọwọ́ rẹ̀ sílẹ̀ tán, ó ṣèrìbọmi. Ó sọ pé, “Ní báyìí, inú mi dùn gan-an, mo sì mọ̀ nínú ara mi pé mo mọ́ tónítóní.”
5. Kí ló ń wu ìwọ náà?
5 Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwa èèyàn lóòótọ́. Ó wù ú pé kí gbogbo èèyàn ronú pìwà dà. (2 Pét. 3:9) Ohun táwa náà sì ń fẹ́ nìyẹn. Ǹjẹ́ ká máa bá a nìṣó láti máa fi tinútinú ṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe láti ran àwọn olóòótọ́ ọkàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè wá mọ Jèhófà, kí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ bí àwa pẹ̀lú ti ṣe.