ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w07 5/1 ojú ìwé 19-23
  • Má Ṣe Ya Ohun Tí Ọlọ́run Ti So Pọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Má Ṣe Ya Ohun Tí Ọlọ́run Ti So Pọ̀
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Báwọn Tọkọtaya Ṣe Lè Borí Àwọn Ìṣòro
  • “Ẹ Máa Bá A Lọ Ní Nínífẹ̀ẹ́ Àwọn Aya Yín”
  • Báwo Ló Ṣe Yẹ Kó O Máa Tọ́jú Aya Rẹ?
  • Kí Ló Túmọ̀ Sí Pé Kó O Máa Ṣìkẹ́ Aya Rẹ?
  • Àwọn Aya Tó Ń Fi Àwọn Ìlànà Bíbélì Ṣèwà Hù
  • Àdéhùn Ìgbéyàwó Ṣe Pàtàkì Gan-An
  • Ìmọ̀ràn Ọlọgbọ́n Fún Àwọn Tọkọtaya
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Kọ́kọ́rọ́ Méjì sí Ìgbéyàwó Wíwà Pẹ́ Títí
    Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé
  • Mú Kí Ìgbéyàwó Rẹ Jẹ́ Ìsopọ̀ Wíwàpẹ́títí
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Báwo Ni Ìdílé Rẹ Ṣe Lè Jẹ́ Aláyọ̀?—Apá Kìíní
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
w07 5/1 ojú ìwé 19-23

Má Ṣe Ya Ohun Tí Ọlọ́run Ti So Pọ̀

“Wọn kì í ṣe méjì mọ́, bí kò ṣe ara kan. Nítorí náà, ohun tí Ọlọ́run ti so pọ̀, kí ènìyàn kankan má ṣe yà á sọ́tọ̀.”—MÁTÍÙ 19:6.

1, 2. Kí nìdí tó fi bá Ìwé Mímọ́ mu tí kò sì burú láti retí pé tọkọtaya á máa níṣòro lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan?

KÁ SỌ pé o fẹ́ bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò ọ̀nà jíjìn kan, ọkọ̀ ìrìnnà lo sì fẹ́ lò. Ǹjẹ́ o rò pé wàá bá ìṣòro pàdé bó o ti ń rìnrìn àjò náà? Kò ní bọ́gbọ́n mu rárá kó o rò pé o ò ní bá ìṣòro kankan pàdé lọ́nà! Bí àpẹẹrẹ, òjò lè máa rọ̀ gan-an, á sì di dandan kó o dín eré ọkọ̀ rẹ kù kó o sì rọra máa lọ. O lè débì kan kí ọkọ̀ rẹ bà jẹ́, tó ò sì ní lè yanjú ìṣòro náà, tá á sì gba pé kó o fi ọkọ̀ náà sílẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà kó o sì lọ wá ẹni tó máa bá ọ tún un ṣe. Ṣé ó wá yẹ káwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí mú kó o ronú pé àṣìṣe ló jẹ́ pé o bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò náà, pé ńṣe ló yẹ kó o pa ọkọ̀ náà tì? Rárá o. Tó o bá ń rìnrìn àjò ọ̀nà jíjìn, ó yẹ kó o mọ̀ pé ìṣòro lè ṣẹlẹ̀ kó o sì wá bí wàá ṣe yanjú wọn.

2 Bí ọ̀rọ̀ ìgbéyàwó ṣe rí náà nìyẹn. Kò sọ́gbọ́n tí kò fi ní sí ìṣòro, kò sì ní bọ́gbọ́n mu kí ọkùnrin àtobìnrin tó ń ronú láti ṣègbéyàwó retí pé gbogbo nǹkan á máa dùn yùngbà ni. Nínú 1 Kọ́ríńtì 7:28, Bíbélì sọ ojú abẹ níkòó, ó sọ pé àwọn ọkọ àtàwọn aya yóò ní “ìpọ́njú nínú ẹran ara wọn.” Kí nìdí tí èyí fi rí bẹ́ẹ̀? Ní ṣókí, nítorí pé àwọn ọkọ àtàwọn aya jẹ́ aláìpé ni àti pé “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò” la wà. (2 Tímótì 3:1; Róòmù 3:23) Nípa báyìí, àwọn tọkọtaya tó tiẹ̀ mọwọ́ ara wọn pàápàá tí wọ́n sì bẹ̀rù Ọlọ́run yóò máa níṣòro lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan.

3. (a) Ojú wo lọ̀pọ̀ èèyàn nínú ayé fi ń wo ìgbéyàwó? (b) Kí nìdí táwọn Kristẹni fi máa ń sapá láti yanjú àwọn ìṣòro tó ń yọjú nínú ìgbéyàwó wọn?

3 Láyé òde òní, táwọn tọkọtaya kan bá ko ìṣòro, ohun tó kọ́kọ́ máa ń wá sí wọn lọ́kàn ni pé káwọn túká. Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, ńṣe ni ìkọ̀sílẹ̀ ń pọ̀ sí i. Àmọ́ o, ńṣe làwọn Kristẹni tòótọ́ máa ń yanjú ìṣòro wọn dípò kí wọ́n kọra wọn sílẹ̀. Kí nìdí? Ìdí ni pé wọ́n gbà pé ìgbéyàwó jẹ́ ẹ̀bùn mímọ́ látọ̀dọ̀ Jèhófà. Jésù sọ nípa àwọn tọkọtaya pé: “Ohun tí Ọlọ́run ti so pọ̀, kí ènìyàn kankan má ṣe yà á sọ́tọ̀.” (Mátíù 19:6) Lóòótọ́, kì í ṣe gbogbo ìgbà ló máa ń rọrùn láti tẹ̀ lé ìlànà yìí. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ẹbí àtàwọn mìíràn tí wọn ò ka ìlànà Bíbélì sí, títí kan àwọn kan lára àwọn tó máa ń gbani nímọ̀ràn lórí ọ̀rọ̀ ìgbéyàwó, sábà máa ń rọ àwọn tọkọtaya láti pínyà tàbí kí wọ́n kọ ara wọn sílẹ̀ nítorí àwọn ìdí tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu.a Àmọ́ àwọn Kristẹni mọ̀ pé ohun tó dáa jù lọ ni pé káwọn wá ojútùú sáwọn ìṣòro ìgbéyàwó kí wọ́n sì tètè máa yanjú wọn bí wọ́n bá ti ń yọjú dípò kí wọ́n yára tú ká. Àní sẹ́, ó ṣe pàtàkì pé ká pinnu ní gbàrà tá a bá ti ṣègbéyàwó pé a óò máa ṣe ohun gbogbo lọ́nà tí Jèhófà fọwọ́ sí, pé a ò ní máa ṣe nǹkan níbàámu pẹ̀lú ìmọ̀ràn ti àwọn èèyàn.—Òwe 14:12.

Báwọn Tọkọtaya Ṣe Lè Borí Àwọn Ìṣòro

4, 5. (a) Àwọn ìṣòro wo ni kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀ nínú ìgbéyàwó? (b) Kí nìdí táwọn ìlànà inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi máa ń ṣiṣẹ́ gan-an kódà bí ìṣòro bá tiẹ̀ yọjú nínú ìgbéyàwó?

4 Ohun kan tó jẹ́ òótọ́ ni pé, gbogbo ìgbéyàwó ló gba kéèyàn máa wá bóun ṣe máa yanjú ìṣòro èyíkéyìí tó bá yọjú. Lọ́pọ̀ ìgbà, ohun tí èyí túmọ̀ sí ni pé kí tọkọtaya máa yanjú àwọn èdèkòyédè kéékèèké. Àmọ́ àwọn ìgbéyàwó kan lè ní àwọn ìṣòro tó le gan-an tó lè fẹ́ da ìgbéyàwó náà rú. Láwọn ìgbà míì, ó lè di dandan kẹ́ ẹ pé alàgbà kan tó níyàwó tó sì lóye gan-an láti ràn yín lọ́wọ́. Àmọ́ ṣá o, àwọn nǹkan wọ̀nyí kò túmọ̀ sí pé ìgbéyàwó rẹ ti forí ṣánpọ́n nìyẹn. Ńṣe ni wọ́n kàn ń jẹ́ kó o rí i pé ó ṣe pàtàkì gan-an kó o máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì láti yanjú àwọn ìṣòro náà.

5 Nítorí pé Jèhófà ni Ẹlẹ́dàá àwa èèyàn, òun sì tún lẹni tó dá ìgbéyàwó sílẹ̀, ó mọ ohun tá a nílò ju ẹnikẹ́ni lọ kí ìgbéyàwó wa lè láyọ̀. Àmọ́ ìbéèrè tó wà níbẹ̀ ni pé, Ǹjẹ́ a óò tẹ́tí sí ìmọ̀ràn tó wà nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ṣé a óò sì fi sílò? Ó dájú pé tá a bá mú ìmọ̀ràn náà lò, á ṣe wá láǹfààní. Jèhófà sọ fáwọn èèyàn rẹ̀ ayé ọjọ́un pé: “Ì bá ṣe pé ìwọ yóò fetí sí àwọn àṣẹ mi ní tòótọ́! Nígbà náà, àlàáfíà rẹ ì bá dà bí odò, òdodo rẹ ì bá sì dà bí ìgbì òkun.” (Aísáyà 48:18) Títẹ̀lé àwọn ìtọ́sọ́nà inú Bíbélì lè mú kí ìgbéyàwó láyọ̀. Ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ gbé ìmọ̀ràn tí Bíbélì fún àwọn ọkọ yẹ̀ wò.

“Ẹ Máa Bá A Lọ Ní Nínífẹ̀ẹ́ Àwọn Aya Yín”

6. Ìmọ̀ràn wo ló wà nínú Ìwé Mímọ́ fún àwọn ọkọ?

6 Nínú lẹ́tà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn ará Éfésù, àwọn ìlànà tó ṣe kedere wà níbẹ̀ fún àwọn ọkọ. Pọ́ọ̀lù sọ níbẹ̀ pé: “Ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa bá a lọ ní nínífẹ̀ẹ́ àwọn aya yín, gan-an gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹ̀lú ti nífẹ̀ẹ́ ìjọ, tí ó sì jọ̀wọ́ ara rẹ̀ lọ́wọ́ fún un. Lọ́nà yìí, ó yẹ kí àwọn ọkọ máa nífẹ̀ẹ́ àwọn aya wọn gẹ́gẹ́ bí ara àwọn fúnra wọn. Ẹni tí ó bá nífẹ̀ẹ́ aya rẹ̀ nífẹ̀ẹ́ ara rẹ̀, nítorí pé kò sí ènìyàn kankan tí ó jẹ́ kórìíra ara òun fúnra rẹ̀; ṣùgbọ́n a máa bọ́ ọ, a sì máa ṣìkẹ́ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹ̀lú ti ń ṣe sí ìjọ. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, pẹ̀lúpẹ̀lù, kí olúkúlùkù yín lẹ́nì kọ̀ọ̀kan máa nífẹ̀ẹ́ aya rẹ̀ bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ṣe nífẹ̀ẹ́ ara rẹ̀.”—Éfésù 5:25, 28, 29, 33.

7. (a) Kí lohun pàtàkì tó yẹ kó jẹ́ ara ìpìlẹ̀ ìgbéyàwó àwọn Kristẹni? (b) Báwo làwọn ọkọ ṣe lè máa nífẹ̀ẹ́ àwọn aya wọn nìṣó?

7 Pọ́ọ̀lù ò jíròrò gbogbo ìṣòro tó ṣeé ṣe kó yọjú láàárín tọkọtaya. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó jẹ́ ojútùú gan-an sí ìṣòro ìgbéyàwó ló sọ, ìyẹn ohun tó ṣe pàtàkì tó yẹ kó jẹ́ ara ìpìlẹ̀ gbogbo ìgbéyàwó àwọn Kristẹni, ìyẹn ni ìfẹ́. Kódà, ìgbà mẹ́fà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni ọ̀rọ̀ náà, ìfẹ́, fara hàn nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí. Tún kíyè sí i pé, Pọ́ọ̀lù sọ fáwọn ọkọ pé: “Ẹ máa bá a lọ ní nínífẹ̀ẹ́ àwọn aya yín.” Láìsí àní-àní Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé, ó lè rọrùn láti nífẹ̀ẹ́ ẹnì kan níbẹ̀rẹ̀ ju kéèyàn máa nífẹ̀ẹ́ ẹni náà nìṣó. “Àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” yìí, tí ọ̀pọ̀ èèyàn jẹ́ “olùfẹ́ ara wọn” àti “aláìṣeé bá ṣe àdéhùn kankan” lèyí tiẹ̀ túbọ̀ wá ń ṣẹlẹ̀ jù. (2 Tímótì 3:1-3) Àwọn ìwà burúkú yìí ń ṣàkóbá fún ọ̀pọ̀ ìgbéyàwó lónìí, àmọ́ ọkọ tó nífẹ̀ẹ́ kò ní jẹ́ kí ìwà ìmọtara ẹni nìkan táráyé ń hù nípa lórí ìrònú àti ìwà òun.—Róòmù 12:2.

Báwo Ló Ṣe Yẹ Kó O Máa Tọ́jú Aya Rẹ?

8, 9. Àwọn ọ̀nà wo ni ọkọ kan tó jẹ́ Kristẹni gbà ń tọ́jú aya rẹ̀?

8 Bó o bá jẹ́ ọkọ tó o sì jẹ́ Kristẹni, báwo lo ṣe lè yàgò fún ìwà ìmọtara ẹni nìkan kó o sì máa fi ìfẹ́ gidi hàn sí ìyàwó rẹ? Nínú ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn ará Éfésù tá a fà yọ níṣàájú, ó sọ àwọn ohun méjì tó yẹ kó o máa ṣe, ìyẹn ni pé kó o máa pèsè ohun tí aya rẹ nílò fún un, kó o sì tún máa ṣìkẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bó o ṣe ń ṣe fún ara rẹ gan-an. Ọ̀nà wo lo lè gbà máa pèsè ohun tí aya rẹ nílò fún un? Ọ̀nà kan jẹ́ nípa tara, ìyẹn ni pé kó o máa pèsè aṣọ, oúnjẹ àti ibùgbé fún un. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí Tímótì pé: “Dájúdájú, bí ẹnì kan kò bá pèsè fún àwọn tí í ṣe tirẹ̀, àti ní pàtàkì fún àwọn tí í ṣe mẹ́ńbà agbo ilé rẹ̀, ó ti sẹ́ ìgbàgbọ́, ó sì burú ju ẹni tí kò ní ìgbàgbọ́.”—1 Tímótì 5:8.

9 Àmọ́ o, kò mọ sórí kó o máa pèsè oúnjẹ, aṣọ, àti ibùgbé fún aya rẹ o. Kí nìdí? Nítorí pé ọkọ kan lè máa pèsè àwọn nǹkan tí aya rẹ̀ nílò nípa tara dáadáa, síbẹ̀ kó má bìkítà nípa ẹ̀dùn ọkàn ìyàwó rẹ̀, kí òun àti aya rẹ̀ má sì jọ máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ṣíṣe àwọn ohun tá a mẹ́nu kàn gbẹ̀yìn yìí ṣe pàtàkì gan-an. Òótọ́ ni pé ọ̀pọ̀ àwọn ọkùnrin tó jẹ́ Kristẹni lọwọ́ wọn máa ń dí gan-an lẹ́nu iṣẹ́ bíbójútó àwọn nǹkan tó jẹ́ mọ́ ti ìjọ. Àmọ́, pé ọkọ kan ní iṣẹ́ tó pọ̀ tó ń bójú tó nínú ìjọ kò túmọ̀ sí pé kó pa iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé e lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí olórí ìdílé tì. (1 Tímótì 3:5, 12) Nígbà tí ìwé ìròyìn yìí ń sọ̀rọ̀ lórí kókó yìí lọ́dún díẹ̀ sẹ́yìn, ó sọ pé: “Ní ìbáramuṣọ̀kan pẹlu awọn ohun-àbéèrè-fún ti Bibeli, a lè sọ pe ‘ṣíṣe olùṣọ́-àgùtàn ńbẹ̀rẹ̀ lati inú ilé.’ Bí alàgbà kan bá ṣàìfiyèsí ìdílé rẹ̀, oun lè fi ìyànsípò rẹ̀ sábẹ́ ewu.”b Èyí fi hàn kedere pé ó ṣe pàtàkì kó o máa bójú tó aya rẹ nípa tara, kó o máa tẹ́tí sílẹ̀ nígbà tó bá fẹ́ sọ ohun tó ń dùn ún lọ́kàn fún ọ, àti èyí tó ṣe pàtàkì jù lọ ni pé, kẹ́ ẹ jọ máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

Kí Ló Túmọ̀ Sí Pé Kó O Máa Ṣìkẹ́ Aya Rẹ?

10. Báwo ni ọkọ ṣe lè tọ́jú aya rẹ̀?

10 Bó o bá mọyì aya rẹ, wàá máa tọ́jú rẹ̀ dáadáa torí pé o nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Ọ̀pọ̀ ọ̀nà lo lè gbà ṣe èyí. Lákọ̀ọ́kọ́, máa lo àkókò pẹ̀lú aya rẹ. Bó o bá kọ̀ láti ṣe èyí, ìfẹ́ tí aya rẹ ní sí ẹ lè bẹ̀rẹ̀ sí í dín kù. Tún kíyè sí i pé, ìwọ̀n àkókò àti àbójútó tí ìwọ́ rò pé ó tó fún aya rẹ lè má tó lójú rẹ̀. Kì í ṣe kó o kàn máa sọ ọ́ lẹ́nu pé ò ń tọ́jú aya rẹ. Aya rẹ gbọ́dọ̀ mọ̀ pé ò ń tọ́jú òun. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Kí olúkúlùkù má ṣe máa wá àǹfààní ti ara rẹ̀, bí kò ṣe ti ẹnì kejì.” (1 Kọ́ríńtì 10:24) Gẹ́gẹ́ bí ọkọ tó nífẹ̀ẹ́, rí i dájú pé o mọ ohun tí aya rẹ nílò.—Fílípì 2:4.

11. Báwo ni ọ̀nà tí ọkọ kan ń gbà hùwà sí aya rẹ̀ ṣe kan àjọṣe àárín òun pẹ̀lú Ọlọ́run àti ìjọ?

11 Ọ̀nà mìíràn tó o tún lè gbà fi hàn pé ò ń ṣìkẹ́ aya rẹ̀ ni pé kó o máa hùwà sí i pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́, nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe rẹ. (Òwe 12:18) Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sáwọn ará Kólósè pé: “Ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa bá a nìṣó ní nínífẹ̀ẹ́ àwọn aya yín, ẹ má sì bínú sí wọn lọ́nà kíkorò.” (Kólósè 3:19) Gẹ́gẹ́ bí ìwé kan tá a ṣèwádìí nínú rẹ̀ ti sọ, ọ̀nà mìíràn tá a tún lè gbà sọ apá tó kẹ́yìn nínú ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù yẹn ni pé, “má ṣe máa ṣe é bí ọmọ ọ̀dọ̀” tàbí “má ṣe ṣe é bí ẹrú.” Ó dájú pé ọkọ kan tó jẹ́ òǹrorò, yálà ní gbangba tàbí ní kọ̀rọ̀ yàrá, kò fi hàn rárá pé òun mọyì ìyàwó òun. Bó bá ń hùwà sí ìyàwó rẹ̀ lọ́nà tí kò dáa, ó lè ba àjọṣe àárín òun àti Ọlọ́run jẹ́. Àpọ́sítélì Pétérù kọ̀wé sáwọn ọkọ pé: “Ẹ máa bá a lọ ní bíbá wọn gbé lọ́nà kan náà ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀, kí ẹ máa fi ọlá fún wọn gẹ́gẹ́ bí fún ohun èlò tí ó túbọ̀ jẹ́ aláìlera, ọ̀kan tí ó jẹ́ abo, níwọ̀n bí ẹ tún ti jẹ́ ajogún ojú rere ìyè tí a kò lẹ́tọ̀ọ́ sí pẹ̀lú wọn, kí àdúrà yín má bàa ní ìdènà.”c—1 Pétérù 3:7.

12. Kí làwọn ọkọ lè kọ́ látinú ọ̀nà tí Jésù gbà hùwà sí ìjọ Kristẹni?

12 Má ṣe rò pé aya rẹ á ṣàdédé máa nífẹ̀ẹ́ rẹ. Máa mú un dá a lójú pé ìfẹ́ tó o ní fún un kò já létí. Jésù fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fáwọn ọkọ tó jẹ́ Kristẹni nínú bó ṣe hùwà sí ìjọ Kristẹni. Ó ní sùúrù, ó ń ṣe dáadáa sí wọn, ó sì ń darí jì wọ́n, kódà nígbà táwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tiẹ̀ ń ṣe ohun tí kò bára dé léraléra. Èyí ló jẹ́ kí Jésù lè sọ fáwọn mìíràn pé: “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi, . . . nítorí onínú tútù àti ẹni rírẹlẹ̀ ní ọkàn-àyà ni èmi, ẹ ó sì rí ìtura fún ọkàn yín.” (Mátíù 11:28, 29) Ọ̀nà tí Jésù gbà hùwà sí ìjọ gẹ́lẹ́ ni ọkọ tó bá ń fara wé Kristi yóò gbà máa hùwà sí aya rẹ̀. Ọkùnrin tó mọyì aya rẹ̀ lóòótọ́, tó ń fi hàn nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe rẹ̀, yóò jẹ́ kí ọkàn ìyàwó rẹ̀ balẹ̀ gan-an.

Àwọn Aya Tó Ń Fi Àwọn Ìlànà Bíbélì Ṣèwà Hù

13. Àwọn ìlànà wo ló wà nínú Bíbélì tó lè ran àwọn aya lọ́wọ́?

13 Bíbélì tún ní àwọn ìlànà tó lè ran àwọn aya lọ́wọ́. Éfésù 5:22-24, 33 sọ pé: “Kí àwọn aya wà ní ìtẹríba fún àwọn ọkọ wọn gẹ́gẹ́ bí fún Olúwa, nítorí pé ọkọ ni orí aya rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹ̀lú ti jẹ́ orí ìjọ, bí òun ti jẹ́ olùgbàlà ara yìí. Ní ti tòótọ́, gẹ́gẹ́ bí ìjọ ti wà ní ìtẹríba fún Kristi, bẹ́ẹ̀ ni kí àwọn aya pẹ̀lú wà fún àwọn ọkọ wọn nínú ohun gbogbo. . . . Kí aya ní ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún ọkọ rẹ̀.”

14. Kí nìdí tí ìlànà nípa ìtẹríba tá a rí nínú Ìwé Mímọ́ kò fi bu àwọn obìnrin kù?

14 Kíyè sí i pé Pọ́ọ̀lù tẹnu mọ́ ìtẹríba àti ọ̀wọ̀. Ó rán àwọn aya létí láti máa tẹrí ba fáwọn ọkọ wọn. Èyí bá ètò tí Ọlọ́run ṣe mu. Gbogbo nǹkan ẹlẹ́mìí pátá láyé àti lọ́run ló wà lábẹ́ ẹnì kan. Kódà Jésù pàápàá wà lábẹ́ Jèhófà Ọlọ́run. (1 Kọ́ríńtì 11:3) Ó dájú pé ọkọ tó bá ń ṣe ohun tó fi hàn pé òun ń lo ipò orí òun dáadáa yóò mú kó rọrùn fún aya rẹ̀ láti máa tẹrí bá fún un.

15. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ìmọ̀ràn tó wà fáwọn aya nínú Bíbélì?

15 Pọ́ọ̀lù tún sọ pé kí aya “ní ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún ọkọ rẹ̀.” Aya tó jẹ́ Kristẹni gbọ́dọ̀ ní “ẹ̀mí ìṣejẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ àti ti ìwà tútù,” kì í ṣe kó máa gbó ọkọ rẹ̀ lẹ́nu tàbí kó máa ṣe ohunkóhun tó bá ṣáà ti wù ú. (1 Pétérù 3:4) Aya tó bẹ̀rù Ọlọ́run máa ń ṣiṣẹ́ kára kí nǹkan lè máa lọ déédéé nínú ìdílé rẹ̀, ó sì máa ń buyì fún orí rẹ̀. (Títù 2:4, 5) Yóò máa sọ̀rọ̀ ọkọ rẹ̀ dáadáa, nípa báyìí, kò ní ṣe ohunkóhun tó máa mú káwọn mìíràn rí ọkọ rẹ̀ fín. Á tún máa sapá gan-an láti mú káwọn ìpinnu tí ọkọ rẹ̀ ń ṣe yọrí sí rere.—Òwe 14:1.

16. Kí làwọn aya lè kọ́ látinú àpẹẹrẹ Sárà àti ti Rèbékà?

16 Pé obìnrin kan tó jẹ́ Kristẹni ní ẹ̀mí ìṣejẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ àti ti ìwà tútù kò túmọ̀ sí pé kò lè sọ èrò ọkàn rẹ̀ jáde tàbí pé èrò rẹ̀ kò ṣe pàtàkì. Àwọn obìnrin tí wọ́n bẹ̀rù Ọlọ́run láyé ọjọ́un, irú bíi Sárà àti Rèbékà, sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn jáde lórí àwọn ọ̀ràn kan, àkọsílẹ̀ inú Bíbélì sì fi hàn pé Jèhófà fọwọ́ sí ohun tí wọ́n ṣe. (Jẹ́nẹ́sísì 21:8-12; 27:46–28:4) Àwọn aya tó jẹ́ Kristẹni náà lè sọ èrò ọkàn wọn jáde. Àmọ́ wọ́n ní láti ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́nà tó fi hàn pé wọ́n gba ti ọkọ wọn rò, kì í ṣe lọ́nà tó máa tàbùkù ọkọ wọn. Ó ṣeé ṣe kí wọ́n tipa bẹ́ẹ̀ rí i pé ọ̀rọ̀ táwọn àtọkọ wọn jọ ń sọ túbọ̀ lárinrin, àwọn ọkọ wọn á sì túbọ̀ máa gba èrò wọn.

Àdéhùn Ìgbéyàwó Ṣe Pàtàkì Gan-An

17, 18. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ọ̀nà tí tọkọtaya lè gbà dènà ipa tí Sátánì ń sà láti da ìgbéyàwó wọn rú?

17 Àdéhùn láti jọ wà títí ayé ni ìgbéyàwó jẹ́. Nípa bẹ́ẹ̀, ó gbọ́dọ̀ wu ọkọ àti aya gan-an láti rí i pé ayọ̀ wà nínú ìgbéyàwó wọn. Tí tọkọtaya kò bá jọ ń sọ̀rọ̀ ní gbogbo ìgbà, èyí lè sọ àwọn ìṣòro wọn di ńlá, tí apá ò ní fẹ́ ká mọ́. Ohun tó sábà máa ń ṣẹlẹ̀ ni pé, tíṣòro bá ti ṣẹlẹ̀, àwọn tọkọtaya kì í bára wọn sọ̀rọ̀ mọ́, èyí sì máa ń mú kí wọ́n di ara wọn sínú. Àwọn kan tiẹ̀ máa ń wá ọ̀nà tí ìgbéyàwó wọn á fi túká, bóyá kí wọ́n máa lójú síta. Jésù kìlọ̀ pé: “Olúkúlùkù ẹni tí ń bá a nìṣó ní wíwo obìnrin kan láti ní ìfẹ́ onígbòónára sí i, ti ṣe panṣágà pẹ̀lú rẹ̀ ná nínú ọkàn-àyà rẹ̀.”—Mátíù 5:28.

18 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba gbogbo Kristẹni nímọ̀ràn, títí kan àwọn tó ní ọkọ tàbí aya, pé: “Ẹ fi ìrunú hàn, síbẹ̀ kí ẹ má ṣẹ̀; ẹ má ṣe jẹ́ kí oòrùn wọ̀ bá yín nínú ipò ìbínú, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má ṣe fi àyè sílẹ̀ fún Èṣù.” (Éfésù 4:26, 27) Ọ̀tá wa tó ga jù lọ, ìyẹn Sátánì, ń gbìyànjú láti lo àwọn aáwọ̀ tó ṣeé ṣe kó wáyé láàárín àwa Kristẹni. Má ṣe jẹ́ kó rí ọ mú! Tíṣòro bá ṣẹlẹ̀, wá ohun tó jẹ́ èrò Jèhófà lórí ọ̀ràn náà nínú Bíbélì, kó o lo àwọn ìwé tó ń ṣàlàyé Bíbélì láti fi ṣèwádìí. Máa fi sùúrù ṣàlàyé ohun tó ń bí ẹ nínú láìfi ohunkóhun pamọ́. Rí i pé àwọn ohun tó o mọ̀ nípa àwọn ìlànà Jèhófà lo fi ń ṣèwàhù. (Jákọ́bù 1:22-25) Ní ti ọ̀rọ̀ ìgbéyàwó rẹ, pinnu pé ìwọ àtẹnì kejì rẹ ni yóò jọ máa bá Ọlọ́run rìn nìṣó, má sì ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tàbí ohunkóhun ya ohun tí Ọlọ́run ti so pọ̀!—Míkà 6:8.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo àpótí tí àkòrí rẹ̀ sọ pé “Pípínyà àti Ìkọ̀sílẹ̀” nínú Jí! February 8, 2002, ojú ìwé 10. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

b Wo Ilé Ìṣọ́ May 15, 1989, ojú ìwé 12.

c Kí ọkùnrin kan tó lè yẹ fún àǹfààní iṣẹ́ ìsìn nínú ìjọ Kristẹni, kò gbọ́dọ̀ jẹ́ “aluni,” ìyẹn ni ẹni tó ń lu àwọn mìíràn tàbí tó ń nà wọ́n ní pàṣán ọ̀rọ̀. Ìdí nìyí tí Ilé Ìṣọ́ ti September 1, 1990 fi sọ lójú ìwé 25 pé: “Ọkunrin kan kò tóótun bí oun bá ńhúwà ní ọ̀nà oníwà-bí-Ọlọ́run nibomiran ṣugbọn tí ó jẹ́ òṣìkà agbonimọ́lẹ̀ ní ilé.”—1 Tímótì 3:2-5, 12.

Ǹjẹ́ O Rántí?

• Kí nìdí tí ìṣòro fi lè wà nínú ìgbéyàwó àwọn tó tiẹ̀ jẹ́ Kristẹni pàápàá?

• Ọ̀nà wo ni ọkọ kan lè gbà máa pèsè ohun tí aya rẹ̀ nílò fún un kó sì máa fi hàn pé òun ń ṣìkẹ́ rẹ̀?

• Kí ni aya lè ṣe láti fi hàn pé òun ń bọ̀wọ̀ fún ọkọ òun dáadáa?

• Báwo ni ọkọ àti aya ṣe lè mú kí ìpinnu tí wọ́n ṣe pé àwọn ò ní fi ara wọn sílẹ̀ túbọ̀ lágbára sí i?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]

Ọkọ gbọ́dọ̀ máa tọ́jú aya rẹ̀, kì í ṣe nípa pípèsè nǹkan tara nìkan, àmọ́ kí wọ́n tún jọ máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọrọ̀ Ọlọ́run

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

Ọkùnrin tó ń ṣìkẹ́ aya rẹ̀ yóò jẹ́ kí ọkàn aya rẹ̀ balẹ̀ gan-an

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ làwọn aya tó jẹ́ Kristẹni máa ń sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́