Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní July 8
Orin 201
15 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Àwọn Ìfilọ̀ tá a mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Nípa lílo àwọn àbá tó wà ní ojú ìwé 4, ṣe àṣefihàn méjì nípa bí a ṣe lè fi Ilé Ìṣọ́ July 15 àti Jí! August 8 lọni. Lo àbá àkọ́kọ́ tó wà ní ojú ìwé 4 láti fi Jí! August 8 lọni. Nínú àṣefihàn kọ̀ọ̀kan, fi hàn bí a ṣe lè fèsì àwọn ọ̀rọ̀ tó lè bẹ́gi dínà ìjùmọ̀sọ̀rọ̀, irú bíi “Kristẹni ni àwa náà níbí.”—Wo ìwé kékeré náà, Bí A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Awọn Ìjíròrò Bibeli Kí A Sì Máa Báa Nìṣó, ojú ìwé 11.
10 min: Àpótí Ìbéèrè. Àsọyé tí alàgbà kan yóò sọ, kí ó ṣàlàyé bí a ṣe lè fi ìsọfúnni náà sílò nínú ìjọ.
20 min: Wíwéwèé Láti Jẹ́rìí Láwọn Ọ̀nà Mìíràn Yàtọ̀ Sí Ìwàásù Ilé-dé-Ilé. Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ èyí tí a gbé ka ìwé Ìṣètòjọ, ojú ìwé 93 àti 94. Nípa lílo àwọn àbá tó wà ní ojú ìwé àkọ́kọ́ nínú àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti January 2002, ṣe àwọn àṣefihàn kúkúrú méjì tàbí mẹ́ta, nípa ọ̀nà tá a lè gbà jẹ́rìí fún ẹnì kan tó jẹ́ àjèjì, aládùúgbò, mọ̀lẹ́bí, tàbí ojúlùmọ̀, láìjẹ́ pé a wà nínú iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé.
Orin 139 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní July 15
Orin 144
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ìròyìn ìnáwó.
15 min: Àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.
20 min: Àwọn Ìdí Pàtàkì Tá A Fi Gbọ́dọ̀ Lo Bíbélì Nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Wa. Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Jésù mọ Ìwé Mímọ́, ó sì máa ń tọ́ka sí i lemọ́lemọ́ nígbà tó bá ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́. (Lúùkù 24:27, 44-47) Kì í ṣe èrò ti ara rẹ̀ ló fi ń kọ́ni. (Jòh. 7:16-18) Ó ṣe pàtàkì pé kí àwa náà máa lo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ó lágbára ju ohun èyíkéyìí tá a lè fẹnu sọ lọ. (Jòh. 12:49, 50; Héb. 4:12) Ọ̀rọ̀ ìtùnú àti ìrètí tó wà nínú Ìwé Mímọ́ máa ń fa àwọn olóòótọ́ ọkàn mọ́ra. Fi ṣe ìpinnu rẹ pé wàá máa ka ó kéré tán, ẹsẹ Bíbélì kan nínú ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ. Ṣàlàyé pé àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wà nínú àwọn ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tá a dábàá fún ìfilọni ìwé ìròyìn ní oṣù yìí. Sọ pé kí àwùjọ sọ bí wọ́n ti ṣe ń lo Bíbélì nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn, kí wọ́n sì sọ ipa tí èyí ti ní lórí wọn àti lórí àwọn tí wọ́n ń wàásù fún.
Orin 215 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní July 22
Orin 47
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Òbí kan àti ọmọ rẹ̀ ni kó ṣe àṣefihàn yìí. Kí wọ́n jọ máa ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí, kí wọ́n wá lo àwọn àbá tó wà ní ojú ìwé 4 láti fi ṣàṣefihàn bí a ṣe lè fi ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ August 1 àti Jí! August 8 lọni. Kí ọ̀kan nínú wọn fi Ilé Ìṣọ́ lọni, kí ẹnì kejì sì fi Jí! lọni. Lo àbá kejì tó wà ní ojú ìwé 4 láti fi Jí! August 8 lọni. Fún àwọn òbí níṣìírí láti máa dá àwọn ọmọ wọn lẹ́kọ̀ọ́ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀-lé nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́.
17 min: “Máa Fi Ìmọrírì Àtọkànwá Hàn fún Àwọn Ìwé Ìkẹ́kọ̀ọ́ Wa.”a Tẹnu mọ́ ọn pé ó ṣe pàtàkì ká rí i pé onílé fi ìfẹ́ àtọkànwá hàn ká tó fún un ní ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́. Bí kò bá fi bẹ́ẹ̀ fìfẹ́ hàn, a lè fún un ní ìwé àṣàrò kúkúrú.
18 min: Báwo Ni Mo Ṣe Lè Yẹra fún Àwọn Ewu Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì? Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tá a gbé ka Jí! ti April 8, 2000, ojú ìwé 23 sí 25. Tọ́ka sí àwọn ọ̀fìn tí lílo Íńtánẹ́ẹ̀tì láìníjàánu lè jẹ́ kéèyàn kó sí, kó o sì ṣàlàyé àwọn ohun tá a lè ṣe kó má bàa dẹkùn mú wa. Sọ pé kí àwùjọ sọ bí wọ́n ti jàǹfààní látinú fífi ìmọ̀ràn yìí sílò.
Orin 61 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní July 29
Orin 54
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí láti fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti oṣù July sílẹ̀.
15 min: “Ipa Tí Àwọn Fídíò Tá A Fi Ń Jẹ́rìí Ń Ní Lórí Àwọn Èèyàn.” Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Ó ti di mọ́kànlá báyìí tá a ti gbé yẹ̀ wò lára àwọn fídíò wa nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn. Lẹ́yìn tó o bá ti jíròrò àwọn àpẹẹrẹ tá a tọ́ka sí nínú àpilẹ̀kọ náà ní ṣókí, sọ pé kí àwọn akéde sọ àwọn àṣeyọrí tí wọ́n ti ṣe nípa jíjẹ́ kí àwọn ẹlòmíràn wo àwọn fídíò náà.
20 min: “Ẹ Máa Ṣiṣẹ́ Ní Ìṣọ̀kan.”b Nígbà tó o bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 3, fi àwọn àlàyé kún un látinú Jí! May 8, 2000, ojú ìwé 9 àti 10. Ní ìpínrọ̀ 4, fi àwọn àlàyé kún un látinú Ilé Ìṣọ́ April 1, 1995, ojú ìwé 16 àti 17, ìpínrọ̀ 4 sí 6.
Orin 81 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní August 5
Orin 38
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ.
20 min: “Kíkó Àwọn Èèyàn Jọ Látinú Gbogbo Èdè.”c Fi àwọn àlàyé kún un látinú Ilé Ìṣọ́ April 1, 2002, ojú ìwé 24. Bí àwọn tó ń sọ èdè ilẹ̀ òkèèrè bá wà ní ìpínlẹ̀ ìjọ, ṣàlàyé ní ṣókí ìgbésẹ̀ tí ìjọ ń gbé láti ṣèrànwọ́ fún irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀, kó o sì ṣàṣefihàn ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ tó wà ní ìpínrọ̀ 4.
15 min: Àwọn ìrírí tí àwọn akéde ní. Ké sí àwùjọ láti sọ àwọn ìrírí tó ń gbéni ró tí wọ́n ní, èyí tó jẹ mọ́ lílọ sí àpéjọ àyíká tàbí àpéjọ àkànṣe, ṣíṣe iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́, tàbí ìrírí tí wọ́n ti ní nígbà tí wọ́n ń kópa nínú àwọn ìgbòkègbodò tẹ̀mí mìíràn nínú ọdún tá a wà yìí.
Orin 184 àti àdúrà ìparí.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì bá àwùjọ fọ̀rọ̀ wérọ̀ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.
b Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì bá àwùjọ fọ̀rọ̀ wérọ̀ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.
c Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì bá àwùjọ fọ̀rọ̀ wérọ̀ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.