Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tá ó lò ní March 1 sí 20: Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. March 21 sí April 17: A ó lo ìwé pẹlẹbẹ Ẹ Máa Ṣọ́nà! fún ìgbòkègbodò àkànṣe. April 18 sí 30, àti May: Ẹ lo Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Bẹ́ ẹ bá padà lọ sọ́dọ̀ àwọn tó fìfẹ́ hàn, tó fi mọ́ àwọn tó wá síbi Ìrántí Ikú Kristi tàbí àwọn ìpàdé ìjọ mìíràn, ṣùgbọ́n tí wọn ò tíì máa wá sí ìpàdé déédéé, ìwé Jọ́sìn Ọlọ́run Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Náà ni kí ẹ fún wọn. Ẹ sapá ní gbogbo ọ̀nà kẹ́ ẹ lè bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, pàápàá báwọn kan bá ti kẹ́kọ̀ọ́ ìwé Ìmọ̀ àti ìwé pẹlẹbẹ Béèrè tẹ́lẹ̀. June: Ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà ni kẹ́ ẹ lò. Báwọn kan bá sì sọ pé àwọn kì í ṣe òbí, ẹ lè fún wọn ní ìwé pẹlẹbẹ Béèrè. Ẹ gbìyànjú láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
◼ Gbàrà tí ìjọ bá ti gba Ilé Ìṣọ́ àti Jí! tuntun ni kẹ́ ẹ ti kó wọn sóde káwọn ará lè rí i gbà. Ìyẹn á jẹ́ káwọn akéde tètè ka àwọn àpilẹ̀kọ inú àwọn ìwé ìròyìn náà kó tó di pé wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí lò wọ́n lóde ẹ̀rí. Gbàrà tí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa náà bá ti tẹ̀ yín lọ́wọ́ ni kẹ́ ẹ ti pín wọn fáwọn ará. Ẹ tiẹ̀ lè pín wọn fáwọn akéde ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ pàápàá.
◼ Nígbàkigbà tẹ́nì kan bá fẹ́ lọ sí ìpàdé ìjọ, àpéjọ àkànṣe tàbí ti àyíká, tàbí àpéjọ àgbègbè lórílẹ̀-èdè mìíràn, ẹ̀ka ọ́fíìsì tó ń bójú tó iṣẹ́ wa lórílẹ̀-èdè náà ni kí onítọ̀hún kọ̀wé sí. Ọwọ́ wọn ni kó ti béèrè ọjọ́ àti àkókò tí ìpàdé tàbí àpéjọ náà yóò wáyé àti ibi tí wọ́n á ti ṣe é. Ibi tá a tó àdírẹ́sì ẹ̀ka ọ́fíìsì sí wà lójú ewé tó gbẹ̀yìn nínú ìwé ọdọọdún wa, ìyẹn Yearbook tọdún yìí.
◼ Kí àwọn akọ̀wé ìjọ máa rí i pé Ìwé Ìwọṣẹ́ Ìsìn Aṣáájú Ọ̀nà Déédéé (S-205) àti Ìwé Ìwọṣẹ́ Ìsìn Aṣáájú Ọ̀nà Olùrànlọ́wọ́ (S-205b) tó pọ̀ tó wà lọ́wọ́. Ẹ lè fi fọ́ọ̀mù Literature Request Form (S-14) béèrè fún wọn. Kẹ́ ẹ rí i pé, ó kéré tán, ìjọ ní èyí tá á tó lò fún ọdún kan lọ́wọ́.
◼ Ọjọ́ Thursday, March 24, ọdún 2005 la ó ṣe Ìrántí Ikú Kristi. Bó bá jẹ́ pé ọjọ́ Thursday lẹ máa ń ṣe ìpàdé yín, ẹ ṣe é ní ọjọ́ mìíràn nínú ọ̀sẹ̀ bí àyè bá máa wà ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Bí kò bá ṣeé ṣe táwọn ohun kan sì wà nínú Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn tó kan ìjọ yín gbọ̀ngbọ̀n, ẹ lè fi apá yẹn kún ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn míì.
◼ Láti ọ̀sẹ̀ June 27, 2005, ìwé tí a óò máa kà ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ ni Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì!
◼ Àkànṣe àsọyé fún gbogbo ènìyàn ti àkókò Ìrántí Ikú Kristi tọdún 2005, yóò wáyé ní Sunday, April 10. Àkòrí àsọyé náà yóò jẹ́ “Kí Nìdí Tí Jésù Fi Jìyà àti Ìdí Tó Fi Kú?” Bí ìjọ yín bá ní ìbẹ̀wò alábòójútó àyíká tàbí tí ẹ óò bá lọ sí àpéjọ àkànṣe tàbí ti àyíká ní ọjọ́ tí a sọ yìí, kí ẹ sọ àsọyé náà ní ọ̀sẹ̀ tí yóò tẹ̀ lé e. Kí ìjọ èyíkéyìí má ṣe sọ àsọyé náà ṣááju Sunday, April 10, 2005.
◼ Àwòkẹ́kọ̀ọ́ Àtẹ́tísí Tá A Ṣe Sórí Ike Pẹlẹbẹ Èyí Tó Wà Lọ́wọ́ Báyìí:
Mímọrírì Ogún Tẹ̀mí Tá A Ní—Gẹ̀ẹ́sì
Ṣiṣe Ohun tí Ó Tọ́ Ni Ojú Jehofa—Gẹ̀ẹ́sì
Awọn Idajọ Jehofah Lodisi Awọn Eniyan Olùṣàyàgbàǹgbà-Pòfinníjà—Gẹ̀ẹ́sì
Gbígba Àmì-Àkíyèsí fun Lilaaja—Gẹ̀ẹ́sì
Titọju Iwalaaye Pamọ ni Akoko Ìyàn—Gẹ̀ẹ́sì
◼ Ní àwọn àpéjọ àyíká àti àpéjọ àkànṣe tí yóò wáyé lọ́dún 2005, a ó ya ibì kan sọ́tọ̀ fáwọn adití láwọn àyíká tá a tò sísàlẹ̀ yìí. Ibi tá a bá sì yà sọ́tọ̀ fún wọn yìí la ó ti túmọ̀ gbogbo ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà sí Èdè Àwọn Adití ní Ìlànà ti Amẹ́ríkà:
Akabo (EE-08) May 14 àti February 26-27
Àkúrẹ́ (WE-12) June 4 àti March 26-27
Badagry (WE-02) July 23 àti April 2-3
Badagry (WE-04) June 11 àti February 5-6
Badagry (WE-23) June 12 àti February 12-13
Calabar (EE-21) February 12 àti June 11-12
Dálùwọ́n (WE-03) May 14 àti August 6-7
Dálùwọ́n (WE-13) April 9 àti September 3-4
Ẹnúgu (EE-17) April 3 àti January 8-9
Ìbàdàn (WE-09) July 30 àti May 7-8
Igwuruta Ali (EE-22) February 12 àti June 11-12
Iléṣà (WE-15) February 6 àti July 23-24
Kàdúná (NE-01b) July 3 àti March 19-20
Ọ̀tà (WE-05) July 2 àti April 9-10
Ọ̀tà (WE-06) July 16 àti February 12-13
Ọ̀tà (WE-07) July 17 àti April 2-3
Ọ̀tà (WE-25) July 3 àti April 23-24
Ùbogò (ME-07) February 13 àti September 3-4
Ùlì (EE-24) July 31 àti April 23-24