ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 5/13 ojú ìwé 3
  • Máa Fi Àwọn Fídíò Wa Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Máa Fi Àwọn Fídíò Wa Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2013
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Máa Lo Fídíò Láti Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
  • Máa Fi Fídíò Kọ́ Àwọn Tó Ò Ń Kọ́ Lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2019
  • Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Bí O Ṣe Lè Fi Fídíò Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni​—Ìwé Ìpàdé (2016)
  • Ǹjẹ́ Ó Yẹ Kí N Máa Wo Àwọn Fídíò Orin?
    Jí!—2003
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2013
km 5/13 ojú ìwé 3

Máa Fi Àwọn Fídíò Wa Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́

Nígbà tí Jèhófà ń fún Ábúráhámù àti Jeremáyà ní ìsọfúnni pàtàkì, kò fẹnu nìkan sọ ọ́, ó tún fi àwòrán ohun tó ń sọ hàn wọ́n. (Jẹ́n. 15:5; Jer. 18:1-6) Àwa náà lè fi àwọn fídíò wa han àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kí wọ́n lè túbọ̀ lóye òtítọ́ Bíbélì, kí wọ́n sì mọyì rẹ̀. Jẹ́ ká wo ìgbà tá a lè fi àwọn fídíò wa hàn wọ́n. Fi sọ́kàn pé àbá ni àwọn ohun tá a kọ síbí yìí, torí pé àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ yàtọ̀ síra.

Ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni

◻ Orí 1: Tẹ́ ẹ bá parí ìpínrọ̀ 17, ẹ wo fídíò tó dá lórí bí ìṣẹ̀dá ṣe ń gbé ògo Ọlọ́run yọ, ìyẹn The Wonders of Creation Reveal God’s Glory

◻ Orí 2: Tẹ́ ẹ bá parí orí náà, ẹ wo fídíò tó sọ̀rọ̀ nípa bí Bíbélì ṣe jẹ́ ìwé tó lọ́jọ́ lórí jù lọ, ìyẹn The Bible—Mankind’s Oldest Modern Book

◻ Orí 9: Tẹ́ ẹ bá parí ìpínrọ̀ 14, ẹ wo fídíò Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—A Ṣètò Wa Láti Wàásù Ìhìn Rere

◻ Orí 14: Tẹ́ ẹ bá parí orí náà, ẹ wo fídíò tó sọ̀rọ̀ nípa bí Bíbélì ṣe ń yí ìgbésí ayé èèyàn pa dà, ìyẹn The Bible—Its Power in Your Life

◻ Orí 15: Tẹ́ ẹ bá parí ìpínrọ̀ 10, ẹ wo fídíò Gbogbo Ẹgbẹ́ Àwọn Ará Wa

Ìwé “Ìfẹ́ Ọlọ́run”

◻ Orí 3: Tẹ́ ẹ bá parí ìpínrọ̀ 15, ẹ wo fídíò tó dá lórí bí àwọn ọ̀dọ́ ṣe lè yan ọ̀rẹ́ gidi, ìyẹn Young People Ask—How Can I Make Real Friends?

◻ Orí 4: Tẹ́ ẹ bá parí orí náà, ẹ wo fídíò tó dá lórí ìdí tó fi yẹ ká máa bọ̀wọ̀ fún àwọn tí Jèhófà yàn sípò, ìyẹn Respect Jehovah’s Authority

◻ Orí 7: Tẹ́ ẹ bá parí ìpínrọ̀ 12, ẹ wo fídíò tó dá lórí àwọn àfidípò ẹ̀jẹ̀, ìyẹn No Blood—Medicine Meets the Challenge

◻ Orí 9: Tẹ́ ẹ bá parí ìpínrọ̀ 6, ẹ wo fídíò tó dá lórí ìtàn tó jẹ́ ìkìlọ̀ pàtàkì fún wa, ìyẹn Warning Examples for Our Day

◻ Orí 17: Tẹ́ ẹ bá parí orí náà, ẹ wo fídíò tó dá lórí bá a ṣe lè máa rìn nípa ìgbàgbọ́, ìyẹn ‘Walk by Faith, Not by Sight’

Ǹjẹ́ o rántí àwọn fídíò míì tó lè ran àwọn tí ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́? Bí àpẹẹrẹ, ẹni tí wọ́n ń ṣe àtakò sí lè rí ìṣírí nínú àwọn fídíò tó dá lórí bí àwọn ará wa kò ṣe yẹhùn nígbà tí wọ́n ṣe inúnibíni sí wọn, ìyẹn Faithful Under Trials—Jehovah’s Witnesses in the Soviet Union àti Jehovah’s Witnesses Stand Firm Against Nazi Assault. Bákan náà, àwọn ọ̀dọ́ tún máa rí ẹ̀kọ́ púpọ̀ kọ́ tí wọ́n bá wo fídíò tó dá lórí bí wọ́n ṣe lè ní àfojúsùn tó dáa, ìyẹn Pursue Goals That Honor God àti èyí tó dá lórí ohun tí wọ́n lè fi ìgbésí ayé wọn ṣe, ìyẹn Young People Ask—What Will I Do With My Life? O lè fi àmì sínú ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni àti ìwé “Ìfẹ́ Ọlọ́run,” kó o lè rántí ìgbà tó o lè yá ẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ ní fídíò láti wò tàbí kẹ́ ẹ jọ wò ó. Bí a ṣe ń gbé àwọn fídíò tuntun jáde, máa ronú lórí bí wàá ṣe lò wọ́n láti ran àwọn tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́wọ́.—Lúùkù 24:32.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́