Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
Àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ wọ̀nyí la óò gbé yẹ̀ wò nígbà àtúnyẹ̀wò aláfẹnusọ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, lọ́sẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ní February 27, 2006. Alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ yóò darí àtúnyẹ̀wò yìí fún ọgbọ̀n ìṣẹ́jú, èyí tó dá lórí àwọn iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ tá a ṣe lọ́sẹ̀ January 2 sí February 27, 2006. [Àkíyèsí: Níbi tí a kò bá ti sọ ibi tí a ti mú ìdáhùn jáde lẹ́yìn ìbéèrè kan, o ní láti ṣe ìwádìí láti wá ìdáhùn sí ìbéèrè náà.—Wo ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 36 àti 37.]
ÀNÍMỌ́ Ọ̀RỌ̀ SÍSỌ
1. Àwọn ọ̀nà wo ni Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ń gbà ràn wá lọ́wọ́ láti ‘rú ẹbọ ìyìn sí Ọlọ́run ká sì ṣe ìpolongo ní gbangba sí orúkọ rẹ̀’? (Héb. 13:15) [be-YR ojú ìwé 5 ìpínrọ̀ 3 sí ojú ìwé 6 ìpínrọ̀ 1]
2. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa sapá láti kàwé lọ́nà tó tọ́? [be-YR ojú ìwé 83, ìpínrọ̀ 1 sí 5]
3. Nígbà tá a bá ń sọ̀rọ̀ tàbí tá à ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́, kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa sọ̀rọ̀ sókè ketekete? [be-YR ojú ìwé 86, ìpínrọ̀ 1 sí 6]
4. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì láti máa pe ọ̀rọ̀ bó ṣe tọ́, kí sì làwọn kókó tó yẹ ká gbé yẹ̀ wò? [be-YR ojú ìwé 89 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 90 ìpínrọ̀ 2, àpótí]
5. Kí làwọn àbá díẹ̀ tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti túbọ̀ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yọ̀ mọ́ wa lẹ́nu? [be-YR ojú ìwé 94, ìpínrọ̀ 4 sí 5, àpótí]
IṢẸ́ AKẸ́KỌ̀Ọ́ KÌÍNÍ
6. Ìdẹkùn wo làwọn ọba Ísírẹ́lì kó sí, ẹ̀kọ́ wo la sì lè rí kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn lónìí? [w85-YR 11/1 ojú ìwé 29 ìpínrọ̀ 4; ojú ìwé 30 ìpínrọ̀ 2 sí 4]
7. Ṣé aláìṣòótọ́ làwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó ṣẹ́ kù sí Bábílónì ni? (Ẹ́sírà 1:3-6) Ǹjẹ́ ohun tó jọ ìyẹn ń ṣẹlẹ̀ lónìí? [w86-YR 2/15 ojú ìwé 29 ìpínrọ̀ 4, 5, 10]
8. Ọ̀nà wo ni ìwé Ẹ́sírà gbà fi hàn pé Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́, báwo lò sì ṣe fi hàn pé a gbọ́dọ̀ gbọ́kàn lé e? [w86-YR 2/15 ojú ìwé 30, ìpínrọ̀ 17]
9. Ọ̀nà wo ni Nehemáyà gbà jẹ́ àpẹẹrẹ rere fáwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lóde òní? [w86-YR 6/1 ojú ìwé 21 ìpínrọ̀ 9]
10. Ọ̀nà wo la lè gbà ní ayọ̀ Jèhófà, báwo la sì ṣe lè máa ní ayọ̀ ọ̀hún nìṣó? [w86-YR 6/1 ojú ìwé 22, ìpínrọ̀ 9]
BÍBÉLÌ KÍKÀ Ọ̀SỌ̀Ọ̀SẸ̀
11. Ǹjẹ́ Úrímù àti Túmímù tí wọ́n máa fi ń béèrè nǹkan lọ́wọ́ Jèhófà wà níkàáwọ́ àwọn tó padà láti ìgbèkùn? (Ẹ́sírà 2:61-63)
12. Kí ló mú kí ọ̀pọ̀ lára àwọn Júù tó wà ní Bábílónì lọ́ tìkọ̀ láti bá Ẹ́sírà gòkè lọ sí Jerúsálẹ́mù? (Ẹ́sírà 7:28–8:20)
13. Ọ̀nà wo ni wọ́n gbà fi ọwọ́ kan ṣoṣo tún odi ìlú náà kọ́? (Neh. 4:17, 18)
14. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé inú àpò tí wọ́n dí pa lẹ́nu ni wọ́n máa ń fi lẹ́tà àṣírí sí, Sáńbálátì ṣe fi “lẹ́tà tí a kò lẹ̀” ránṣẹ́ sí Nehemáyà? (Neh. 6:5)
15. Yàtọ̀ sí rírí tí Nehemáyà rí “àléébù” lára àwọn Júù ọ̀dàlẹ̀ yẹn bó ṣe rí i lára àwọn ìjòyè àtàwọn ọ̀tọ̀kùlú, ohun mìíràn wo ló ṣe láti ṣàtúnṣe àwọn nǹkan wọ̀nyẹn? (Neh. 13:25, 28)