Ohun Tí O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ile Iṣọ Feb. 15
“Lọ́pọ̀ ìgbà, a máa ń gbọ́ pé àwọn kan ṣe iṣẹ́ ìyanu. [Sọ àpẹẹrẹ kan.] Àwọn èèyàn kan máa ń gba àwọn ìròyìn wọ̀nyí gbọ́. Ṣùgbọ́n àwọn mìíràn máa ń ṣiyèméjì. Ìwé ìròyìn yìí á jẹ́ kó o mọ̀ bóyá lóòótọ́ làwọn iṣẹ́ ìyanu tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ wáyé àti pé bóyá irú àwọn ohun bẹ́ẹ̀ ṣì ń ṣẹlẹ̀ lónìí.” Ka Jeremáyà 32:21.
Ile Iṣọ Mar. 1
“Ǹjẹ́ o rò pé ayé yóò dára ju bó ṣe wà yìí lọ bí gbogbo èèyàn bá tẹ̀ lé ìmọ̀ràn yìí? [Ka Róòmù 12:17, 18. Lẹ́yìn náà jẹ́ kó fèsì.] Ó ṣeni láàánú pé, nígbà míì èdèkòyédè máa ń wáyé. Ìwé ìròyìn yìí ṣàlàyé bí fífi ìmọ̀ràn Bíbélì sílò ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti yanjú ìṣòro tó bá wà láàárín àwa àtàwọn èèyàn kí àlàáfíà lè jọba.”
Jí Mar. 8
áyé ìgbàanì, Ọlọ́run pàṣẹ pé kí àwọn ọmọ máa bọlá fún ìyá wọn àti bàbá wọn. [Ka Ẹ́kísódù 20:12.] Ǹjẹ́ o rò pé àwọn èèyàn ń bọlá fún àwọn ìyá bó ṣe yẹ lóde òní? [Jẹ́ kó fèsì.] Ìwé ìròyìn yìí sọ̀rọ̀ lórí ohun tí ojú àwọn ìyá ń rí ní orílẹ̀-èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ àti bí wọ́n ṣe ń ṣe ojúṣe wọn ní àṣeyege.”