Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
Àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ wọ̀nyí la óò gbé yẹ̀ wò nínú àtúnyẹ̀wò aláfẹnusọ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ní ọ̀sẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ní August 30, 2004. Alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ yóò darí àtúnyẹ̀wò yìí fún ọgbọ̀n ìṣẹ́jú, èyí tá a gbé ka àwọn iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ tá a ṣe ní ọ̀sẹ̀ July 5 sí August 30, 2004. [Àkíyèsí: Níbi tí a kò bá ti tọ́ka sí ibi tí a ti mú ìdáhùn jáde lẹ́yìn ìbéèrè kan, o ní láti ṣe ìwádìí fúnra rẹ láti wá ìdáhùn sí ìbéèrè náà.—Wo ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 36 àti 37.]
ÀNÍMỌ́ Ọ̀RỌ̀ SÍSỌ
1. Báwo la ṣe lè fi “inú tútù àti ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀” ṣàlàyé ìdí tá a fi ní irú ìrètí tá a ní? (1 Pét. 3:15) [be-YR ojú ìwé 192 ìpínrọ̀ 2 sí 4]
2. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa fi ìdánilójú sọ̀rọ̀? (Róòmù 8:38, 39; 1 Tẹs. 1:5; 1 Pét. 5:12) [be-YR ojú ìwé 194]
3. Báwo la ṣe lè fi hàn pé ọ̀rọ̀ dá wa lójú? [be-YR ojú ìwé 195 ìpínrọ̀ 3 sí ojú ìwé 196 ìpínrọ̀ 4]
4. Báwo lèèyàn ṣe ń lo ọgbọ́n inú, kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì, báwo la sì ṣe lè lo ọgbọ́n inú síbẹ̀ ká dúró lórí òtítọ́? (Róòmù 12:18) [be-YR ojú ìwé 197]
5. Kí ni ẹnì kan tó ń lo ọgbọ́n inú yóò kọ́kọ́ ronú lé lórí kó tó sọ̀rọ̀? (Òwe 25:11; Jòh. 16:12) [be-YR ojú ìwé 199]
IṢẸ́ AKẸ́KỌ̀Ọ́ KÌÍNÍ
6. Báwo ni irú ọ̀rọ̀ tá à ń sọ àti ọ̀nà tá à ń gbà kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe lè fi bá a ṣe tẹ̀ síwájú tó nínú òtítọ́ hàn? [be-YR ojú ìwé 74 ìpínrọ̀ 3 sí ojú ìwé 75 ìpínrọ̀ 2]
7. Kí ni ‘ríra àkókò tí ó rọgbọ padà fún ara wa’ túmọ̀ sí, báwo la sì ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀? (Éfé. 5:16) [w02-YR 11/15 ojú ìwé 22 àti 23]
8. Báwo ni Ìwé Mímọ́ ṣe fi hàn kedere pé gbogbo èèyàn dọ́gba lójú Ọlọ́run, báwo ló sì ṣe yẹ kí èyí kan iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa? [w02-YR 1/1 ojú ìwé 5 àti 7]
9. Báwo ni Jèhófà, orúkọ aláìlẹ́gbẹ́ tí Ẹlẹ́dàá ń jẹ́, ti ṣe pàtàkì tó? [w02-YR 1/15 ojú ìwé 5]
10. Kí ló mú kí ẹbọ Ébẹ́lì “níye lórí ju ti” Kéènì lọ, ẹ̀kọ́ wo sì ni èyí kọ́ wa nípa “ẹbọ ìyìn” tí à ń rú? (Héb. 11:4; 13:15) [w02-YR 1/15 ojú ìwé 21 ìpínrọ̀ 6 sí 8]
BÍBÉLÌ KÍKÀ Ọ̀SỌ̀Ọ̀SẸ̀
11. Báwo ni Léfítíkù 18:3 ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti yẹra fún níní èrò òdì nípa ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́? (Éfé. 4:17-19) [w02-YR 2/1 ojú ìwé 29]
12. Kí ni “ìṣù búrẹ́dì méjì” tí àlùfáà àgbà máa ń fi rúbọ gẹ́gẹ́ bí “ọrẹ ẹbọ fífì” nígbà Àjọyọ̀ Àwọn Ọ̀sẹ̀ (Pẹ́ńtíkọ́sì) dúró fún tá a bá ń ṣàlàyé àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì? (Léf. 23:15-17) [w98-YR 3/1 ojú ìwé 13 ìpínrọ̀ 21]
13. Bí obìnrin kan bá ṣe panṣágà bí ìwé Númérì orí karùn-ún ṣe sọ, báwo ni ‘itan rẹ̀ yóò ṣe joro’? (Núm. 5:27) [w84-YR 4/15 ojú ìwé 30]
14. Kí nìdí tí Míríámù àti Áárónì fi ń sọ̀rọ̀ sí Mósè nítorí pé ó fẹ́ aya tí ó jẹ́ ará Kúṣì? (Núm. 12:1)
15. Kí ni “ìwé Àwọn Ogun Jèhófà”? (Núm. 21:14)