Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ May 27
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ MAY 27
Orin 6 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
jr orí 10 ìpínrọ̀ 1 sí 7 (30 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Jòhánù 12-16 (10 min.)
No. 1: Jòhánù 12:20-36 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Ọlọ́run Jẹ́ Aláàánú—td 31D (5 min.)
No. 3: Kí Nìdí Tó Fi Bọ́gbọ́n Mu Láti Pe Jèhófà Ní “Ọlọ́run Tí Ń Fúnni Ní Àlàáfíà”?—Róòmù 15:33 (5 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
5 min: Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ní Sátidé Àkọ́kọ́. Àsọyé. Ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní Sátidé àkọ́kọ́ lóṣù June, kó o lo àpilẹ̀kọ tó wà lẹ́yìn Ilé Ìṣọ́. Gba àwọn ará níyànjú pé kí wọ́n wá sóde ẹ̀rí lọ́jọ́ yẹn.
15 min: Bá A Ṣe Lè Bomirin Àwọn Irúgbìn Tá A Ti Gbìn. (1 Kọ́r. 3:6-9) Ìjíròrò tó dá lórí àwọn ìbéèrè yìí: (1) Kí lo fẹ́ràn nínú ṣíṣe ìpadàbẹ̀wò? (2) Kí ló máa ń mú kó ṣòro fún àwọn kan láti ṣe ìpadàbẹ̀wò? (3) Báwo ni wọ́n ṣe lè borí àwọn ìṣòro yìí? (4) Kí ni ohun tá a lè ṣe tó bá ń ṣòro fún wa láti ṣe ìpadàbẹ̀wò? (5) Kí lo máa ń ṣe láti rántí ẹni tó nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wa, ohun tẹ́ ẹ jọ jíròrò, ìwé tó o fún un àtàwọn nǹkan míì tó yẹ kó o rántí? (6) Báwo lo ṣe ń múra ìpadàbẹ̀wò sílẹ̀? (7) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì láti máa wáyè ṣe ìpadàbẹ̀wò lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀?
10 min: “Máa Fi Àwọn Fídíò Wa Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́.” Ìjíròrò. Ní kí àwọn ará sọ bí wọ́n ṣe jàǹfààní nínú wíwo àwọn fídíò wa kí wọ́n tó di Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
Orin 101 àti Àdúrà