ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 3/07 ojú ìwé 4
  • “Kí Ni Ìdáhùn Rẹ?”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Kí Ni Ìdáhùn Rẹ?”
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2007
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Sí Àwọn Òǹkàwé Wa
    Jí!—2006
  • (1) Ìbéèrè, (2) Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ àti (3) Orí
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
  • Ohun Tuntun Tá A Lè Fi Bẹ̀rẹ̀ Ìjíròrò
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni​—Ìwé Ìpàdé (2016)
  • Sí Ẹ̀yin Òǹkàwé Wa
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2007
km 3/07 ojú ìwé 4

“Kí Ni Ìdáhùn Rẹ?”

1. Ìṣòro wo lọ̀pọ̀ wa ń kojú?

1 Ṣó o fẹ́ràn Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run? Ṣó máa ń ṣòro fún ẹ láti rántí kúlẹ̀kúlẹ̀ àwọn àkọsílẹ̀ Bíbélì, tó o sì máa ń gbàgbé àwọn ibi tí gbólóhùn kan pàtó wà nínú Ìwé Mímọ́? Ṣó o fẹ́ káwọn ẹ̀kọ́ inú Bíbélì yé àwọn ọmọ rẹ yékéyéké? Àpilẹ̀kọ kan tó máa ń jáde nínú ìwé ìròyìn Jí! lóòrèkóòrè lójú ìwé 31 á ran tèwe tàgbà lọ́wọ́ láti túbọ̀ mọ tinú tẹ̀yìn Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dáadáa.—Ìṣe 17:11.

2. Báwo lo ṣe lè lo onírúurú apá tí àpilẹ̀kọ tá a pè ní “Kí Ni Ìdáhùn Rẹ?” pín sí?

2 Ọ̀nà wo ni àpilẹ̀kọ yẹn lè gbà wúlò fún ẹ? Nínú Jí! ti January-March 2006, a dábàá yìí pé: “Tiẹ̀ wo ojú ewé 31 nínú ìwé ìròyìn . . . yìí. Àwọn apá ibì kan wà lójú ewé náà tó máa wu àwọn òǹkàwé wa tó jẹ́ ọ̀dọ́; àwọn apá ibòmíì á jẹ́ káwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó lóye Bíbélì dunjú máa níran ohun tí wọ́n ti mọ̀. Apá ibi tá a pè ní ‘Ìgbà Wo Lèyí Ṣẹlẹ̀?’ á ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti máa rántí ìgbà táwọn nǹkan ṣẹlẹ̀, á jẹ́ kó o mọ ìgbà táwọn tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa wọn gbé láyé àti ìgbà táwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì pàtàkì wáyé. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìdáhùn sáwọn ìbéèrè tó wà ní abala, ‘Nínú Ìtẹ̀jáde Yìí,’ á wà káàkiri inú ìwé ìròyìn yìí, ojú ewé tá a bá sọ lẹ ó ti máa rí ìdáhùn sí èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn ìbéèrè náà, a ó sì máa tẹ̀ ẹ́ ní àtoríkòdí. O ò ṣe kúkú máa ṣèwádìí díẹ̀ kó o tó máa ka àwọn ìdáhùn náà kó o sì máa sọ àwọn ohun tó o bá rí kọ́ fáwọn ẹlòmíì? Ẹ tún lè máa lo abala tuntun náà, ‘Kí Ni Ìdáhùn Rẹ?’ gẹ́gẹ́ bí ohun tẹ́ ẹ ó fi máa ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé tàbí kẹ́ ẹ máa fi kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bí àwùjọ.”

3. Ọ̀nà wo làwọn ìdílé kan ti gbà jàǹfààní látinú àpilẹ̀kọ yìí, apá wo nìwọ alára sì máa ń gbádùn jù nínú rẹ̀?

3 Ọ̀pọ̀ ìdílé ló fẹ́ràn láti máa fi àpilẹ̀kọ náà ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé wọn. Ìyá kan kọ̀wé sí wa pé: “Èmi àtọkọ mi rí i pé ó máa dáa pé ká fi ‘Eré Àwòrán Wíwá Fáwọn Ọmọdé’ kún ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé wa kó bàa lè jẹ́ kóríyá fún ọmọbìnrin wa ọlọ́dún mẹ́ta, kó sì tún lè máa gbádùn mọ́ ọn. Inú wa máa ń dùn nígbà tó bá ń wá ìdáhùn káàkiri inú ìwé ìròyìn Jí! tiẹ̀ fúnra ẹ̀ títí tó fi máa rí ohun tó ń wá.” Bàbá kan lórílẹ̀-èdè Brazil sọ pé: “Èmi àtọmọ mi ọlọ́dún méje tó ń jẹ́ Moises fẹ́ràn apá yìí nínú ìwé ìròyìn Jí! gidigidi. Ó ran Moises lọ́wọ́ láti pọkàn pọ̀, láti máa wá ibi táwọn ẹsẹ Bíbélì kan wà nínú Ìwé Mímọ́, láti mọ ìwúlò àwòrán, ó sì jẹ́ kí àwọn déètì túbọ̀ yé e.” Ohun tí Ashley, ọmọ ọdún mẹ́jọ sọ rèé: “Ẹ ṣeun ti àpilẹ̀kọ tó máa ń wà lẹ́yìn ìwé ìròyìn Jí!, èyí tẹ́ ẹ pè ní ‘Kí Ni Ìdáhùn Rẹ?’ Ọ̀pọ̀ nǹkan látinú Bíbélì ni mo ti rí kọ́ látinú ẹ̀.

4. Báwo ni ìdílé ṣe lè lo àpilẹ̀kọ tó wà lẹ̀yin ìwé ìròyìn Jí! nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé wọn?

4 Ẹ ẹ̀ ṣe kúkú rò ó wò bóyá ẹ lè máa lo àpilẹ̀kọ “Kí Ni Ìdáhùn Rẹ?” lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé yín? Ẹ lè lo ìwé atọ́ka [Index] tàbí àkójọ ìwé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tá a ṣe sórí àwo CD [Watchtower Library on CD-ROM] láti lè wá àwọn ìdáhùn kan tó sábà máa ń ṣòro láti rí ìdáhùn sí. Bẹ́ ẹ bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe lẹ̀ ń kọ́ àwọn ọmọ yín láti mọ báa ṣeé wá ìsọfúnni rí. Bí àwọn ọmọ rẹ bá ti dàgbà, o ò ṣe jẹ́ kí wọ́n wá ìdáhùn sí apá tá à ń pè ní “Ta Ni Mí?” tàbí èyí tá à ń pè ní “Ìgbà Wo Lèyí Ṣẹlẹ̀?” kí ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé yín tó bẹ̀rẹ̀. Kí wọ́n sì jábọ̀ ìwádìí wọn nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. Báwọn òbí bá ń lo ojú ìwé tá à ń sọ yìí dáadáa, wọ́n á lè fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kọ́ àwọn ọmọ wọn, wọ́n á sì lè jẹ́ kí wọ́n mọ “Ìwé Mímọ́” látìgbà tí wọ́n bá ti wà lọ́mọdé jòjòló.—2 Tím. 3:15; Diu. 6:7.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́