ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb19 March ojú ìwé 7
  • Máa Fi Fídíò Kọ́ Àwọn Tó Ò Ń Kọ́ Lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Máa Fi Fídíò Kọ́ Àwọn Tó Ò Ń Kọ́ Lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2019
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Bí O Ṣe Lè Fi Fídíò Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni​—Ìwé Ìpàdé (2016)
  • Máa Lo Fídíò Láti Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
  • Ǹjẹ́ Ó Yẹ Kí N Máa Wo Àwọn Fídíò Orin?
    Jí!—2003
  • Máa Fi Àwọn Fídíò Wa Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2013
Àwọn Míì
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2019
mwb19 March ojú ìwé 7
Arábìnrin kan ń fi fídíò han ẹni ó ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Máa Fi Fídíò Kọ́ Àwọn Tó Ò Ń Kọ́ Lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì

Ohun téèyàn fojú rí máa ń gba àfíyèsí ẹni gan-an, ó máa ń ranni lọ́wọ́ láti lóye ohun tó ń kọ́, ó sì máa ń jẹ́ kéèyàn rántí. Jèhófà, Olùkọ́ni Atóbilọ́lá wa máa ń lo ohun téèyàn lè fojú rí láti kọ́ni láwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì. (Jẹ 15:5; Jer 18:1-6) Jésù Olùkọ́ Ńlá wa náà ṣe bẹ́ẹ̀. (Mt 18:2-6; 22:19-21) Ọ̀kan lára ohun téèyàn lè fojú rí ni fídíò, ó sì ti wúlò gan-an láwọn ọdún àìpẹ́ yìí. Ṣé o máa ń lo fídíò dáadáa tó o bá ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?

A ti ṣe àwọn fídíò mẹ́wàá tó máa ràn wá lọ́wọ́ láti kọ́ni láwọn ẹ̀kọ́ tó wà nínu ìwé Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run! Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn fídíò yẹn wà fún àwọn ìbéèrè kan nínú ìwé náà. Tá a bá ń lo ìwé yìí lórí ẹ̀rọ, a máa rí ìlujá tó máa jẹ́ ká mọ ìgbà tá a máa fi fídíò kọ̀ọ̀kan han ẹni tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́. Láfikún síyẹn, a tún ní àwọn fídíò míì nínú Àpótí Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ wa.

Ṣé ó máa ṣòro díẹ̀ fún ẹni tí ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì láti lóye ohun tẹ́ ẹ̀ ń kọ́? Àbí ìṣòro kan wà tí ẹni náà ń dojú kọ? O lè wá àwọn fídíò tó máa ràn án lọ́wọ́ lórí ìkànnì jw.org® àti Tẹlifíṣọ̀n JW. Ìwọ àti ẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ lè jọ wò ó, kẹ́ ẹ sì jọ jíròrò rẹ̀.

Oṣooṣù ni àwọn fídíò tuntun ń jáde. Bó o ṣe ń wò wọ́n, ronú nípa bó o ṣe lè fi ran àwọn tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́.

ÀWỌN FÍDÍÒ TÓ WÀ FÚN ÀWỌN Ẹ̀KỌ́ INÚ ÌWÉ ÌRÒYÌN AYỌ̀

  • Fídíò Ṣé Ọlọ́run Ní Orúkọ?

    Ẹ̀kọ́ 2

    Ṣé Ọlọ́run Ní Orúkọ?

  • Fídíò Ta Ni Òǹṣèwé Bíbélì?

    Ẹ̀kọ́ 3

    Ta Ni Òǹṣèwé Bíbélì?

  • Fídíò Báwo La Ṣe Mọ̀ Pé Òótọ́ ni Ọ̀rọ̀ Inú Bíbélì?

    Báwo La Ṣe Mọ̀ Pé Òótọ́ ni Ọ̀rọ̀ Inú Bíbélì?

  • Fídíò Kí Nìdí Tí Jésù Fi Kú?

    Ẹ̀kọ́ 4

    Kí Nìdí Tí Jésù Fi Kú?

  • Fídíò Kí Ni Ìdí Tí Ọlọ́run Fi Dá Ayé?

    Ẹ̀kọ́ 5

    Kí Ni Ìdí Tí Ọlọ́run Fi Dá Ayé?

  • Fídíò Kí Ló Ń Ṣẹlẹ̀ sí Àwọn Tó Ti Kú?

    Ẹ̀kọ́ 6

    Kí Ló Ń Ṣẹlẹ̀ sí Àwọn Tó Ti Kú?

  • Fídíò Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?

    Ẹ̀kọ́ 7

    Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?

  • Fídíò Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Gbà Pé Ká Máa Jìyà?

    Ẹ̀kọ́ 8

    Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Gbà Pé Ká Máa Jìyà?

  • Fídíò Ṣé Gbogbo Ìsìn Ni Ọlọ́run Tẹ́wọ́ Gbà?

    Ẹ̀kọ́ 10

    Ṣé Gbogbo Ìsìn Ni Ọlọ́run Tẹ́wọ́ Gbà?

  • Fídíò Ṣé Gbogbo Àdúrà Ni Ọlọ́run Ń Gbọ́?

    Ẹ̀kọ́ 12

    Ṣé Gbogbo Àdúrà Ni Ọlọ́run Ń Gbọ́?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́