Mú Kí Ìgbéyàwó Rẹ Jẹ́ Ìsopọ̀ Wíwàpẹ́títí
“Ohun tí Ọlọrun bá so ṣọ̀kan, kí ènìyàn kí ó máṣe yà wọ́n.”—MATTEU 19:6.
1. Kí ni ìdí náà fún àṣeyọrísírere nínú ìgbéyàwó láàárín àwọn Kristian lónìí?
Ọ̀PỌ̀ ẹgbẹẹgbẹ̀rún lára àwọn ènìyàn Jehofa lónìí ń gbádùn ìgbéyàwó tí ń mú ìtẹ́lọ́rùn wá tí ó sì ń wà pẹ́. Bí ó ti wù kí ó rí, irúfẹ́ àṣeyọrísírere tí ó tànkálẹ̀ bẹ́ẹ̀ kìí ṣe èèṣì rárá. Ìgbéyàwó Kristian ń yọrísírere nígbà tí àwọn tọkọtaya náà bá (1) ń bọ̀wọ̀ fún ojú-ìwòye Ọlọrun nípa ìgbéyàwó àti (2) ń sakun láti gbé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ó ṣetán, Ọlọrun fúnraarẹ̀ ni ó fi ìdí ìṣètò ìgbéyàwó múlẹ̀. Òun ni Ẹni náà ‘ti a ń fi orúkọ rẹ̀ pe gbogbo ìdílé tí ń bẹ ní ayé.’ (Efesu 3:14, 15) Níwọ̀n bí Jehofa ti mọ ohun tí ó ní nínú láti ṣe àṣeyọrísírere nínú ìgbéyàwó, a ṣe araawa ní àǹfààní nípa títẹ̀lé àwọn ìtọ́sọ́nà rẹ̀.—Isaiah 48:17.
2. Kí ni àwọn àbájáde kíkùnà láti fi àwọn ìlànà Bibeli sílò nínú ìgbéyàwó?
2 Ní ìdàkejì, ìkùnà láti fi àwọn ìlànà Bibeli sílò lè yọrísí ìgbéyàwó aláìrójú-ráyè. Àwọn ògbógi kan gbàgbọ́ pé iye tí ó pọ̀ tó ìdáméjì nínú mẹ́ta àwọn wọnnì tí ń ṣègbéyàwó ní United States lónìí yóò kọ araawọn sílẹ̀ ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀. Àní àwọn Kristian pàápàá kò bọ́ lọ́wọ́ àwọn másùnmáwo àti ìgalára “awọn àkókò lílekoko tí ó nira lati bálò” wọ̀nyí. (2 Timoteu 3:1, NW) Ìnira níti ìṣúnná-owó àti àwọn ìkìmọ́lẹ̀ ní ibi iṣẹ́ lè ní ìyọrísí eléwu tiwọn lórí ìgbéyàwó. Àwọn Kristian kan ni ìkùnà àwọn alájọṣègbéyàwó wọn láti fi àwọn ìlànà Bibeli sílò tún ti jákulẹ̀ lọ́nà tí ń mú ìbànújẹ́ kíkorò wá. Kristian aya kan sọ pé, “Mo nífẹ̀ẹ́ Jehofa, ṣùgbọ́n ìgbéyàwó mi ti kún fún ìṣòro fún 20 ọdún. Ọkọ mi jẹ́ onímọtara-ẹni-nìkan kò sì fẹ́ láti ṣe ìyípadà èyíkéyìí. Mo nímọ̀lára pé a há mi mọ́.” Àwọn ọkọ àti aya tí wọ́n jẹ́ Kristian tí wọ́n ti sọ ìmọ̀lára bí èyí jáde kò kéré rárá. Kí ni ó ṣàìtọ́? Kí sì ni ó lè mú kí ìgbéyàwó kan má di ti ìṣọ̀tá onídàágunlá tàbí ti ìgbóguntini ní gbangba wálíà?
Ìwàpẹ́títí Ìgbéyàwó
3, 4. (a) Kí ni ọ̀pá ìdíwọ̀n Ọlọrun fún ìgbéyàwó? (b) Èéṣe tí ìwàpẹ́títí ìgbéyàwó fi bá ìdájọ́-òdodo mu tí ó sì ṣàǹfààní?
3 Àní lábẹ́ àwọn àyíká ipò tí ó dára jùlọ pàápàá, ìgbéyàwó jẹ́ ìsopọ̀ àwọn ènìyàn aláìpé. (Deuteronomi 32:5) Nítorí èyí ni aposteli Paulu fi wí pé “awọn wọnnì tí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ [gbéyàwó] yoo ní ìpọ́njú ninu ẹran-ara wọn.” (1 Korinti 7:28, NW) Àwọn àyíká ipò díẹ̀ tí ń pinnilẹ́mìí tilẹ̀ lè yọrísí ìpínyà tàbí ìkọ̀sílẹ̀. (Matteu 19:9; 1 Korinti 7:12-15) Bí ó ti wù kí ó rí, nínú àwọn ọ̀ràn tí ó pọ̀ jùlọ àwọn Kristian ń fi ìmọ̀ràn Paulu sílò pé: “Kí aya kí ó máṣe fí ọkọ rẹ̀ sílẹ̀ . . . , kí ọkọ kí ó máṣe kọ aya rẹ̀ sílẹ̀.” (1 Korinti 7:10, 11) Nítòótọ́, ìgbéyàwó ni a retí pé kí ó jẹ́ ìdè wíwàpẹ́títí, nítorí tí Jesu Kristi polongo pé: “Ohun tí Ọlọrun bá so ṣọ̀kan, kí ènìyàn kí ó máṣe yà wọ́n.”—Matteu 19:6.
4 Lójú ẹnìkan tí ó lérò pé a ti há òun mọ́ sínú ìgbéyàwó tí ń kóguntini àti aláìnífẹ̀ẹ́, ọ̀pá ìdíwọ̀n Jehofa lè dàbí èyí tí ó lekoko tí kò sì lọ́gbọ́n nínú. Ṣùgbọ́n kò rí bẹ́ẹ̀. Ìwàpẹ́títí ìdè ìgbéyàwó ń sún tọkọtaya olùfọkànsìn Ọlọrun láti ko àwọn ìṣòro wọn lójú kí wọ́n sì yanjú rẹ̀, kàkà kí wọ́n fi ìwàǹwára pa àwọn ojúṣe wọn tì sápákan nígbà tí ìṣòro bá kọ́kọ́ farahàn. Ọkùnrin kan tí ó ti ṣègbéyàwó fún ohun tí ó ju 20 ọdún lọ sọ ọ́ lọ́nà yìí: “Ìwọ kò lè yẹra fún àwọn àkókò ìṣòro. Kìí ṣe gbogbo ìgbà ni ẹ óò máa láyọ̀ pẹ̀lú araayín. Ìgbà yẹn gan-an ni ẹ̀jẹ́ ṣe pàtàkì nítòótọ́.” Àmọ́ ṣáá ó, àwọn tọkọtaya tí wọ́n jẹ́ Kristian nímọ̀lára pé ojúṣe wọn àkọ́kọ́ jẹ́ sí Jehofa Ọlọrun, Olùpilẹ̀ṣẹ̀ ìgbéyàwó.—Fiwé Oniwasu 5:4.
Ipò-Orí àti Ìtẹríba
5. Kí ni díẹ̀ lára ìmọ̀ràn Paulu fún àwọn ọkọ àti àwọn aya?
5 Nítorí náà, nígbà tí àwọn ìṣòro bá dìde, kì yóò jẹ́ àkókò fún wíwá ọnà àti yọwọ́-yọsẹ̀, bíkòṣe ọ̀nà dídára jùlọ láti fi ìmọ̀ràn Ọ̀rọ̀ Ọlọrun sílò. Fún àpẹẹrẹ, ṣe ìgbéyẹ̀wò àwọn ọ̀rọ̀ Paulu wọ̀nyí tí a rí nínú Efesu 5:22-25, 28, 29: “Ẹ̀yin aya, ẹ máa tẹríba fún àwọn ọkọ yín, gẹ́gẹ́ bíi fún Oluwa. Nítorí pé ọkọ níí ṣe orí aya, gẹ́gẹ́ bí Kristi ti ṣe orí ìjọ ènìyàn rẹ̀: òun sì ni Olùgbàlà ara. Nítorí náà gẹ́gẹ́ bí ìjọ ti tẹríba fún Kristi, bẹ́ẹ̀ sì ni kí àwọn aya kí ó máa ṣe sí ọkọ wọn ní ohun gbogbo. Ẹ̀yin ọkọ, ẹ fẹ́ràn àwọn aya yín, gẹ́gẹ́ bí Kristi sì ti fẹ́ràn ìjọ, tí ó sì fi ara rẹ̀ fún un. Bẹ́ẹ̀ ni ó tọ́ kí àwọn ọkùnrin kí ó máa fẹ́ràn àwọn aya wọn gẹ́gẹ́ bí ara àwọn tìkáraawọn. Ẹni tí ó bá fẹ́ràn aya rẹ̀, ó fẹ́ràn òun tìkáraarẹ̀. Nítorí kò sí ẹnìkan tí ó ti kórìíra ara rẹ̀; bíkòṣe pé kí ó máa bọ́ ọ kí ó sì máa ṣìkẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Kristi sì ti ń ṣe sí ìjọ.”
6. Báwo ni àwọn Kristian ọkọ ṣe níláti yàtọ̀ sí àwọn ọkùnrin inú ayé?
6 Àwọn ọkùnrin sábà máa ń ṣi ọlá-àṣẹ wọn gẹ́gẹ́ bí ọkọ lò tí wọ́n sì máa ń jẹgàba lé àwọn aya wọn lórí. (Genesisi 3:16) Bí ó ti wù kí ó rí, Paulu rọ àwọn Kristian ọkọ láti yàtọ̀ sí àwọn ọkùnrin nínú ayé, kí wọ́n fi ìwà jọ Kristi, kí wọ́n máṣe jẹ́ òṣìkà agbonimọ́lẹ̀ tí ń darí gbogbo apá ìgbésí-ayé aya wọn. Dájúdájú, ọkùnrin náà Jesu Kristi kò fìgbàkan rí lekoko tàbí kí ó jẹgàba lénilórí. Ó fi ọlá àti ọ̀wọ̀ bá àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lò, ní sísọ pé: “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣíṣẹ̀ẹ́, tí a sì di ẹrù wúwo lé lórí, èmi óò sì fi ìsinmi fún yín. Ẹ gba àjàgà mi sí ọrùn yín, kí ẹ sì máa kọ́ ẹ̀kọ́ lọ́dọ̀ mi; nítorí onínú tútù àti onírẹ̀lẹ̀ ọkàn ni èmi.”—Matteu 11:28, 29.
7. Báwo ni ọkùnrin kan ṣe lè fi ọlá fún aya rẹ̀ nígbà tí obìnrin náà bá níláti ṣiṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́?
7 Kristian ọkọ kan ń fi ọlá fún aya rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi fún ohun èlò kan tí kò ní agbára. (1 Peteru 3:7) Fún àpẹẹrẹ, kání obìnrin náà níláti ṣiṣẹ́ oúnjẹ-òòjọ́. Òun yóò gba èyí rò, ní ṣíṣe ìrànlọ́wọ́ àti jíjẹ́ olùgbatẹnirò bí ó bá ti lè ṣeéṣe tó. Ìdí pàtàkì kan tí àwọn obìnrin sọ pé ó ń fa ìkọ̀sílẹ̀ ni pé àwọn ọkọ wọn ṣàìnáání àwọn ọmọ àti ìdílé. Nítorí náà, Kristian ọkọ kan ń wá ọ̀nà láti ran aya rẹ̀ lọ́wọ́ nínú ilé ní àwọn ọ̀nà tí ó nítumọ̀ tí ó ṣàǹfààní fún gbogbo ìdílé náà.
8. Kí ni ìtẹríba ní nínú fún àwọn Kristian aya?
8 Jíjẹ́ ẹni tí a bálò pẹ̀lú ọlá ń mú kí ó túbọ̀ rọrùn fún àwọn aya tí wọ́n jẹ́ Kristian láti wà ní ìtẹríba fún àwọn ọkọ wọn. Bí ó ti wù kí ó rí, èyí kò túmọ̀sí jíjẹ́ ẹrú paraku. Ọlọrun kò pàṣẹ pé kí aya kan jẹ́ ẹrú, bíkòṣe “àṣekún” (“olùbádọ́gba,” àkíyèsí ẹsẹ̀ ìwé), tí ń túmọ̀sí ohun yíyẹ kan fún ọkùnrin náà. (Genesisi 2:18) Ní Malaki 2:14 (NW), a sọ̀rọ̀ nípa aya kan gẹ́gẹ́ bí “alájọṣepọ̀” pẹ̀lú ọkùnrin. Nítorí ìdí èyí, àwọn aya ní àwọn àkókò tí a kọ Bibeli gbádùn òmìnira púpọ̀ wọ́n sì lè ṣe yíyàn. Nípa ti “obìnrin oníwà rere,” Bibeli sọ pé: “Àyà ọkọ rẹ̀ gbẹ́kẹ̀lé e láìbẹ̀rù.” Nítòótọ́, ní ìkáwọ́ rẹ̀ ni àwọn ọ̀ràn gbogbogbòò tí ó jẹ mọ́ mímójútó agbo-ilé, ṣíṣàbójútó oúnjẹ rírà, dídúnàádúrà fún ríra dúkìá ilé àti ilẹ̀, àti mímójútó iṣẹ́-òwò kékeré kan wà.—Owe 31:10-31.
9. (a) Báwo ni àwọn obìnrin olùbẹ̀rù Ọlọrun ní àwọn àkókò tí a kọ Bibeli ṣe fi ìtẹríba tòótọ́ hàn? (b) Kí ni ó lè ran Kristian aya kan lọ́wọ́ láti jẹ́ ẹni tí ń fi ìtẹríba hàn lónìí?
9 Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, aya tí ó jẹ́ olùbẹ̀rù Ọlọrun náà mọ ipò ọlá-àṣẹ ọkọ rẹ̀ dájú. Fún àpẹẹrẹ, Sara “gbọ́ ti Abrahamu, tí ó ń pè é ní oluwa,” kìí ṣe gẹ́gẹ́ bí ìwà ẹyẹ kan tí a wulẹ̀ ń dá láṣà, bíkòṣe gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà láti gbà fi ìwà ìtẹríba rẹ̀ hàn pẹ̀lú òtítọ́-inú. (1 Peteru 3:6; Genesisi 18:12) Ó tún fi pẹ̀lú ìfínnúfíndọ̀ fi ilé rẹ̀ tí ó tura ní ìlú-ńlá Uri sílẹ̀ kí ó baà lè gbé pẹ̀lú ọkọ rẹ̀ nínú àgọ́. (Heberu 11:8, 9) Ṣùgbọ́n ìtẹríba kò túmọ̀sí pé aya kan kò lè gbé ìgbésẹ̀ yíyẹ nígbà tí ó bá pọndandan. Nígbà tí Mose kùnà láti ṣègbọràn sí òfin Ọlọrun lórí ìkọlà, aya rẹ̀, Sippora, dènà ìjábá nípa gbígbégbèésẹ̀ tìpinnu tìpinnu. (Eksodu 4:24-26) Púpọ̀ síi wémọ́ ọn ju títẹ́ ọkùnrin aláìpé kan lọ́rùn. Àwọn aya gbọ́dọ̀ “tẹríba fún àwọn ọkọ [wọn], gẹ́gẹ́ bíi fún Oluwa.” (Efesu 5:22) Nígbà tí Kristian aya kan bá ronú ní ìlà pẹ̀lú ipò-ìbátan rẹ̀ pẹ̀lú Ọlọrun, èyí ń ràn án lọ́wọ́ láti gbójúfo àwọn àléébù tí kò tó nǹkan àti àwọn ìkù-díẹ̀-ká-à-tó ọkọ rẹ̀, àní gẹ́gẹ́ bí òun náà ti níláti ṣe nínú ìbálò rẹ̀ pẹ̀lú aya rẹ̀.
Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀—Ẹ̀jẹ̀-Ìyè fún Ìgbéyàwó
10. Báwo ni ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ ti ṣe pàtàkì tó fún ìgbéyàwó?
10 Nígbà tí a béèrè ìdí kanṣoṣo tí ó tóbi jùlọ tí ń mú kí àwọn tọkọtaya pínyà lọ́wọ́ rẹ̀, aṣojú ìkọ̀sílẹ̀ lábẹ́ òfin kan dáhùn pé: “Àìní agbára náà láti jùmọ̀sọ̀rọ̀ láìlábòsí, kí wọ́n finúhàn, kí wọ́n sì fi ọwọ́ mú araawọn lẹ́nìkínní kejì gẹ́gẹ́ bí ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ jùlọ nínú ìbálò wọn.” Bẹ́ẹ̀ni, ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ ni ẹ̀jẹ̀-ìyè fún ìgbéyàwó lílágbára kan. Gẹ́gẹ́ bí Bibeli ti sọ, “ìjákulẹ̀ ìwéwèé wà níbi tí kò ti sí ọ̀rọ̀ àṣírí.” (Owe 15:22, NW) Àwọn ọkọ àti àwọn aya gbọ́dọ̀ jẹ́ ‘ọ̀rẹ́ àfinúhàn,’ ní gbígbádùn ipò-ìbátan kòríkòsùn, tí ó jẹ́ ọlọ́yàyà. (Owe 2:17) Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn tọkọtaya máa ń lọ́ra láti jùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀, àti nípa bẹ́ẹ̀ ìfìbínúhàn túbọ̀ di ìbànújẹ́ títí tí ìbúgbàù ìbínú tí ó lè ba nǹkan jẹ́ yóò fi wáyé. Tàbí kí àwọn alájọṣègbéyàwó máa fi ìwà ẹ̀yẹ oréfèé ṣe bojúbojú, nígbà tí ó jẹ́ pé wọ́n takété pátápátá sí araawọn níti ṣíṣàjọpín èrò ìmọ̀lára.
11. Báwo ni a ṣe lè mú ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ láàárín ọkọ àti aya sunwọ̀n síi?
11 Apákan ìṣòro náà dàbí ẹni pé àwọn ọkùnrin àti obìnrin máa ń sábà ní ọ̀nà ìgbàjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ tí kò báramu. Èyí tí ó pọ̀ jùlọ nínú àwọn obìnrin ni ó máa ń tẹ́lọ́rùn jùlọ láti jíròrò àwọn ìmọ̀lára, nígbà tí ó jẹ́ pé àwọn ọkùnrin sábà máa ń yàn láti jíròrò àwọn kókó. Àwọn obìnrin túbọ̀ nítẹ̀sí láti fi ẹ̀mí ìfọ̀rànrora ẹni wò hàn, nígbà tí àwọn ọkùnrin máa ń nítẹ̀sí láti wá kí wọ́n sì pèsè ojútùú sí nǹkan. Síbẹ̀, agbára náà fún ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ wà níbi tí àwọn alájọṣègbéyàwó méjèèjì náà bá ti pinnu láti jẹ́ ẹni tí ó “yára láti gbọ́, kí ó lọ́ra láti fọhùn, kí ó lọ́ra láti bínú.” (Jakọbu 1:19) Ẹ máa wo ojú ara yín kí ẹ sì máa tẹ́tísílẹ̀ níti gidi. Ẹ jẹ́ kí ẹnìkínní kejì sọ ti inú rẹ̀ jáde nípasẹ̀ àwọn ìbéèrè tí ó fi ìgbatẹnirò hàn. (Fiwé 1 Samueli 1:8; Owe 20:5.) Dípò gbígbìyànjú láti pèsè ojútùú ní kóyákóyá nígbà tí ẹnìkejì rẹ nínú ìgbéyàwó bá ṣípayá ìṣòro kan, tẹ́tísílẹ̀ dáradára bí o ti ń ṣiṣẹ́ láti yanjú àwọn ọ̀ràn. Kí ẹ sì fi pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ gbàdúrà papọ̀, ní wíwá ìtọ́sọ́nà àtọ̀runwá.—Orin Dafidi 65:2; Romu 12:12.
12. Báwo ni àwọn alájọṣègbéyàwó tí wọ́n jẹ́ Kristian ṣe lè ra ìgbà padà fún araawọn?
12 Ní ìgbà mìíràn ó máa ń dàbí ẹni pé àwọn pákáǹleke àti ìgalára ìgbésí-ayé máa ń mú kí àwọn ẹnìkejì ẹni nínú ìgbéyàwó ní kìkì àkókò tàbí okun tí kò tó nǹkan fún ọ̀rọ̀ àjọsọ tí ó ní ìtumọ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, bí àwọn Kristian bá níláti pa ìgbéyàwó wọn mọ́ gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó lọ́lá kí wọ́n sì dáàbòbò ó kúrò lọ́wọ́ ìsọdẹ̀gbin, wọ́n gbọ́dọ̀ máa báa nìṣó ní wíwà tímọ́tímọ́ pẹ̀lú araawọn. Wọ́n níláti fọwọ́ mú ìsopọ̀ wọn gẹ́gẹ́ bí ohun kan tí ó ṣeyebíye, tí ó níyelórí, wọ́n sì gbọ́dọ̀ ra ìgbà padà fún un àti fún araawọn. (Fiwé Kolosse 4:5.) Nínú àwọn ọ̀ràn kan ojútùú náà sí wíwá àkókò fún ọ̀rọ̀ àjọsọ gbígbámúṣé lè jẹ́ ohun rírọrùn kan bíi pípa tẹlifíṣọ̀n. Jíjókòó papọ̀ láti jùmọ̀ mu ife tíì tàbí kọfí déédéé lè ran àwọn alájọṣègbéyàwó lọ́wọ́ láti jùmọ̀ sọ èrò ìmọ̀lára wọn papọ̀. Ní irú àwọn àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ wọ́n lè ‘fikùnlukùn’ lórí onírúurú àwọn ọ̀ràn ìdílé. (Owe 13:10) Ẹ sì wo bí ó ti bọ́gbọ́nmu tó láti mú àṣà sísọ̀rọ̀ lórí àwọn ohun tí ń fa ìbínú tàbí èdèkòyédè tí kò tó nǹkan dàgbà ṣáájú kí wọ́n tó di okùnfà pàtàkì fún pákáǹleke!—Fiwé Matteu 5:23, 24; Efesu 4:26.
13. (a) Àpẹẹrẹ wo ni Jesu fi lélẹ̀ níti àìfọ̀rọ̀-sábẹ́-ahọ́n àti àìṣàbòsí? (b) Kí ni àwọn ọ̀nà díẹ̀ tí àwọn alájọṣègbéyàwó lè gbà láti fàmọ́ araawọn tímọ́tímọ́?
13 Ọkùnrin kan jẹ́wọ́ pé: “Ó ṣòro gidigidi fún mi, lọ́pọ̀ ìgbà, láti sọ ohun tí ń bẹ lọ́kàn mi níti gidi kí n sì sọ fún [aya mi] bí ìmọ̀lára mi ti rí gẹ́lẹ́.” Ṣùgbọ́n, ṣíṣí ara ẹni payá ni kọ́kọ́rọ́ pàtàkì náà sí mímú ìbátan tímọ́tímọ́ dàgbà. Ṣàkíyèsí bí Jesu ti jẹ́ aláìfọ̀rọ̀-sábẹ́-ahọ́n àti aláìṣàbòsí tó pẹ̀lú àwọn tí wọn yóò di mẹ́ḿbà ẹgbẹ́ ìyàwó rẹ̀. Ó wí pé: “Èmi kò pè yín ní ọmọ-ọ̀dọ̀ mọ́; nítorí ọmọ-ọ̀dọ̀ kò mọ ohun tí oluwa rẹ̀ ń ṣe: ṣùgbọ́n èmi pè yín ní ọ̀rẹ́; nítorí ohun gbogbo tí mo ti gbọ́ láti ọ̀dọ̀ Baba mi wá, mo ti fihàn fún yín.” (Johannu 15:15) Nítorí náà wo alábàáṣègbéyàwó rẹ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rẹ́. Fi ìgbẹ́kẹ̀lé àwọn ìmọ̀lára rẹ sínú ẹnìkejì rẹ nínú ìgbéyàwó. Sapá láti sọ “àwọn ọ̀rọ̀ ìfẹ́ràn” rírọrùn, aláìlábòsí. (Orin Solomoni 1:2, NW) Ní àwọn ìgbà mìíràn, ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ láìfọ̀rọ̀sábẹ́-ahọ́n lè dàbí èyí tí ó nira, ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn tọkọtaya méjèèjì bá ṣe ìsapá tí ó yẹ, ọ̀pọ̀ nǹkan ni wọn yóò ṣe àṣeyọrí rẹ̀ sí ìlà mímú kí ìgbéyàwó wọn jẹ́ ìsopọ̀ wíwàpẹ́títí.
Bíbójútó Èdèkòyedè
14, 15. Báwo ni a ṣe lè yẹra fún aáwọ̀?
14 Ó dájú pé èdèkòyedè tí kò mú àbòsí lọ́wọ́ yóò máa jẹyọ láti ìgbà dé ìgbà. Ṣùgbọ́n ìyẹn kò sọ pé kí ìfàsẹ́yìn bá ilé rẹ tí yóò fi di ‘ilé tí ó kún fún ìjà.’ (Owe 17:1) Ṣọ́ra láti máṣe jíròrò àwọn ọ̀ràn ẹlẹgẹ́ ní etígbọ̀ọ́ àwọn ọmọdé, kí o sì fi ìgbatẹnirò hàn fún ìmọ̀lára ẹnìkejì rẹ. Nígbà tí Rakeli sọ ìmọ̀lára ìdààmú rẹ̀ jáde nítorí ipò àgàn rẹ̀ tí ó sì sọ pé kí Jakobu fún òun ní ọmọ, ó dáhùnpadà tìbínú tìbínú pé: “Èmi ha wà ní ipò Ọlọrun, ẹni tí ó dù ọ́ ní ọmọ bíbí?” (Genesisi 30:1, 2) Bí àwọn ìṣòro abẹ́lé bá dìde, ìṣòro náà ni kí o gbéjàkò, kìí ṣe ẹni tí ó fà á. Nígbà tí ẹ bá ń jùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ ní ìdákọ́ńkọ́, ẹ yẹra fún “sísọ̀rọ̀ láìnírònú” tàbí jíjá ọ̀rọ̀ gbà mọ́ araayín lẹ́nu lọ́nà tí kò yẹ.—Owe 12:18, NW.
15 Òtítọ́ ni pé, ìwọ lè ní ìmọ̀lára lílágbára nípa ojú-ìwòye rẹ, ṣùgbọ́n ìwọ̀nyí ni o lè sọ láìsí “ìwà kíkorò, àti ìbínú, àti ìrunú, àti ariwo, àti ọ̀rọ̀ búburú.” (Efesu 4:31) Ọkọ kan sọ pé, “Ẹ jíròrò àwọn ìṣòro yín pẹ̀lú ohùn tí ẹ fi ń bárasọ̀rọ̀ déédéé. Bí ohùn ẹnìkan bá ń ṣe fatafata, ẹ dá ìjíròrò náà dúró. Ẹ padà wá lẹ́yìn àkókò kúkúrú. Kí ẹ sì tún bẹ̀rẹ̀.” Owe 17:14 fúnni ní ìmọ̀ràn rere yìí: “Fi ìjà sílẹ̀ kí ó tó di ńlá.” Ẹ gbìyànjú láti tún àwọn ọ̀rọ̀ jíròrò nígbà tí ara ẹ̀yin méjèèjì bá ti balẹ̀.
Ẹ Jẹ́ Olóòótọ́ sí Araayín
16. Èéṣe ti panṣágà fi jẹ́ ọ̀ràn kan tí ó wúwo tóbẹ́ẹ̀?
16 Heberu 13:4 sọ pé: “Kí ìgbéyàwó kí ó ní ọlá láàárín gbogbo ènìyàn, kí àkéte sì jẹ́ aláìléèérí: nítorí àwọn àgbèrè àti àwọn panṣágà ni Ọlọrun yóò dá lẹ́jọ́.” Panṣágà jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ sí Ọlọrun. Ó tún máa ń ba ìgbéyàwó jẹ́. (Genesisi 39:9) Olùgbaninímọ̀ràn lórí ìgbéyàwó kan kọ̀wé pé: “Ní gbàrà tí ó bá ti di mímọ̀, panṣágà máa ń kọlu gbogbo mẹ́ḿbà ìdílé bí ìjì-líle àjàyíká kan, tí ń ba àwọn ilé jẹ́, tí ń fọ́ ìgbẹ́kẹ̀lé àti ọ̀wọ̀ ara-ẹni túútúú, tí ó sì ń fi ojú àwọn ọ̀dọ́ rí màbo.” Oyún tàbí òkùnrùn tí ìbálòpọ̀ ń ta látaré tún lè jẹyọ.
17. Báwo ni a ṣe lè yẹra fún tàbí kí a kọ òòfà-ọkàn tí ó tẹ síhà panṣágà sílẹ̀?
17 Àwọn ènìyàn kan ń mú òòfà-ọkàn tí ó tẹ̀ síhà panṣágà dàgbà nípa fífi ojú-ìwòye oníwà-ìbàjẹ́ tí ayé ń fihàn nínú àwọn ìwé, lórí tẹlifíṣọ̀n, àti nínú àwọn àwòrán sinimá bọ́ araawọn. (Galatia 6:8) Ṣùgbọ́n, àwọn olùṣèwádìí sọ pé panṣágà sábà máa ń wáyé kìí wulẹ̀ ṣe nítorí ìfẹ́-ọkàn fún ìbálòpọ̀ ṣùgbọ́n nítorí àìní náà tí a lérò pé ó wà láti fi ẹ̀rí hàn pé olúwarẹ̀ ṣì fanimọ́ra tàbí láti inú ìfẹ́-ọkàn náà pé kí a túbọ̀ fẹ́ràn ẹni. (Fiwé Owe 7:18.) Ohun yòówù kí ìdí náà jẹ́, Kristian kan gbọ́dọ̀ kọ àwọn àlá-asán oníwà pálapàla sílẹ̀. Fi àìlábòsí jíròrò àwọn ìmọ̀lára rẹ pẹ̀lú ẹnìkejì rẹ. Bí ó bá pọndandan, wá ìrànlọ́wọ́ lọ́dọ̀ àwọn alàgbà ìjọ. Lọ́nà dídára ṣíṣe bẹ́ẹ̀ lè ṣèdíwọ́ fún ṣíṣubú sínú ẹ̀ṣẹ̀. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, àwọn Kristian gbọ́dọ̀ ṣọ́ra nínú ìbálò wọn pẹ̀lú àwọn ẹ̀yà òdìkejì. Yóò lòdì sí ìlànà Ìwé Mímọ́ láti ṣègbéyàwó pẹ̀lú ẹnìkan ṣùgbọ́n kí a máa ní ìfẹ́ gbígbóná sí ẹlòmíràn. (Jobu 31:1; Matteu 5:28) Ní pàtàkì ni àwọn Kristian níláti ṣọ́ra nípa mímú òòfà-ọkàn níti èrò-ìmọ̀lára dàgbà pẹ̀lú àwọn alábàáṣiṣẹ́pọ̀ wọn. Jẹ́ kí irú ipò-ìbátan bẹ́ẹ̀ jẹ́ ti ọlọ́yàyà ṣùgbọ́n kí ó jọ ti òṣìṣẹ́-sí-òṣìṣẹ́.
18. Kí ni ó sábà máa ń jẹ́ gbòǹgbò àwọn ìṣòro ìbálòpọ̀ nínú ìgbéyàwó, báwo ni a sì ṣe lè yanjú ìwọ̀nyí?
18 Ìdáàbòbò kan tí ó túbọ̀ pọ̀ síi ni ipò-ìbátan ọlọ́yàyà àti onítùúraká pẹ̀lú ẹnìkejì ẹni. Ọ̀pọ̀ àwọn olùṣèwádìí sọ pé àwọn ìṣòro ìbálòpọ̀ nínú ìgbéyàwó kìí sábà jẹ́ ti ara ìyára ṣùgbọ́n wọ́n sábà máa ń jẹyọ láti inú àìní ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ tí ó dára tó. Irú àwọn ìṣòro wọ̀nyí a máa ṣọ̀wọ́n nígbà tí tọkọtaya bá ń jùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ ní fàlàlà tí wọ́n si ń ṣe ojúṣe ìgbéyàwó gẹ́gẹ́ bí ìfìfẹ́hàn dípò kí ó jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ohun àìgbọ́dọ̀máṣe.a Lábẹ́ irú àwọn àyíká-ipò yíyẹ bẹ́ẹ̀, ipò-ìbátan tímọ́tímọ́ lè ṣiṣẹ́ láti fún ìdè ìgbéyàwó lókun.—1 Korinti 7:2-5; 10:24.
19. Kí ni “ìdè ìrẹ́pọ̀ pípé” kan jẹ́, ipa wo ni ó sì lè ní lórí ìgbéyàwó?
19 Ìfẹ́ ni ó jẹ́ “ìdè ìrẹ́pọ̀ pípé” láàárín ìjọ Kristian. Nípa mímú ìfẹ́ dàgbà, àwọn tọkọtaya kan tí wọ́n jẹ́ olùfọkànsìn Ọlọrun lè ‘máa bá a lọ ní fífaradà á fún araawọn lẹ́nìkínní kejì kí wọ́n sì máa dáríji ara wọn fàlàlà lẹ́nìkínní kejì.’ (Kolosse 3:13, 14, NW) Ìfẹ́ tí a gbékarí ìlànà ń wá ire àwọn ẹlòmíràn. (1 Korinti 13:4-8) Ẹ mú irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ dàgbà. Yóò ràn yín lọ́wọ́ láti fún ìdè ìgbéyàwó yín lókun. Ẹ fi àwọn ìlànà Bibeli sílò nínú ìgbésí-ayé ìṣègbéyàwó yín. Bí ẹ bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìgbéyàwó yín yóò jásí ìsopọ̀ wíwàpẹ́títí yóò sì mú ìyìn àti ọlá wá fún Jehofa Ọlọrun.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ náà “Ijumọsọrọpọ—Ju Kìkì Ọ̀rọ̀ Sísọ Lasan Lọ,” tí ó farahàn nínú Ilé-Ìṣọ́nà August 1, 1993, fihàn bí àwọn tọkọtaya ṣe lè borí àwọn ìṣòro ní agbègbè yìí.
Báwo Ni Ìwọ Yóò Ṣe Dáhùn?
◻ Èéṣe tí ìgbéyàwó fi níláti jẹ́ ìdè wíwàpẹ́títí?
◻ Kí ni ojú-ìwòye Ìwé Mímọ́ nípa ipò-orí àti ìtẹríba?
◻ Báwo ni àwọn tọkọtaya ṣe lè mú ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ sunwọ̀n síi?
◻ Báwo ni àwọn tọkọtaya ṣe lè bójútó èdèkòyedè ní ọ̀nà kan tí ó jẹ́ ti Kristian?
◻ Kí ni yóò ṣèrànlọ́wọ́ láti fún ìdè ìgbéyàwó lókun?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Bí aya rẹ̀ bá níláti ṣiṣẹ́ oúnjẹ-òòjọ́, Kristian ọkọ kan kì yóò jẹ́ kí ó ru ẹrù iṣẹ́ ju bí ó ti yẹ lọ