Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tá a ó lò lóṣù February: Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé. March: Ẹ lo ìwé Kí ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Ẹ sapá gidigidi láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. April àti May: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! la ó lò. Ẹ sapá lákànṣe láti ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn ẹni tó ṣẹ̀ṣẹ̀ fìfẹ́ hàn tó wá síbi Ìrántí Ikú Kristi tí wọ́n sì tún wá gbọ́ àkànṣe àsọyé àmọ́ tí wọn kì í wá sípàdé ìjọ déédéé. Ìdí tẹ́ ẹ fi fẹ́ padà bẹ̀ wọ́n wò ni láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn tí kò tíì bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
◼ Níwọ̀n bí oṣù March ti ní òpin ọ̀sẹ̀ márùn-ún, ó máa dáa gan-an láti fi ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́.
◼ Kí akọ̀wé àti alábòójútó iṣẹ́ ìsìn ṣàyẹ̀wò ìgbòkègbodò gbogbo àwọn aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Bó bá ṣòro fún èyíkéyìí lára wọn láti ní iye wákàtí tó yẹ kó ròyìn, kí àwọn alàgbà ṣètò láti ràn án lọ́wọ́.
◼ Ẹṣin ọ̀rọ̀ àkànṣe àsọyé fún gbogbo èèyàn ní àkókò Ìrántí Ikú Kristi ti ọdún 2008 ni “Ta Ló Kúnjú Ìwọ̀n Láti Ṣàkóso Aráyé?” Ẹ wo ìfilọ̀ tó jọ èyí nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti September 2007.