ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 12/07 ojú ìwé 5
  • Iṣẹ́ Ìwàásù Tó Lókìkí Tó Báyìí Ò Tíì Wáyé Rí!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Iṣẹ́ Ìwàásù Tó Lókìkí Tó Báyìí Ò Tíì Wáyé Rí!
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2007
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • A Ṣètò Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Láti Wàásù Ìhìn Rere
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2011
  • Àwọn Irin Iṣẹ́ Tó Ń Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́, Tó Ń Súnni Ṣiṣẹ́, Tó sì Tún Ń Fúnni Lókun
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
  • Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa Eto-ajọ ti Ó Wà Lẹhin Orukọ Naa
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • Àwọn Èrọ Tó Ń Gbé Ohùn àti Fídíò Jáde Ń Mú Ká Túbọ̀ Gbádùn Àwọn Àpéjọ Wa
    Bá A Ṣe Ń Ná Owó Tẹ́ Ẹ Fi Ń Ṣètọrẹ
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2007
km 12/07 ojú ìwé 5

Iṣẹ́ Ìwàásù Tó Lókìkí Tó Báyìí Ò Tíì Wáyé Rí!

Ó ti lé lọ́gọ́rùn-ún ọdún báyìí, táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń ṣètò ara wa láti wàásù ìhìn rere fáráyé. (1 Kọ́r. 9:23) Ọgọ́rọ̀ọ̀rún èdè la fi ń wàásù ìhìn rere tó ti wá di iṣẹ́ ìwàásù tó lókìkí jù lọ táyé tíì gbọ́ rí yìí. Ó sì ti tó ọgbọ̀n-lé-rúgba [230] orílẹ̀-èdè tá a ti wàásù ìhìn rere náà dé. (Mát. 24:14) Kí nìdí tó fi pọn dandan pé ká wàásù? Báwo la sì ṣe ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù yìí kárí ayé?

Fídíò wa tá a ṣe sórí àwo DVD, èyí tó dá lórí báwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń pòkìkí ìhìn rere, ìyẹn Jehovah’s Witnesses—Organized to Share the Good News, ló máa dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí, ó sì máa ṣàlàyé lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ nípa bá a ṣe ń bójú tó iṣẹ́ ìsìn wa kárí ayé. Bó o ṣe ń wo fídíò yìí máa fiyè sáwọn ìbéèrè wọ̀nyí: (1) Báwo la ṣe ṣètò àwọn ohun tó jẹ mọ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, báwo la sì ṣe ń bójú tó wọn? (2) Ipa wo làwọn Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ìwé Kíkọ, Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Iṣẹ́ Ìtumọ̀, Ẹ̀ka Tó Ń Yàwòrán àti Ẹ̀ka Tó Ń Ṣe Kásẹ́ẹ̀tì Àtẹ́tísí àti Fídíò, ń kó láti rí i pé a wàásù ìhìn rere fáráyé? (3) Kí nìdí tá a fi ṣètò iṣẹ́ ìtẹ̀wé àti ìpínkiri lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀ bẹ́ẹ̀? (Jòh. 17:3) (4) Ẹ̀dà ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ mélòó là ń tẹ̀ lọ́dọọdún? (5) Àwọn àṣeyọrí wo la ti ṣe nípa lílo àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wa? (Héb. 4:12) (6) Àwọn ètò wo la ti ṣe láti jẹ́ káwọn afọ́jú àtàwọn adití kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? (7) Báwo la ṣe ń rówó tá a fi ń bójú tó iṣẹ́ wa? (8) Àǹfààní wo là ń rí jẹ lára Ẹ̀ka Ìpèsè Ìsọfúnni Ilé Ìwòsàn, Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Iṣẹ́ Ìsìn àti Ẹ̀ka Àpéjọ? (9) Gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, báwo ni fídíò yìí ṣe mú kó o fi ìmọrírì hàn fún (a) ohun tí ètò Jèhófà ń ṣe láti rí i pé a wàásù ìhìn rere yìí? (b) iṣẹ́ táwọn ìdílé Bẹ́tẹ́lì tó lé lọ́gọ́rùn-ún ń ṣe kárí ayé? (d) ẹ̀kọ́ táwọn alábòójútó àtàwọn míṣọ́nnárì ń gbà? (e) àǹfààní tó wà nínú bíbẹ̀rẹ̀ ọjọ́ kọ̀ọ̀kan pẹ̀lú ṣíṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ojoojúmọ́ àti mímúra àwọn ìpàdé tá à ń ṣe lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ sílẹ̀? (ẹ) àwọn àǹfààní tá à ń rí tá a bá ń lọ sáwọn ìpàdé Kristẹni? (f) bí ilẹ̀ ayé ṣe máa rí nígbà tó bá di Párádísè? (Aísá. 11:9) (g) ohun tíwọ fúnra ẹ ń ṣe nínú iṣẹ́ ìkórè tó ń lọ lọ́wọ́ yìí?—Jòh. 4:35.

Àwọn ìrírí tó ta yọ wo lo ní nígbà tó o fi fídíò yìí han àwọn ẹbí, ọ̀rẹ́, ojúlùmọ̀, ìpadàbẹ̀wò àtàwọn tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? O ò ṣe fi fídíò náà han ẹlòmíì láìpẹ́ láìjìnnà, kó o sì wàásù ìhìn rere fún un?—Mát. 28:19, 20.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́