ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g02 5/8 ojú ìwé 22
  • A Bù Kún Ìdánúṣe Tó Lò

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • A Bù Kún Ìdánúṣe Tó Lò
  • Jí!—2002
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa Eto-ajọ ti Ó Wà Lẹhin Orukọ Naa
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
  • “Èyí Mà Rọrùn Gan-an O!”
    Jí!—2016
  • Ipa Tí Àwọn Fídíò Tá A Fi Ń Jẹ́rìí Ń Ní Lórí Àwọn Èèyàn
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
  • A Ṣètò Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Láti Wàásù Ìhìn Rere
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2011
Àwọn Míì
Jí!—2002
g02 5/8 ojú ìwé 22

A Bù Kún Ìdánúṣe Tó Lò

Ọ̀PỌ̀ ÀWỌN Ọ̀DỌ́ LÁÀÁRÍN ÀWỌN ẸLẸ́RÌÍ JÈHÓFÀ ló ní àpẹẹrẹ rere nípa fífi ìgboyà sọ̀rọ̀ nípa ohun tí wọ́n gbà gbọ́. Gbé ti Stella, ọ̀dọ́ kan láti Salonika, ní Gíríìsì yẹ̀ wò. Ó sọ pé: “Nínú ọ̀kan lára àwọn ìpàdé wa, a jíròrò àwọn ọ̀nà tá a lè gbà lo àwọn fídíò wa láti ran àwọn mìíràn lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ Jèhófà. Mo wá ronú nípa bí mo ṣe lè lo fídíò Jehovah’s Witnesses—The Organization Behind the Name. Ní ọjọ́ kejì, mo lọ bá ọ̀gá àgbà ilé ìwé mo sì sọ fún un pé mo fẹ́ kí gbogbo akẹ́kọ̀ọ́ wo fídíò náà. Sí ìyàlẹ́nu mi, ó ní kò burú, táwọn olùkọ́ bá sáà ti gbà.

“Lọ́jọ́ yẹn kan náà, ọ̀gá àgbà ilé ìwé sọ fún mi pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lè wo fídíò náà ní ọ̀sẹ̀ tó máa tẹ̀ lé e, àmọ́ lẹ́yìn aago ìjáde ni ṣá o. Èyí kò dùn mọ́ mi nínú torí mo rò pé àwọn ọmọ kíláàsì mi ò ní lè fi àkókò wọn sílẹ̀ láti wo fídíò náà. Síbẹ̀, lọ́jọ́ kejì, mo sọ fún gbogbo wọn pé kí wọ́n wá wo fídíò náà. Wọ́n gbà pé àwọn á wá, kódà, wọ́n tún pe àwọn ọmọ kíláàsì mìíràn pàápàá. Olùkọ́ mẹ́fà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló wá wò fídíò náà, ẹ̀kọ́ nípa ìsìn ni ọ̀kan lára wọn ń kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́.

“Ńṣe ni gbogbo wọn tẹ́tí bẹ̀lẹ̀jẹ́. Nígbà tá a wò ó tán, ọ̀gá àgbà sọ pé kí n wá ṣe atọ́kùn ètò kan tí wọ́n á ti máa béèrè ìbéèrè, tí màá máa fún wọn ní ìdáhùn. Iṣẹ́ ìyọ̀ǹda ara ẹni tí wọ́n ń ṣe ní orílé iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tó wà nínú fídíò náà wú ọ̀pọ̀ lórí gan-an. Akẹ́kọ̀ọ́ kan sọ pé: ‘Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọn kì í gbowó oṣù, tayọ̀tayọ̀ ni wọ́n ń ṣiṣẹ́ wọn!’

“Mo sọ fún gbogbo àwọn tó wá wo fídíò náà nípa àwọn ìtẹ̀jáde wa tá a gbé ka Bíbélì. Mo tún fún wọn ní Ìròyìn Ìjọba, nọnba 36, tó ní àkọlé náà ‘Mìlẹ́níọ̀mù Tuntun—Kí Ni Ká Máa Retí?’ Ọ̀gá àgbà sọ pé kí n fún òun sí i kóun lè fún àwon olùkọ́ tí kò sí níbẹ̀.

“Lẹ́yìn náà, ọ̀pọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ bá àwọn ọ̀rẹ́ wọn sọ̀rọ̀ nípa fídíò náà. Inú mi dùn gan-an pé mo lo àǹfààní yìí láti wàásù. Àwọn ọmọ kíláàsì mi túbọ̀ ń fi ọ̀wọ̀ fún mí. Èyí tó wá ṣe pàtàkì jù lọ ni pé wọ́n ń fi ọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run tí mò ń sìn!”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́