Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ile Iṣọ Feb. 15
“Èrò àwọn kan ni pé aráyé ti bayé jẹ́ tán. Ǹjẹ́ ìwọ náà ti ronú nípa ìyẹn rí? [Jẹ́ kó fèsì.] Ìwọ gbọ́ ìlérí tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ yìí. [Ka Ìṣípayá 11:18.] Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé ohun tó mú kí orí ilẹ̀ ayé wa yìí ṣàrà ọ̀tọ̀. Ó sì jẹ́ ká mọ ohun tí Bíbélì sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀ sí ayé yìí lọ́jọ́ iwájú.”
Ile Iṣọ Mar. 1
“Ìgbàgbọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn ni pé gbogbo ẹ̀sìn ni Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà. Ǹjẹ́ o rò pé ẹ̀sìn tó bá ṣáà ti wu èèyàn lèèyàn lè ṣe? [Jẹ́ kó fèsì.] Ìwọ wo ìmọ̀ràn yìí ná. [Ka 1 Jòhánù 4:1.] Ìwé ìròyìn yìí jíròrò bá a ṣe lè mọ̀ àwọn ẹ̀kọ́ tí Ọlọ́run fọwọ́ sí. Ó sì tún ṣàlàyé bí onírúurú ìsìn tó wà lónìí ṣe bẹ̀rẹ̀.”
Jí! Jan.-Mar.
“Ọ̀pọ̀ èèyàn rò pé ìgbà táwọn bá lọ sọ́run làwọn máa tó bọ́ lọ́wọ́ ìrora àti àìsàn. Ṣó o ti ronú bẹ́ẹ̀ rí? [Jẹ́ kó fèsì.] Inú rẹ á dùn láti mọ̀ pé ọ̀rọ̀ ò rí báwọn èèyàn ṣe rò ó o. Ohun tí Bíbélì sọ ni pé gbogbo aráyé á láǹfààní láti wà láàyè títí láé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé.” [Ka Sáàmù 37:11.] Lẹ́yìn náà, fi àpilẹ̀kọ́ tó bẹ̀rẹ̀ lójú ìwé 10 hàn án.
“Kí ni díẹ̀ lára àwọn ìṣòro tó ń bá àwọn ọ̀dọ́ fínra lóde òní? [Jẹ́ kó fèsì.] Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé ọ̀kan lára irú àwọn ìṣòro bẹ́ẹ̀, ìyẹn níní ìbálòpọ̀ ṣáájú ìgbéyàwó. [Ka 1 Kọ́ríńtì 6:9, 10.] Báwọn méjì bá ń bára wọn lò pọ̀ láìtíì tọwọ́ bọ̀wé àdéhùn ìgbéyàwó, àgbèrè ni wọ́n ń bára wọn ṣe! Àti pàápàá, yàtọ̀ sí pé èèyàn á kan àbùkù, ó tún lè mú kéèyàn kó àrùn, kéèyàn lóyún tí ò fẹ́, ó sì lè kó ẹ̀dùn ọkàn bá èèyàn. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, ẹ̀ṣẹ̀ sí ìlànà òdodo Ọlọ́run ni. Ìwé ìròyìn yìí jẹ́ ká rí ìdí tó fi jẹ́ pé ìbálòpọ̀ ṣáájú ìgbéyàwó kì í ṣe ọ̀nà táwọn tó ń gbèrò àtifẹ́ra lè gbà fi hàn pé àwọn nífẹ̀ẹ́ ara àwọn dénúdénú.”