Ẹ Ní Ẹ̀mí Aṣáájú Ọ̀nà
1. Báwo lo ṣe lè ṣàlàyé ohun tó ń jẹ́ ẹ̀mí aṣáájú ọ̀nà?
1 Yálà àwọn akéde Ìjọba Ọlọ́run lè ṣe aṣáájú ọ̀nà nísinsìnyí tàbí wọn kò lè ṣe é, gbogbo wọn ló lè ní ẹ̀mí aṣáájú ọ̀nà. Tọkàntọkàn ni wọ́n fi fẹ́ pa àṣẹ Jésù mọ́, ìyẹn pé kí wọ́n máa wàásù kí wọ́n sì máa sọni di ọmọ ẹ̀yìn. (Mát. 28:19, 20; Ìṣe 18:5) Ọ̀ràn àwọn èèyàn jẹ wọ́n lọ́kàn, wọ́n sì máa ń fi ọ̀pọ̀ nǹkan du ara wọn kí wọ́n bàa lè ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn. (Mát. 9:36; Ìṣe 20:24) Àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ti múra tán láti ṣe ohunkóhun tó bá yẹ ní ṣíṣe kí wọ́n lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. (1 Kọ́r. 9:19-23) Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ ẹnì kan tó ní ẹ̀mí aṣáájú ọ̀nà, ìyẹn Fílípì ajíhìnrere.
2. Báwo làwọn alàgbà àtàwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ṣe lè jẹ́ onítara nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ bíi ti Fílípì?
2 Wíwàásù àti Kíkọ́ni: Ọ̀pọ̀ ẹrù iṣẹ́ pàtàkì ni Fílípì ń bójú tó nínú ìjọ Kristẹni ọ̀rúndún kìíní. (Ìṣe 6:1-6) Síbẹ̀, fífi ìtara wàásù ìhìn rere ló fọwọ́ pàtàkì mú jù lọ. (Ìṣe 8:40) Bákan náà lóde òní, bí àwọn alàgbà àtàwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ṣe ń bójú tó àwọn ẹrù iṣẹ́ wọn, wọ́n lè jẹ́ ẹni tó ní ẹ̀mí aṣáájú ọ̀nà bí wọ́n bá ń fi ìtara múpò iwájú nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. Èyí á mà fún àwọn ará níṣìírí láti ṣe púpọ̀ sí i o!—Róòmù 12:11.
3. Báwo la ṣe lè jẹ́ ẹni tó ní ẹ̀mí aṣáájú ọ̀nà tá a bá wà nínú ìṣòro?
3 Lẹ́yìn ikú Sítéfánù, inúnibíni àwọn alátakò kó ìnira bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn gan-an. Síbẹ̀, Fílípì ò dẹwọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù, ó sì kópa tí kì í ṣe kékeré nínú mímú ìhìn rere lọ sọ́dọ̀ àwọn ará Samáríà. (Ìṣe 8:1, 4-6, 12, 14-17) A lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀ nípa ṣíṣàì dẹwọ́ nínú wíwàásù ìhìn rere nígbà tá a bá wà nínú ìṣòro àti nípa wíwàásù fún gbogbo ẹni tá a bá rí láìṣe ojúsàájú.—Jòh. 4:9.
4. Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ lára Fílípì tá a bá fẹ́ jẹ́ ọ̀jáfáfá olùkọ́?
4 A óò rí i pé Fílípì jẹ́ ọ̀jáfáfá olùkọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run bá a bá ṣàyẹ̀wò àkọsílẹ̀ bí a ṣe yí ìwẹ̀fà ará Etiópíà lọ́kàn padà. (Ìṣe 8:26-38) Ọ̀nà mìíràn tá a fi lè jẹ́ ẹni tó ní ẹ̀mí aṣáájú ọ̀nà ni pé ká mọ bá a ṣe lè lo Bíbélì dáadáa àti ‘bá a ṣe lè bá àwọn èèyàn fèrò-wérò látinú Ìwé Mímọ́.’ (Ìṣe 17:2, 3) Bíi ti Fílípì, a fẹ́ sapá láti wàásù ìhìn rere níbikíbi tá a bá ti lè rí àwọn èèyàn àti ní gbogbo ìgbà tí àyè bá yọ.
5. Kí ló lè ran àwọn Kristẹni tí wọ́n jẹ́ òbí lọ́wọ́ láti gbin ẹ̀mí aṣáájú ọ̀nà sọ́kàn àwọn ọmọ wọn?
5 Nínú Ìdílé àti Ìjọ: Láìsí àní-àní, ẹ̀mí tí Fílípì ní àti àpẹẹrẹ rẹ̀ ní ipa tó dára gan-an lórí àwọn ọmọbìnrin rẹ̀. (Ìṣe 21:9) Lọ́nà kan náà, bí àwọn Kristẹni tí wọ́n jẹ́ òbí bá ka ìgbòkègbodò Ìjọba Ọlọ́run sí ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ nígbèésí ayé wọn, èyí á fún àwọn ọmọ wọn níṣìírí láti ṣe bíi tiwọn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè ti rẹ àwọn òbí ní òpin ọ̀sẹ̀, òbí tó bá ń fi tọkàntọkàn wàásù fún àwọn èèyàn yóò gbin ohun táwọn ọmọ rẹ̀ ò lè gbàgbé títí ayé sí wọn lọ́kàn.—Òwe 22:6.
6. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọyì àwọn aṣáájú ọ̀nà inú ìjọ wa?
6 Fílípì gba Pọ́ọ̀lù àti Lúùkù lálejò. Àwọn méjèèjì jẹ́ Kristẹni onítara tí ń ṣiṣẹ́ kára nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. (Ìṣe 21:8, 10) Báwo la ṣe lè fi hàn lónìí pé a mọyì àwọn Ẹlẹ́rìí onítara, a sì fẹ́ tì wọ́n lẹ́yìn? A lè sọ fún àwọn aṣáájú ọ̀nà pé àá fẹ́ bá wọn ṣiṣẹ́ ní òwúrọ̀ tàbí ọ̀sán ọjọ́ tó jẹ́ pé àwọn ará díẹ̀ ló máa ń jáde òde ẹ̀rí. (Fílí. 2:4) A tún lè pè wọ́n wá sílé wa ká lè jọ ní ìfararora tí ń gbéni ró. Ipòkípò tá a bá wà, ẹ jẹ́ kí gbogbo wa sapá láti ní ẹ̀mí aṣáájú ọ̀nà.