Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a ó fi lọni ní oṣù July sí September: A lè fi èyíkéyìí nínú àwọn ìwé pẹlẹbẹ olójú ewé 32 tó tẹ̀ lé e yìí lọni: Akoso Naa Ti Yoo Mu Paradise Wá, Gbádùn Iwalaaye Lori Ilẹ Ayé Titilae!, Iwọ Ha Nilati Gbàgbọ́ Ninu Mẹtalọkan Bí?, Ki Ni Ète Igbesi-Aye? Bawo Ni Iwọ Ṣe Le Rí I?, Kí Ní Ń Ṣẹlẹ̀ sí Wa Nígbà Tí A Bá Kú?, Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú?, Orukọ Atọrunwa naa Tí Yoo Wà Titilae, Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi? àti “Sawo O! Emi Nsọ Ohun Gbogbo Di Ọtun.” A tún lè fi àwọn ìwé pẹlẹbẹ wọ̀nyí, Ẹmi Awọn Oku—Wọn Ha Le Ran Ọ Lọwọ Tabi Pa Ọ Lara Bi? Wọn Ha Wa Niti Gidi Bi?, Ìwé Kan Tí Ó Wà fún Gbogbo Ènìyàn, àti Ìwọ́ Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run lọni níbi tó bá ti bá àkókò mu. October: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Níbi tí wọ́n bá ti fi ìfẹ́ hàn, fi ìwé pẹlẹbẹ Béèrè lọni, kí o sì ní in lọ́kàn pé o fẹ́ bẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé.
◼ Bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀sẹ̀ September 16, 2002, a óò bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ ìwé náà, Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kejì, ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ.
◼ Bẹ̀rẹ̀ láti oṣù September, àsọyé tí àwọn alábòójútó àyíká yóò máa sọ fún gbogbo èèyàn yóò jẹ́, “Pa Ìdúró Rẹ Gẹ́gẹ́ Bíi Kristẹni Mọ́!”