Bíbélì Ni Yóò Túbọ̀ Máa Tẹnu Mọ́!
1. Nítorí àwọn wo la fi bẹ̀rẹ̀ sí tẹ ìwé ìròyin Ilé Ìṣọ́, nítorí àwọn wo la sì ṣe bẹ̀rẹ̀ sí tẹ ìwé ìròyìn The Golden Age?
1 Ní October 1, ọdún 1919 la kọ́kọ́ tẹ ìwé ìròyìn The Golden Age. Ó sì jẹ́ irin iṣẹ́ tó wúlò gbáà fún iṣẹ́ ìwàásù. Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀? Nítorí pé a dìídì ṣe é fún gbogbo ènìyàn ni. Àmọ́ ti Ilé Ìṣọ́ yàtọ̀ síyẹ̀n, torí pé ọ̀pọ̀ ọdún la fi kà á sí ìwé ìròyìn tó wà fún “agbo kékeré.” (Lúùkù 12:32) Nígbà tá a bẹ̀rẹ̀ sí tẹ ìwé ìròyìn The Golden Age, àwọn akéde Ìjọba Ọlọ́run fẹ́ràn àtimáa gbà á gan-an tó fi jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ọdún ni ìye ìwé ìròyìn náà tá à ń tẹ̀ fi ju ti Ilé Ìṣọ́ lọ fíìfíì.
2. Kí lorúkọ tá à ń pe ìwé ìròyìn The Golden Age báyìí, kí sì nìdí tá a fi ń tẹ̀ ẹ́ látìbẹ̀rẹ̀?
2 À ń tẹ ìwé ìròyìn The Golden Age káwọn èèyàn bàa lè mọ̀ pé Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi tó máa tó mú sànmánì aláásìkí wá fáráyé nìkan ló lè yanjú àwọn ìṣòro tó ń bá aráyé fínra. Bí ọdún ti ń gorí ọdún, àwọn ìyípadà mélòó kan dé bá ìwé ìròyìn The Golden Age kó bàa lè máa ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ sí i bí ìgbà ṣe ń yí padà. Lọ́dún 1937, a yí orúkọ rẹ̀ padà sí Consolation. Lọ́dún 1946 la bẹ̀rẹ̀ sí pè é ní Jí!, ìyẹn sì lorúkọ tá a fi ń pè é títí dòní.
3. Nínú ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ wo ni ìwé ìròyìn Jí! ti ń kópa ribiribi?
3 Látìgbà tá a ti ń tẹ ìwé ìròyìn yìí, ó ti kópa ribiribi nínú iṣẹ́ ìjẹ́rìí ńláǹlà tá a ti ń ṣe bọ̀ látọdún 1919. (Mát. 24:14) Àmọ́ ṣá o, nítorí pé àkókò káńjúkáńjú la wà yìí, ó dà bíi pé ó bọ́gbọ́n mu kí ìyípadà díẹ̀ sí i bá ìwé ìròyìn Jí!
4. (a) Kí lẹnì kan gbọ́dọ̀ ṣe bó bá fẹ́ la “ọjọ́ ìbínú Jèhófà” já? (b) Bí ìwé Ìṣípayá 14:6, 7 ṣe sọ, kí ni “áńgẹ́lì . . . tí ń fò ní agbedeméjì ọ̀run” ń ké sí gbogbo èèyàn láti ṣe?
4 Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn ló gbádùn àtimáa ka Jí! nítorí pé ó máa ń sọ̀rọ̀ lórí onírúurú kókó tó yàtọ̀ sí ọ̀ràn ìsìn lọ́nà tó fani mọ́ra. Ó dájú pé èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn tó máa ń wá síbi Ìrántí Ìkú Kristi lọ́dọọdún ló máa ń ka ìwé ìròyìn Jí! déédéé. Síbẹ̀, bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ la “ọjọ́ ìbínú Jèhófà” já, ó máa nílò ìrànlọ́wọ kó má bàa fọ̀rọ̀ ara rẹ̀ mọ sórí kíka àwọn ìtẹ̀jáde wa déédéé.—Sef. 2:3; Ìṣí. 14:6, 7.
5. (a) Láti January, ọdún 2006, kí ni Jí! yóò túbọ̀ máa tẹnu mọ́? (b) Kí lèyí lè ran àwọn èèyàn púpọ̀ sí i lọ́wọ́ láti ṣe, èyí á sì mú àsọtẹ́lẹ̀ wo ṣẹ?
5 Nítorí èyí, bẹ̀rẹ̀ láti oṣù January, ọdún 2006, ìwé ìròyìn Jí! á túbọ̀ máa tẹnu mọ́ ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Ní tààràtà lá á túbọ̀ máa gba àwọn tó ń kà á níyànjú láti máa ka Bíbélì kí wọ́n bàa lè rí ojútùú sáwọn ìṣòro wọn. Yóò sì túbọ̀ máa tẹnu mọ́ àlàyé tí Bíbélì ṣe lórí àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́ nínú ayé. Lọ́nà yìí, àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́ nínú ayé á túbọ̀ máa yé àwọn tó ń ka ìwé ìròyìn náà dáadáa, bóyá ìyẹn á sì lè jẹ́ kí ohun tí wọ́n ń kà ràn wọ́n lọ́wọ́ tí wọ́n á fi fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa Jèhófà.—Sek. 8:23.
6, 7. (a) Báwo ni Jí! á ṣe máa mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn fojú ohun tó wà nínú 1 Tẹsalóníkà 2:13 wo ìwé ìròyìn náà? (b) Báwo la ó ṣe máa tẹ Jí! jáde lemọ́lemọ́ tó, èdè mélòó sì ni ìyípadà yìí máa bá?
6 Ìwé ìròyìn Jí! á ṣì máa bá a nìṣó láti sọ̀rọ̀ lórí onírúurú kókó ẹ̀kọ́ tó faní lọ́kàn mọ́ra. Àmọ́, Bíbélì ni yóò máa tẹnu mọ́ jù lọ. (1 Tẹs. 2:13) Àti pé níwọ̀n bí Ilé Iṣọ́ ti máa ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì tó jinlẹ̀ tí Jí! á sì wá máa ní àpilẹ̀kọ púpọ̀ sí i tó dá lórí Ìwé Mímọ́, kò dà bí ohun tó pọn dandan pé ká ṣì máa tẹ Jí! lẹ́ẹ̀mejì lóṣù. Nítorí náà, látorí ìtẹ̀jáde ti oṣù January, ọdún 2006, Jí! máa di ìtẹ̀jáde ẹlẹ́ẹ̀kan lóṣù. Èyí á mú káwọn iṣẹ́ tó jẹ mọ́ kíkọ àwọn ìwé wa, títúmọ̀ wọn sí èdè mìíràn, àti kíkó wọn ránṣẹ́ sáwọn ìjọ tàbí sáwọn ilẹ̀ mìíràn rọrùn sí i.
7 Ìyípadà yìí á bá nǹkan bí ìdá ogójì nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn èdè tá a fi ń tẹ Jí! Títi di báyìí, ìtẹ̀jáde ẹlẹ́ẹ̀kan lóṣù tàbí ẹlẹ́ẹ̀kan lóṣù mẹ́ta ni Jí! lọ́pọ̀ èdè. A ó máa tẹ Ilé Ìṣọ́ bíi ti tẹ́lẹ̀.
8. Ọ̀nà wo làwọn akéde lè gbà lo Jí! àti Ilé Ìṣọ́ papọ̀?
8 Àwọn akéde lè máa lo Jí! tó bá jáde lóṣù pẹ̀lú Ilé Ìṣọ́ tó bá kọ́kọ́ jáde tàbí èyí tó bá jáde ṣìkejì lóṣù yẹn. Àwọn tó bá sì ń fi Jí! ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí á lè lo ìtẹ̀jáde kan náà yẹn jálẹ̀ oṣù láìsí pé wọ́n ń yí bí wọ́n ṣe ń gbọ́rọ̀ kalẹ̀ padà bí oṣù bá dé ìdajì, báa ti ń ṣe nísinsìnyí.
9. Kí ni Jí! á máa bá a nìṣó láti ṣe?
9 Látìgbà tí ìwé ìròyìn yìí ti kọ́kọ́ jáde lọ́dún 1919 tá a ti fàwọn orúkọ bíi The Golden Age, Consolation àti Jí! mọ̀ ọ́n, ó ti ṣe bẹbẹ fún wa nínú iṣẹ́ ìwàásù. Àdúra wa ni pé kí Jèhófà máa bá a nìṣó láti fìbùkún rẹ̀ sórí ìwé ìròyìn náà bá ó ṣe máa tẹ̀ ẹ́ jáde lákọ̀tun àti bá ó ṣe máa mú un tọ àwọn èèyàn lọ. Kí Jèhófà sì tún jẹ́ kó lè ran àwọn èèyàn púpọ̀ sí i láti “gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ènìyàn àti ahọ́n” lọ́wọ́ kí wọ́n lè gbàgbọ́ pé Ìjọba Ọlọ́run nìkan lọ̀nà àbájáde kan ṣoṣo fún wọn.—Ìṣí. 7:9.