Ohun Tí O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ile Ìṣọ́ Feb. 15
“Ọ̀pọ̀ èèyàn làwọn ohun burúkú táwọn èèyàn ń fi ẹ̀sìn bojú ṣe ń kó ìdààmú bá. Àwọn kan rò pé ìsìn ló ń fa ìṣòro ọmọ aráyé. Ǹjẹ́ o tíì ronú nípa èyí rí? [Jẹ́ kó fèsì. Lẹ́yìn náà ka Ìṣípayá 18:24.] Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé ohun tí Bíbélì sọ nípa ọ̀ràn yìí.”
Ile Ìṣọ́ Mar. 1
“Lákòókò kan, wọ́n béèrè lọ́wọ́ Jésù Kristi pé: ‘Èwo ni èkíní nínú gbogbo àṣẹ?’ Kíyè sí ìdáhùn rẹ̀. [Ka Máàkù 12:29, 30.] Ǹjẹ́ o tíì ronú rí nípa ohun tí Jésù ní lọ́kàn? [Jẹ́ kó fèsì.] Àpilẹ̀kọ náà, ‘Àwọn Ọ̀nà Tá A Lè Gbà Fi Hàn Pé A Nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run’ ṣàlàyé ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ táwọn èèyàn mọ̀ dáadáa yẹn.”
Jí! Mar. 8
“Nígbà kan, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń bẹ̀rù pé ogun ọ̀gbálẹ̀gbáràwé lè wáyé. Ǹjẹ́ o rò pé ó ṣeé ṣe kí ogun ọ̀gbálẹ̀gbáràwé bẹ́ sílẹ̀ lóde òní? [Jẹ́ kó fèsì.] Ìwé ìròyìn yìí sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ní lọ́ọ́lọ́ọ́, tó kan gbogbo wa. Ó tún ṣàlàyé nípa ìlérí tó wà nínú Bíbélì pé ìbẹ̀rù yóò di ohun àtijọ́.” Ka Sefanáyà 3:13.