ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwbq àpilẹ̀kọ 184
  • Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Ìgbéyàwó?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Ìgbéyàwó?
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun tí Bíbélì sọ
  • Ìlànà wo ni Ọlọ́run fún àwọn tó ṣègbéyàwó?
  • Kí ni Bíbélì sọ nípa ìpínyà àti ìkọ̀sílẹ̀?
  • Ṣó yẹ kí tọkọtaya forúkọ ìgbéyàwó wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin kó tó ní ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run?
  • Kí ni Bíbélì sọ pé ó jẹ́ ojúṣe ọkọ àti aya nínú ìgbéyàwó?
  • Ṣé Ọlọ́run sọ pé káwọn tó ṣègbéyàwó lóde òní bímọ?
  • Báwo ni Bíbélì ṣe lè ran ìdílé mi lọ́wọ́?
  • Ohun Táá Jẹ́ Kí Tọkọtaya Bára Wọn Kalẹ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2016
  • Bí Ìgbéyàwó Ṣe Lè Wà Pẹ́ Títí
    Jí!—2012
  • Bí Tọkọtaya Ṣe Lè Ṣera Wọn Lọ́kan Kí Wọ́n sì Láyọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Mú Kí Ìgbéyàwó Rẹ Jẹ́ Ìsopọ̀ Wíwàpẹ́títí
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
Àwọn Míì
Ohun Tí Bíbélì Sọ
ijwbq àpilẹ̀kọ 184
Inú tọkọtaya kan ń dùn bí wọ́n ṣe ń jẹun àárọ̀.

Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Ìgbéyàwó?

Ohun tí Bíbélì sọ

Lẹ́yìn tí Ọlọ́run dá ọkùnrin àti obìnrin àkọ́kọ́, ó so wọ́n pọ̀, wọ́n sì di tọkọtaya. Ọlọ́run fi ìgbéyàwó lọ́lẹ̀ kó lè jẹ́ àjọṣe pàtàkì láàárín ọkùnrin àti obìnrin, kó sì di ìpìlẹ̀ tí ìdílé dúró lé lórí.​—Jẹ́nẹ́sísì 1:27, 28; 2:18.

Ọlọ́run fẹ́ kí tọkọtaya máa láyọ̀. (Òwe 5:18) Nínú Bíbélì, ó pèsè àwọn ìtọ́ni táá máa darí ìgbéyàwó àti àwọn ìlànà táá jẹ́ kó yọrí sí rere.

Nínú àpilẹ̀kọ yìí

  • Ìlànà wo ni Ọlọ́run fún àwọn tó ṣègbéyàwó?

  • Kí ni Bíbélì sọ nípa ìpínyà àti ìkọ̀sílẹ̀?

  • Ṣó yẹ kí tọkọtaya forúkọ ìgbéyàwó wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin kó tó ní ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run?

  • Kí ni Bíbélì sọ pé ó jẹ́ ojúṣe ọkọ àti aya nínú ìgbéyàwó?

  • Ṣé Ọlọ́run sọ pé káwọn tó ṣègbéyàwó lóde òní bímọ?

  • Báwo ni Bíbélì ṣe lè ran ìdílé mi lọ́wọ́?

  • Àwọn ẹsẹ Bíbélì tó sọ̀rọ̀ nípa ìgbéyàwó

Ìlànà wo ni Ọlọ́run fún àwọn tó ṣègbéyàwó?

Láti ìbẹ̀rẹ̀ ni Ọlọ́run ti mú kí ìgbéyàwó jẹ́ ọ̀nà tí ọkùnrin àti obìnrin á fi máa gbé pọ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 2:24) Ọlọ́run ò fọwọ́ sí kíkó obìnrin jọ, bíbá ẹ̀yà kan náà lò pọ̀, tàbí kí ọkùnrin àti obìnrin jọ máa gbé pọ̀ láìṣègbéyàwó. (1 Kọ́ríńtì 6:9; 1 Tẹsalóníkà 4:3) Jésù kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé ìlànà tí Ọlọ́run fi lélẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ ìgbéyàwó ni kí wọ́n máa tẹ̀ lé.​—Máàkù 10:6-8.

Lójú Ọlọ́run, ìgbéyàwó jẹ́ àjọṣe tó wà títí lọ. Nígbà tí ọkùnrin àti obìnrin bá ṣègbéyàwó, wọ́n á ṣèlérí pé àwọn máa jẹ́ olóòótọ́ síra wọn àti pé wọn ò ní ya ara wọn níwọ̀n ìgbà tí àwọn méjèèjì bá fi jọ wà láàyè. Ọlọ́run fẹ́ kí wọ́n pa àdéhùn yẹn mọ́.​—Máàkù 10:9.

Kí ni Bíbélì sọ nípa ìpínyà àti ìkọ̀sílẹ̀?

Àwọn ìgbà kan lè wà tí tọkọtaya lè má wà pa pọ̀, irú bí ìgbà tí ọ̀kan lára wọn bá rìnrìn àjò kó lè lọ bójú tó ohun àìròtẹ́lẹ̀ tó kan ìdílé wọn. Ṣùgbọ́n Bíbélì sọ pé kí wọ́n má ṣe pínyà torí ìṣòro ìgbéyàwó. Dípò tí wọ́n á fi pínyà, Bíbélì rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n yanjú ìṣòro náà.​—1 Kọ́ríńtì 7:10.

Àgbèrè nìkan ṣoṣo ni Bíbélì sọ pé ó lè fa ìkọ̀sílẹ̀. (Mátíù 19:9) Torí náà, bí tọkọtaya bá pinnu láti pínyà tàbí kọ ara wọn sílẹ̀ torí ìdí èyíkéyìí yàtọ̀ sí àgbèrè, kò sí èyíkéyìí nínú wọ́n tó lómìnira láti fẹ́ ẹlòmíì sọ́nà tàbí kó bá a ṣègbéyàwó.​—Mátíù 5:32; 1 Kọ́ríńtì 7:11.

Ṣó yẹ kí tọkọtaya forúkọ ìgbéyàwó wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin kó tó ní ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run?

Ọlọ́run fẹ́ kí àwọn Kristẹni pa òfin ìjọba nípa ìgbéyàwó mọ́. (Títù 3:1) Tó bá ṣeé ṣe fún tọkọtaya láti forúkọ ìgbéyàwó wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin, ìyẹn á fi hàn pé wọ́n bọ̀wọ̀ fún àwọn aláṣẹ àti ìlànà Ọlọ́run tó sọ pé kí ìgbéyàwó jẹ́ àdéhùn tó wà pẹ́ títí.a

Kí ni Bíbélì sọ pé ó jẹ́ ojúṣe ọkọ àti aya nínú ìgbéyàwó?

  • Ojúṣe tọkọtaya. Tọkọtaya gbọ́dọ̀ máa bọ̀wọ̀ fúnra wọn, kí wọ́n sì máa fi ìfẹ́ bára wọn lò. (Éfésù 5:33) Kí wọ́n má fi ìbálòpọ̀ du ara wọn, kí wọ́n sì máa ṣe é tìfẹ́tìfẹ́. Bákan náà, kí wọ́n yẹra fún ìwà àìṣòótọ́ èyíkéyìí. (1 Kọ́ríńtì 7:3; Hébérù 13:4) Tí wọ́n bá bímọ, kí wọ́n jọ fọwọ́sowọ́pọ̀ tọ́ wọn.​—Òwe 6:20.

    Ìyá kan ń ran ọmọbìnrin rẹ̀ kékeré lọ́wọ́ láti ṣe iṣẹ́ àṣetiléwá, bàbá ń ṣètò oúnjẹ nítòsí wọn.

    Bíbélì ò ṣe kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé nípa bí tọkọtaya á ṣe máa ṣe iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ àtàwọn iṣẹ́ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ míì nínú ilé. Wọ́n lè jọ pinnu ohun tí wọ́n bá mọ̀ pé ó máa rọrùn fún ìdílé wọn.

  • Ojúṣe ọkọ. Bíbélì sọ pé “ọkọ ni orí aya rẹ̀.” (Éfésù 5:23) Ọkọ jẹ́ orí ní ti pé òun ló gbọ́dọ̀ máa darí ìdílé rẹ̀ kó sì máa ṣe ìpinnu táá ṣe ìyàwó àtàwọn ọmọ rẹ̀ láǹfààní.

    Tọkọtaya kan ń ka Bíbélì nínú ilé lẹ́yìn tí wọ́n ti wá nǹkan díẹ̀ panu.

    Ó gbọ́dọ̀ rí i pé òun pèsè ohun tí á mú kí wọ́n ní ìlera tó dáa, kí wọ́n láyọ̀, kí wọ́n sì sún mọ́ Ọlọ́run. (1 Tímótì 5:8) Tóun àti ìyàwó rẹ̀ bá ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀, tó sì ń fara balẹ̀ gbé èrò rẹ̀ àtí bí nǹkan ṣe rí lára ìyàwó rẹ̀ yẹ̀ wò tó bá ń ṣe ìpinnu, á tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé òun mọyì àwọn ànímọ́ àti òye tí ìyàwó rẹ̀ ní. (Òwe 31:11, 28) Bíbélì sọ pé kí ọkọ máa fi ìfẹ́ ṣe ojúṣe rẹ̀ nínú ìdílé.​—Kólósè 3:19.

  • Ojúṣe aya. Bíbélì sọ pé “kí aya ni ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún ọkọ rẹ̀.” (Éfésù 5:33) Inú Ọlọ́run máa ń dùn tí aya bá fi ọ̀wọ̀ hàn fún ojúṣe ọkọ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olórí ìdílé.

    Tọkọtaya kan ń sọ̀rọ̀ lórí bí wọ́n ṣe máa náwó.

    Ojúṣe rẹ̀ ni pé kó máa ti ọkọ rẹ̀ lẹ́yìn, kó máa ràn án lọ́wọ́ kó lè máa ṣe ìpinnu tó dáa, kó sì máa kọ́wọ́ tì í bó ṣe ń bójú tó ipò orí rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 2:18) Bíbélì sọ̀rọ̀ tó dáa nípa aya tó bá ṣe ojúṣe pàtàkì tó jẹ́ tiẹ̀ nínú ìgbéyàwó.​—Òwe 31:10.

Ṣé Ọlọ́run sọ pé káwọn tó ṣègbéyàwó lóde òní bímọ?

Rárá o. Nígbà àtijọ́, Ọlọ́run pàṣẹ pé kí àwọn kan lára àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ bímọ. (Jẹ́nẹ́sísì 1:28; 9:1) Ṣùgbọ́n àṣẹ yẹn ò sí fáwọn Kristẹni. Jésù ò pàṣẹ pé kí àwọn ọmọlẹ́yìn òun bímọ. Kò sì sí èyíkéyìí lára àwọn tó kọ́kọ́ di ọmọ ẹ̀yìn tó sọ pé tọkọtaya gbọ́dọ̀ bímọ. Tọkọtaya lo máa pinnu bóyá àwọn máa bímọ tàbí àwọn ò ṣe bẹ́ẹ̀.

Báwo ni Bíbélì ṣe lè ran ìdílé mi lọ́wọ́?

Àwọn ìlànà inú Bíbélì lè ran tọkọtaya lọ́wọ́ kí ìgbéyàwó wọn lè ní ìbẹ̀rẹ̀ tó dáa. Ìlànà Bíbélì tún lè ran tọkọtaya lọ́wọ́ kí wọ́n má bàa ní ìṣòro tàbí kí wọ́n lè borí rẹ̀.

Ìlànà Bíbélì lè ran tọkọtaya lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa . . .

  • fi ìfẹ́ tòótọ́ hàn.​—1 Kọ́ríńtì 13:4-7; Kólósè 3:14.

  • yanjú èdèkòyédè.​—1 Kọ́ríńtì 10:24.

  • gbọ́ra wọn yé.​—Jémíìsì 1:19.

  • bọ̀wọ̀ fúnra wọn.​—Róòmù 12:10.

  • dárí ji ara wọn.​—1 Pétérù 4:8.

  • fòótọ́ bára wọn lò.​—Máàkù 10:9.

  • ní sùúrù.​—Éfésù 4:2, 3.

  • fọwọ́ sowọ́ pọ̀.​—Oníwàásù 4:9.

  • mú kí ìfẹ́ wọn jinlẹ̀ sí i.​—Orin Sólómọ́nì 8:7.

a Tó o bá fẹ́ mọ ojú tí Bíbélì fi wo ìgbéyàwó ti ìbílẹ̀, wo Ilé Ìṣọ́ October 15, 2006, ojú ìwé 21, ìpínrọ̀ 12.

Àwọn ẹsẹ Bíbélì tó sọ̀rọ̀ nípa ìgbéyàwó

Òwe 18:22: “Ẹni tó bá rí aya rere fẹ́ ti rí ohun rere.”

Ìtumọ̀: Bíbélì sọ ohun tó dáa nípa ìgbéyàwó.

Málákì 2:15: “Ẹ má sì hùwà àìṣòótọ́ sí aya ìgbà èwe yín.”

Ìtumọ̀: Kódà lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún tí tọkọtaya ti ṣègbéyàwó, Ọlọ́run ò fẹ́ kí wọ́n dalẹ̀ ara wọn, ó sì fẹ́ kí wọ́n máa bọ̀wọ̀ fúnra wọn.

Máàkù 10:9: “Ohun tí Ọlọ́run ti so pọ̀, kí èèyàn kankan má ṣe yà á.”

Ìtumọ̀: Ọlọrun fẹ́ kí ìgbéyàwó jẹ́ àjọṣe tó máa wà pẹ́ títí.

Hébérù 13:4: “Kí ìgbéyàwó ní ọlá láàárín gbogbo èèyàn.”

Ìtumọ̀: Kí tọkọtaya fi ọwọ́ pàtàkì mú ìgbéyàwó wọn kí wọ́n sì ṣiṣẹ́ kára láti dáàbò bò ó.

1 Kọ́ríńtì 7:28: “Àwọn tó [ṣègbéyàwó] máa ní ìpọ́njú nínú ara wọn.”

Ìtumọ̀: Kò sí ìgbéyàwó tí kò ní ìṣòro; ṣe ló yẹ kí tọkọtaya jọ máa yanjú ìṣòro tó bá yọjú.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́