Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
Àwọn ìbéèrè àtúnyẹ̀wò tó wà nísàlẹ̀ yìí la óò gbé yẹ̀ wò ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run lọ́sẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ní February 25, 2008. Àtúnyẹ̀wò yìí dá lórí àwọn iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ tá a ṣe lọ́sẹ̀ January 7 sí February 25, 2008, alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ yóò sì darí rẹ̀ fún ọgbọ̀n ìsẹ́jú.
ÀNÍMỌ́ Ọ̀RỌ̀ SÍSỌ
1. Kí la gbọ́dọ̀ ṣe ká lè ran àwọn tí à ń bá sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ láti lóye ohun tí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan ń sọ, kì nìdí tó sì fi yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀? [be-YR ojú ìwé 228 ìpínrọ̀ 2 sí 3]
2. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì ká gbé ọ̀rọ̀ wa kalẹ̀ lọ́nà tí àwùjọ á fi rí ẹ̀kọ́ nínú rẹ̀, báwo la sì ṣe lè ṣe èyí? [be-YR ojú ìwé 230 ìpínrọ̀ 3 sí 5, àpótí]
3. Àwọn ọ̀nà wo ni ṣíṣe ìwádìí á fi mú kí ọ̀rọ̀ wa jẹ́ èyí táwọn èèyàn túbọ̀ rí ẹ̀kọ́ kọ́ nínú rẹ̀? [be-YR ojú ìwé 231 ìpínrọ̀ 1 sí 3]
4. Kí la lè ṣe tí àwùjọ á fi túbọ̀ rí ẹ̀kọ́ kọ́ nínú àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí wọ́n ti mọ̀ dunjú? [be-YR ojú ìwé 231 ìpínrọ̀ 4 sí 5]
5. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì ká ṣàlàyé àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a bá kà? [be-YR ojú ìwé 232 ìpínrọ̀ 3 sí 4]
IṢẸ́ AKẸ́KỌ̀Ọ́ KÌÍNÍ
6. Nínú Ìwàásù Jésù Lórí Òkè, kí lohun tó sọ nínú Mátíù 5:22 túmọ̀ sí? [w89-YR 7/15 ojú ìwé 25 ìpínrọ̀ 1]
7. Báwo la ṣe lè múra ọkàn wa sílẹ̀ láti gba ìtọ́ni lọ́dọ̀ Ọlọ́run nígbà tí olùbánisọ̀rọ̀ bá ń bá wa sọ̀rọ̀? (2 Kíró. 20:33) [be-YR ojú ìwé 13 ìpínrọ̀ 4 sí ojú ìwé 14 ìpínrọ̀ 5]
8. Kí làwọn òbí lè ṣe láti kọ́ àwọn ọmọ wọn kí wọ́n lè di “ọlọ́gbọ́n fún ìgbàlà”? (2 Tím. 3:15) [be-YR ojú ìwé 16 ìpínrọ̀ 3 sí 4]
9. Ọ̀nà wo la lè gbà fi ohun tí Jésù sọ nínú Mátíù 9:16, 17 sílò? [w89-YR 7/15 ojú ìwé 25 ìpínrọ̀ 3]
10. Kí nìdí táwọn ọkùnrin tó gbé alárùn ẹ̀gbà kan wá fi ní láti dá òrùlé lu? (Máàkù 2:4) [w89-YR 10/15 ojú ìwé 30 ìpínrọ̀ 5]
BÍBÉLÌ KÍKÀ Ọ̀SỌ̀Ọ̀SẸ̀
11. Ṣé fífi ìbínú sọ̀rọ̀ ìṣáátá síni burú ju kéèyàn máa bá a lọ ní kíkún fún ìrunú? (Mát. 5:21, 22) [w08-YR 1/15 “Ọ̀rọ̀ Jèhófà Yè—Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Mátíù”]
12. Ọ̀nà wo làwọn Kristẹni ń gbà jẹ́ kí ‘ojú wọn mú ọ̀nà kan’? (Mát. 6:22, 23) [w06-YR 10/1 ojú ìwé 29]
13. Kí ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó béèrè lọ́wọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Òye gbogbo nǹkan wọ̀nyí ha yé yín bí?” (Mát. 13:51, 52) [w08-YR 1/15 “Ọ̀rọ̀ Jèhófà Yè—Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Mátíù”]
14. Kí nìdí tí Jésù fi sábà máa ń pàṣẹ fáwọn tó bá wò sàn “láti má ṣe fi òun hàn kedere”? (Mát. 12:16) [w87-YR 5/15 ojú ìwé 9; cl-YR ojú ìwé 93 sí 94]
15. Kí ni Jésù fẹ́ ká mọ̀ nígbà tó sọ nípa “òṣùwọ̀n” tí èèyàn bá fi “díwọ̀n fúnni”? (Máàkù 4:24, 25) [w80-YR 12/15 ojú ìwé 15 gt-YR orí 43]