ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 1 Tẹsalóníkà 2
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé 1 Tẹsalóníkà

      • Iṣẹ́ òjíṣẹ́ Pọ́ọ̀lù ní Tẹsalóníkà (1-12)

      • Àwọn ará Tẹsalóníkà gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run (13-16)

      • Àárò àwọn ará Tẹsalóníkà ń sọ Pọ́ọ̀lù (17-20)

1 Tẹsalóníkà 2:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Iṣe 17:1, 4

1 Tẹsalóníkà 2:2

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “nígboyà.”

  • *

    Tàbí kó jẹ́, “nínú ọ̀pọ̀ ìjàkadì.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Iṣe 16:12, 22-24
  • +Iṣe 17:1, 2

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!, ẹ̀kọ́ 59

    Ilé Ìṣọ́,

    7/15/2009, ojú ìwé 20

    7/15/2008, ojú ìwé 8

    12/15/1999, ojú ìwé 23-25

    Jíjẹ́rìí Kúnnákúnná, ojú ìwé 133

1 Tẹsalóníkà 2:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Owe 17:3; Jer 11:20

1 Tẹsalóníkà 2:5

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ojúkòkòrò.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Iṣe 20:33

1 Tẹsalóníkà 2:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kọ 11:9; 2Tẹ 3:8, 10

1 Tẹsalóníkà 2:7

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ṣìkẹ́.”

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    11/15/2000, ojú ìwé 22

    Yiyan, ojú ìwé 146

1 Tẹsalóníkà 2:8

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Grk., “ó dùn mọ́ wa pé.”

  • *

    Tàbí “ọkàn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jo 15:13
  • +Jo 13:35

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    11/15/2000, ojú ìwé 22

1 Tẹsalóníkà 2:9

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “iṣẹ́ àṣekára.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Iṣe 18:3; 20:34; 2Kọ 11:9; 2Tẹ 3:8, 10

1 Tẹsalóníkà 2:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Iṣe 20:31
  • +1Kọ 4:15

1 Tẹsalóníkà 2:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ef 4:1; Kol 1:10; 1Pe 1:15
  • +Lk 22:28-30
  • +1Pe 5:10

1 Tẹsalóníkà 2:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Tẹ 1:2, 3

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!, ẹ̀kọ́ 5

1 Tẹsalóníkà 2:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Iṣe 17:5

1 Tẹsalóníkà 2:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Iṣe 2:22, 23; 7:52
  • +Mt 23:34

1 Tẹsalóníkà 2:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Lk 11:52; Iṣe 13:49, 50
  • +Ro 1:18

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    “Ete aiyeraiye,” ojú ìwé 173

1 Tẹsalóníkà 2:17

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “gbà yín kúrò lọ́wọ́ wa.”

  • *

    Ní Grk., “rí ojú yín.”

1 Tẹsalóníkà 2:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Tẹ 5:23; 2Tẹ 1:4

Àwọn míì

1 Tẹs. 2:1Iṣe 17:1, 4
1 Tẹs. 2:2Iṣe 16:12, 22-24
1 Tẹs. 2:2Iṣe 17:1, 2
1 Tẹs. 2:4Owe 17:3; Jer 11:20
1 Tẹs. 2:5Iṣe 20:33
1 Tẹs. 2:62Kọ 11:9; 2Tẹ 3:8, 10
1 Tẹs. 2:8Jo 15:13
1 Tẹs. 2:8Jo 13:35
1 Tẹs. 2:9Iṣe 18:3; 20:34; 2Kọ 11:9; 2Tẹ 3:8, 10
1 Tẹs. 2:11Iṣe 20:31
1 Tẹs. 2:111Kọ 4:15
1 Tẹs. 2:12Ef 4:1; Kol 1:10; 1Pe 1:15
1 Tẹs. 2:12Lk 22:28-30
1 Tẹs. 2:121Pe 5:10
1 Tẹs. 2:131Tẹ 1:2, 3
1 Tẹs. 2:14Iṣe 17:5
1 Tẹs. 2:15Iṣe 2:22, 23; 7:52
1 Tẹs. 2:15Mt 23:34
1 Tẹs. 2:16Lk 11:52; Iṣe 13:49, 50
1 Tẹs. 2:16Ro 1:18
1 Tẹs. 2:191Tẹ 5:23; 2Tẹ 1:4
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
1 Tẹsalóníkà 2:1-20

Ìwé Kìíní sí Àwọn Ará Tẹsalóníkà

2 Ẹ̀yin ará, ẹ̀yin fúnra yín mọ̀ dájú pé ìbẹ̀wò tí a ṣe sọ́dọ̀ yín kò já sí asán.+ 2 Nítorí bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ti kọ́kọ́ jìyà, tí wọ́n sì hùwà àfojúdi sí wa ní ìlú Fílípì,+ bí ẹ̀yin náà ṣe mọ̀, Ọlọ́run wa mú kí a mọ́kàn le* kí a lè sọ ìhìn rere Ọlọ́run+ fún yín lójú ọ̀pọ̀ àtakò.* 3 Nítorí ọ̀rọ̀ ìyànjú wa kò wá látinú ìṣìnà tàbí látinú ìwà àìmọ́ tàbí pẹ̀lú ẹ̀tàn, 4 àmọ́ gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ṣe tẹ́wọ́ gbà wá pé kí ìhìn rere wà ní ìkáwọ́ wa, bẹ́ẹ̀ ni à ń sọ̀rọ̀, kì í ṣe torí ká lè wu èèyàn, àmọ́ torí ká lè wu Ọlọ́run, ẹni tó ń yẹ ọkàn wa wò.+

5 Kódà, ẹ mọ̀ pé kò sí ìgbà kankan tí a sọ ọ̀rọ̀ ìpọ́nni tàbí tí a ṣe ojú ayé nítorí ohun tí a fẹ́ rí gbà;*+ Ọlọ́run ni ẹlẹ́rìí! 6 Bẹ́ẹ̀ ni a kò máa wá ògo lọ́dọ̀ èèyàn, ì báà jẹ́ lọ́dọ̀ yín tàbí lọ́dọ̀ àwọn ẹlòmíì, bó tiẹ̀ jẹ́ pé gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì Kristi, àwa fúnra wa lè sọ ara wa di ẹrù tó wúwo sí yín lọ́rùn.+ 7 Kàkà bẹ́ẹ̀, a di ẹni jẹ́jẹ́ láàárín yín, bí ìgbà tí abiyamọ ń tọ́jú* àwọn ọmọ rẹ̀. 8 Torí náà, bí a ṣe ní ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ sí yín, a ti pinnu* pé kì í ṣe ìhìn rere Ọlọ́run nìkan la máa fún yín, a tún máa fún yín ní ara* wa,+ torí ẹ ti di ẹni ọ̀wọ́n sí wa.+

9 Ẹ̀yin ará, ó dájú pé ẹ rántí òpò* àti làálàá wa. A ṣiṣẹ́ tọ̀sántòru ká má bàa di ẹrù wọ ìkankan nínú yín lọ́rùn,+ nígbà tí a wàásù ìhìn rere Ọlọ́run fún yín. 10 Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí, Ọlọ́run náà sì jẹ́ ẹlẹ́rìí, bí a ṣe jẹ́ adúróṣinṣin àti olódodo àti aláìlẹ́bi sí ẹ̀yin onígbàgbọ́. 11 Ẹ mọ̀ dáadáa pé ṣe là ń gbà yín níyànjú, tí à ń tù yín nínú, tí a sì ń jẹ́rìí fún ẹnì kọ̀ọ̀kan yín,+ bí bàbá+ ṣe máa ń ṣe fún àwọn ọmọ rẹ̀, 12 kí ẹ lè máa rìn lọ́nà tó yẹ Ọlọ́run,+ ẹni tó ń pè yín sí Ìjọba+ àti ògo rẹ̀.+

13 Ní tòótọ́, ìdí nìyẹn tí àwa náà fi ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nígbà gbogbo,+ torí nígbà tí ẹ gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, èyí tí ẹ gbọ́ lọ́dọ̀ wa, ẹ tẹ́wọ́ gbà á, kì í ṣe bí ọ̀rọ̀ èèyàn, àmọ́ gẹ́gẹ́ bó ṣe jẹ́ lóòótọ́, bí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, èyí tó tún wà lẹ́nu iṣẹ́ nínú ẹ̀yin onígbàgbọ́. 14 Ẹ̀yin ará ń fara wé àwọn ìjọ Ọlọ́run tó wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Kristi Jésù ní Jùdíà, nítorí àwọn ará ìlú yín ń fìyà jẹ yín  + bí àwọn Júù ṣe ń fìyà jẹ àwọn náà, 15 kódà wọ́n pa Jésù Olúwa+ àti àwọn wòlíì, wọ́n sì ṣe inúnibíni sí wa.+ Bákan náà, wọn ò ṣe ohun tó wu Ọlọ́run, wọn ò sì ní ire àwọn èèyàn lọ́kàn, 16 bí wọ́n ṣe ń gbìyànjú láti dí wa lọ́wọ́ ká má lè bá àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè sọ̀rọ̀, kí wọ́n sì rí ìgbàlà.+ Ọ̀nà yìí ni wọ́n gbà ń mú kí ẹ̀ṣẹ̀ wọn pọ̀ sí i. Àmọ́ ìrunú Ọlọ́run ti dé tán sórí wọn.+

17 Ẹ̀yin ará, nígbà tí wọ́n yà wá kúrò lọ́dọ̀ yín* fún àkókò kúkúrú (nínú ara, tí kì í ṣe nínú ọkàn wa), àárò yín tó ń sọ wá gan-an mú ká sa gbogbo ipá wa láti rí yín lójúkojú.* 18 Torí náà, a fẹ́ wá sọ́dọ̀ yín, bẹ́ẹ̀ ni, èmi Pọ́ọ̀lù, gbìyànjú láti wá, kódà kì í ṣe ẹ̀ẹ̀kan, ẹ̀ẹ̀mejì ni; àmọ́ Sátánì dí wa lọ́nà. 19 Nítorí kí ni ìrètí tàbí ìdùnnú tàbí adé ayọ̀ wa níwájú Jésù Olúwa wa nígbà tó bá wà níhìn-ín? Ní tòótọ́, ṣé kì í ṣe ẹ̀yin ni?+ 20 Dájúdájú, ẹ̀yin ni ògo àti ìdùnnú wa.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́