Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní March 14
Orin 132
8 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Àwọn ìfilọ̀ tá a mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìlàjì oṣù March sílẹ̀. Bí àwọn àbá tó wà ní ojú ìwé 4 bá ṣeé lò ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín, fi wọ́n ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo Ilé Ìṣọ́ March 15 àti Jí! April 8. (Lo àbá kẹta fún Jí! April 8.) Ẹ tún lè gbọ̀rọ̀ kalẹ̀ lọ́nà mìíràn tẹ́ ẹ bá fẹ́ lo ìwé ìròyìn náà. Nínú ọ̀kan lára àwọn àṣefihàn náà, fi hàn bá a ṣe lè ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ ẹni tó máa ń gba ìwé ìròyìn wa déédéé. Bí àṣefihàn náà bá ń parí lọ, lo àkọlé tó wà lẹ́yìn ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ March 15 láti rán onílé létí Ìrántí Ikú Kristi tó ń bọ̀ lọ́nà.
20 min: “Bíbélì Ni Yóò Túbọ̀ Máa Tẹnu Mọ́!”a
17 min: “Ìgbòkègbodò Àkànṣe Láti Mú Ìwé Pẹlẹbẹ Tuntun Tọ Àwọn Èèyàn Lọ.”b Alábòójútó iṣẹ́ ìsìn ni kó bójú tó o. Ṣe àṣefihàn tá a dámọ̀ràn nípa bá a ó ṣe lo ìwé pẹlẹbẹ náà. Nínú ọ̀kan lára àṣefihàn náà, onílé ò fi bẹ́ẹ̀ fìfẹ́ hàn sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí Ẹlẹ́rìí sọ fún un, nítorí náà Ẹlẹ́rìí fún un ní ìwé àṣàrò kúkúrú dípò ìwé pẹlẹbẹ.
Orin 69 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní March 21
Orin 140
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ.
15 min: “Bí A Ṣe Lè Darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Tí Yóò Máa Tẹ̀ Síwájú—Apá Keje.”c Bó o bá ń múra iṣẹ́ yìí sílẹ̀, lo Ilé Ìṣọ́ July 15, 2002, ojú ìwé 27, ìpínrọ̀ 5 sí 6.
20 min: Kí Ni Amágẹ́dọ́nì? Lẹ́yìn ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tí kò tó ìṣẹ́jú kan, lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó apá yìí. A gbé e karí Ilé-Ìṣọ́nà May 15, 1990, ojú ìwé 3 sí 7. Ní kí àwọn ará dáhùn àwọn ìbéèrè tó wà níbi ìsọ̀rí ọ̀rọ̀ inú àpilẹ̀kọ náà, kó o sì lo àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a fà yọ àtàwọn tá a tọ́ka sí.
Orin 109 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní March 28
Orin 144
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ka ìròyìn ìnáwó àti lẹ́tà tí ọ́fíìsì kọ láti dúpẹ́. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìparí oṣù March sílẹ̀. Rọ àwọn ará láti pe àwọn olùfìfẹ́hàn wá síbi àkànṣe àsọyé fún gbogbo ènìyàn, èyí tí yóò wáyé ní April 10. Mẹ́nu kan ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tá a máa fi sóde lóṣù April àti May.
15 min: Àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.
20 min: Ẹ Fi Ìwé Ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Ṣiṣẹ́ Lóde Ẹ̀rí. Ṣàlàyé àwọn àbá nípa bá a ṣe lè mú kí ìwé ìròyìn tá à ń fi sóde pọ̀ sí i. Àwọn àbà náà wà lójú ìwé 8 nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti February 2005. Sọ̀rọ̀ lórí àwọn kókó tá a lè fi nasẹ̀ ọ̀rọ̀ nínú àwọn ìwé ìròyìn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde. Bí àwọn àbá tó wà ní ojú ìwé 4 bá ṣeé lò ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín, lò wọ́n láti fi ṣe àṣefihàn bá a ṣe lo Ilé Ìṣọ́ April 1 àti Jí! April 8. (Lo àbá kẹrin fún Jí! April 8.) O tún lè gbọ́rọ̀ kalẹ̀ lọ́nà mìíràn tó bá bá àdúgbò yín mu tẹ́ ẹ bá fẹ́ lo ìwé ìròyìn náà. Nínú àwọn àṣefihàn náà, ṣàlàyé ọ̀nà tá a gbà ń rówó bójú tó iṣẹ́ tá à ń ṣe kárí ayé.—Wo ojú ìwé 2 nínú ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ tàbí ojú ìwé 5 nínú ìwé ìròyìn Jí!
Orin 116 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní April 4
Orin 119
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ.
15 min: Ẹ Ní Ìfẹ́ Láàárín Ara Yín. (Jòhánù 13:35) Kí alàgbà kan sọ àsọyé lórí ẹṣin ọ̀rọ̀ yìí tá a gbé karí Ilé Ìṣọ́ February 1, 2003, ojú ìwé 15 sí 18, ìpínrọ̀ 10 sí 21. Gbìyànjú láti kọ́ àwọn tó ti ka ìwé Ìmọ̀ àti ìwé pẹlẹbẹ Béèrè tẹ́lẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́ síwájú sí i. Tẹnu mọ́ bí àwọn akéde ṣe lè fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn alàgbà láti ran àwọn tó jẹ́ aláìlera nípa tẹ̀mí lọ́wọ́.
20 min: Àwọn ìrírí táwọn akéde ní. Sọ pé kí àwọn ará sọ àwọn ìrírí tí wọ́n gbádùn nígbà tí wọ́n padà lọ sọ́dọ̀ àwọn tó gba ìwé pẹlẹbẹ Ẹ Máa Ṣọ́nà! Múra àtiṣe àṣefihàn àwọn ìrírí tó bá fani mọ́ra gan-an. Dúpẹ́ lọ́wọ́ gbogbo àwọn ará fún bí wọ́n ṣe kọ́wọ́ ti ìgbòkègbodò àkànṣe náà lẹ́yìn.
Orin 137 àti àdúrà ìparí.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.
b Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.
c Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.