ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 1/06 ojú ìwé 3-4
  • Sí Àwọn Òǹkàwé Wa

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Sí Àwọn Òǹkàwé Wa
  • Jí!—2006
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bíbélì Ni Yóò Túbọ̀ Máa Tẹnu Mọ́!
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
  • “Kí Ni Ìdáhùn Rẹ?”
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2007
  • Sí Ẹ̀yin Òǹkàwé Wa
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Ilé-Ìṣọ́nà àti Jí!—Àwọn Àkànṣe Ìwé-Ìròyìn Òtítọ́ Bíbọ́sákòókò
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
Àwọn Míì
Jí!—2006
g 1/06 ojú ìwé 3-4

Sí Àwọn Òǹkàwé Wa

BẸ̀RẸ̀ látorí ìtẹ̀jáde yìí, àyípadà díẹ̀ máa bá ohun táá máa jáde nínú ìwé ìròyìn Jí! Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn nǹkan kan á yàtọ̀, ọ̀pọ̀ nǹkan ṣì máa wà bó ṣe wà.

Ìwé ìròyìn Jí! á ṣì máa gbájú mọ́ ohun tá à ń tìtorí rẹ̀ tẹ̀ ẹ́ láti ọ̀pọ̀ ọdún wá. Gẹ́gẹ́ bá a ṣe ṣàlàyé sí ojú ìwé 4, “à ń tẹ ìwé ìròyìn yìí jáde fún ìlàlóye gbogbo ìdílé.” Ó ń kíyè sí àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé, ó ń ròyìn nípa oríṣiríṣi àwọn èèyàn àti àṣà wọn, ó ń sọ nípa àgbàyanu iṣẹ́ Ẹlẹ́dàá, ó ń jíròrò ọ̀rọ̀ ìlera tàbí ọ̀rọ̀ tó ní í ṣe pẹ̀lú ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì fáwọn tí kì í ṣe onímọ̀ sáyẹ́ǹsì. Ìwé ìròyìn Jí! kò ní ṣíwọ́ láti máa fún àwọn tó ń kà á ní ìròyìn, á sì máa tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ kí wọ́n mọ bí nǹkan ṣe ń lọ sí káàkiri ayé.

Nínú ìtẹ̀jáde ti August 22, 1946, lédè Gẹ̀ẹ́sì, ìwé ìròyìn Jí! ṣèlérí pé: “Ohun tó máa jẹ́ olórí èròǹgbà ìwé ìròyìn yìí ni bó ṣe máa dúró ṣinṣin lórí òtítọ́.” Ìwé ìròyìn Jí! sì ti mú ìlérí tó ṣe yìí ṣẹ ní ti pé kì í fi igbá kan bọ̀kan nínú. Ìdí nìyẹn tá a fi máa ń ṣe ìwádìí jinlẹ̀ lórí àwọn àpilẹ̀kọ tá a máa ń gbé jáde, a sì máa ń yẹ̀ ẹ́ wò dáadáa ká lè rí i pé ohun tá a kọ sínú rẹ̀ péye. Àmọ́ ìwé ìròyìn yìí ti “dúró ṣinṣin lórí òtítọ́” lọ́nà kan tó túbọ̀ ṣe pàtàkì jùyẹn lọ.

Bíbélì ni ìwé ìròyìn Jí! máa ń darí àwọn tó ń kà á sí. Síbẹ̀, bẹ̀rẹ̀ látorí ìtẹ̀jáde yìí, Jí! á túbọ̀ máa gbé àwọn àpilẹ̀kọ tó dá lórí Bíbélì jáde ju ti àtẹ̀yìnwá lọ. (Jòhánù 17:17) Ìwé ìròyìn Jí! á tún máa bá a lọ nínú bó ṣe ń gbé àwọn àpilẹ̀kọ tó fi hàn pé ìmọ̀ràn Bíbélì wúlò jáde àti pé wọ́n lè ràn wá lọ́wọ́ láti gbé ìgbé ayé aláyọ̀ pẹ̀lú ìbàlẹ̀ ọkàn nínú ayé yìí. Gẹ́gẹ́ bẹ́ ẹ ti mọ̀, ọ̀pọ̀ ìtọ́sọ́nà tó bá Ìwé Mímọ́ mu ló máa ń wà nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ bíi “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . ” àti “Ojú Ìwòye Bíbélì.” A sì fẹ́ kó dáa yín lójú pé wọ́n á ṣì máa jáde déédéé nínú ìwé ìròyìn yìí. Láfikún sí i, ìwé ìròyìn Jí! á máa bá a nìṣó láti máa ṣàlàyé ìlérí tí Ọlọ́run ṣe nínú Bíbélì fáwọn tó ń kà á pé láìpẹ́ ayé tuntun alálàáfíà kan ń bọ̀ wá rọ́pò ètò àwọn nǹkan tí ìwà àìlófin pọ̀ nínú rẹ̀ yìí.—Ìṣípayá 21:3, 4.

Kí ló tún máa yí padà nínú rẹ̀? Bẹ̀rẹ̀ látorí ìtẹ̀jáde yìí, nínú èyí tó pọ̀ lára èdè méjìlélọ́gọ́rin tá a fi ń tẹ ìwé ìròyìn Jí!, ẹ̀ẹ̀kan lóṣù la ó máa gbé ìwé ìròyìn náà jáde (tẹ́lẹ̀ ẹ̀ẹ̀méjì lóṣù ló máa ń jáde láwọn èdè kan).a “Wíwo Ayé” tó ti máa ń jáde déédéé tẹ́lẹ̀ lédè Gẹ̀ẹ́sì látọdún 1946, tó sì máa ń gba ojú ìwé méjì á ṣì máa jáde, àmọ́ a ti dín in kù sí ojú ìwé kan. A óò tún máa fi abala alárinrin míì kún un lójú ìwé 31, apá tí yóò máa jáde déédéé yìí la ó máa pè ní “Kí Ni Ìdáhùn Rẹ?” Kí láá máa wà nínú rẹ̀, báwo sì ni wàá ṣe máa lò ó?

Tiẹ̀ wo ojú ewé 31 nínú ìwé ìròyìn tó wà lọ́wọ́ rẹ yìí. Àwọn apá ibì kan wà lójú ewé náà tó máa wu àwọn òǹkàwé wa tó jẹ́ ọ̀dọ́; àwọn apá ibòmíì á jẹ́ káwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó lóye Bíbélì dunjú máa níran ohun tí wọ́n ti mọ̀. Apá ibi tá a pè ní “Ìgbà Wo Lèyí Ṣẹlẹ̀?” á ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti máa rántí ìgbà táwọn nǹkan ṣẹlẹ̀, á jẹ́ kó o mọ ìgbà táwọn tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa wọn gbé láyé àti ìgbà táwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì pàtàkì wáyé. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìdáhùn sáwọn ìbéèrè tó wà ní abala, “Nínú Ìtẹ̀jáde Yìí,” á wà káàkiri inú ìwé ìròyìn yìí, ojú ewé tá a bá sọ lẹ ó ti máa rí ìdáhùn sí èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn ìbéèrè náà, a ó sì máa tẹ̀ ẹ́ ní àtoríkòdí. O ò ṣe kúkú máa ṣèwádìí díẹ̀ kó o tó máa ka àwọn ìdáhùn náà kó o sì máa sọ àwọn ohun tó o bá rí kọ́ fáwọn ẹlòmíì? Ẹ tún lè máa lo abala tuntun náà, “Kí Ni Ìdáhùn Rẹ?” gẹ́gẹ́ bí ohun tẹ́ ẹ ó fi máa ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé tàbí kẹ́ ẹ máa fi kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bí àwùjọ.

Ní nǹkan bí ọgọ́ta ọdún sẹ́yìn, ìwé ìròyìn Jí! ṣèlérí pé: “Ní ti àwọn kókó tí ìwé ìròyìn yìí á máa gbé jáde, a ó máa sapá láti jẹ́ kó bá apá ìbi tó pọ̀ jákèjádò ayé mu dípò kó wulẹ̀ jẹ́ apá ibì kan. Gbogbo èèyàn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ jákèjádò àgbáálá ayé ló máa bá mu. . . . Ohun tá a ó máa jíròrò nínú ìwé ìròyìn yìí . . . á máa fúnni ní ìmọ̀ àti òye, á sì máa gbádùn mọ́ àwọn èèyàn tó pọ̀ jù lọ, lọ́mọdé lágbà.” Gbogbo àwọn tó ń kàwé ìròyìn yìí káàkiri àgbáyé ló gbà pé Jí! ti mú ìlérí yẹn ṣẹ. A ń fi dá a yín lójú pé kò ní ṣíwọ́ láti máa mú ìlérí náà ṣẹ.

Àwa Òǹṣèwé

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ẹ̀ẹ̀mẹrin lọ́dún ni ìwé ìròyìn Jí! máa ń jáde láwọn èdè kan. Yorùbá náà ti wà lára irú àwọn èdè bẹ́ẹ̀ báyìí, nítorí náà àwọn kan lára ohun tá a sọ yìí lè má máa jáde nínú ẹ̀ àti nínú àwọn èdè yòókù tí yóò máa jáde lẹ́ẹ̀mẹrin lọ́dún.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]

Lédè Gẹ̀ẹ́sì “The Golden Age” la kọ́kọ́ ń pè é lọ́dún 1919, a yí orúkọ náà padà sí “Consolation” lọ́dún 1937, nígbà tó sì di ọdún 1946 ló wá di “Awake!” èyí tá a wá mọ̀ sí “Jí!” lónìí, ní èdè Yorùbá

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

Ọjọ́ ti pẹ́ tí ìwé ìròyìn “Jí!” ti ń fi ohun tó wà nínú Bíbélì han àwọn èèyàn

[Àwọn Credit Line]

Ìbọn: Fọ́tò tí U.S. National Archives yà; ọmọ tíyà ń jẹ: Fọ́tò tí W. Cutting yà fún àjọ WHO

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́