ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 8/04 ojú ìwé 3
  • Àwọn Ìfilọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìfilọ̀
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2004
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2004
km 8/04 ojú ìwé 3

Àwọn Ìfilọ̀

◼ Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a ó fi lọni ní August: A lè fi èyíkéyìí nínú àwọn ìwé pẹlẹbẹ olójú ewé 32 tó tẹ̀ lé e yìí lọni: Akoso Naa Ti Yoo Mu Paradise Wá, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà—Ta Ni Wọ́n? Kí Ni Wọ́n Gbà Gbọ́?, Ẹmi Awọn Oku—Wọn Ha Le Ran Ọ Lọwọ Tabi Pa Ọ Lara Bi? Wọn Ha Wa Niti Gidi Bi?, Gbádùn Iwalaaye Lori Ilẹ Ayé Titilae!, Ìwé Kan Tí Ó Wà fún Gbogbo Ènìyàn, Iwọ Ha Nilati Gbàgbọ́ Ninu Mẹtalọkan Bí?, Ki Ni Ète Igbesi-Aye? Bawo Ni Iwọ Ṣe Le Rí I?, Kí Ní Ń Ṣẹlẹ̀ sí Wa Nígbà Tí A Bá Kú?, Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú?, Orukọ Atọrunwa naa Tí Yoo Wà Titilae, Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi?, Ọ̀nà Tó Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun—Ṣé O Ti Rí I?, àti “Sawo O! Emi Nsọ Ohun Gbogbo Di Ọtun.” September: Sún Mọ́ Jèhófà. Bí kò bá sí, a lè lo ìwé Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì! tàbí ìwé Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye. October: Ilé Ìṣọ́ àti Jí! la ó fi lọni jálẹ̀ gbogbo oṣù yìí. Níbi tí wọ́n bá ti fìfẹ́ hàn, kí a fi ìwé pẹlẹbẹ Béèrè lọni, kí a sì sapá gidigidi láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. November: Ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà la ó fi lọni. Bí ẹni tá à ń wàásù fún bá sọ pé òun ò lọ́mọ, fún un ní ìwé pẹlẹbẹ Béèrè. Gbìyànjú láti lo ìwé pẹlẹbẹ yìí láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

◼ Àwọn nọ́ńbà tẹlifóònù tí à ń lò ní ẹ̀ka ọ́fíìsì ní Igieduma nìwọ̀nyí láfikún sí àwọn tá a ti ní tẹ́lẹ̀: 0803-4561101, 0803-4561102, 0803-4561103.

◼ Kí alábòójútó olùṣalága tàbí ẹni tó bá yàn ṣàyẹ̀wò àkáǹtì ìjọ ní September 1 tàbí bó bá ti lè yá tó lẹ́yìn náà. Bí a bá ti ṣe èyí, ẹ ṣèfilọ̀ rẹ̀ fún ìjọ lẹ́yìn tẹ́ ẹ bá ti ka ìròyìn ìnáwó ti oṣù tó ń bọ̀.

◼ Ní August 31, 2004 tàbí bó bá ti lè yá tó lẹ́yìn náà, kẹ́ ẹ ṣírò gbogbo iye ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ àti ìwé ìròyìn tí ìjọ ní lọ́wọ́, bí a ti ń ṣe lọ́dọọdún. Ìṣirò yìí jọ èyí tí olùṣekòkáárí ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ máa ń ṣe lóṣooṣù nípa kíka àwọn ìwé náà lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan. Kí ẹ kọ àròpọ̀ iye wọn sórí fọ́ọ̀mù Literature Inventory (S-18). Ẹ gba àròpọ̀ iye ìwé ìròyìn tó wà lọ́wọ́ lọ́dọ̀ (àwọn) ìránṣẹ́ tó ń bójú tó ìwé ìròyìn. Kí akọ̀wé ìjọ tí ń ṣe kòkáárí bójú tó ìṣirò ọdọọdún náà. Akọ̀wé àti alábòójútó olùṣalága ìjọ tí ń ṣe kòkáárí ni kó fọwọ́ sí fọ́ọ̀mù náà. Gbogbo ìjọ tí ń ṣe kòkáárí yóò gba fọ́ọ̀mù Literature Inventory (S-18) mẹ́ta-mẹ́ta. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ fi ẹ̀dà àkọ́kọ́ ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì ní September 6, ó pẹ́ tán. Ẹ tọ́jú ẹ̀dà kejì sínú fáìlì ìjọ. Ẹ lè lo ẹ̀dà kẹta láti fi ṣe ìṣírò tẹ́ ẹ kọ́kọ́ máa ṣe kẹ́ ẹ tó dà á kọ sínú àwọn ìyókù.

◼ Láti August 26 sí August 30, 2004, a óò ṣírò gbogbo iye ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tó wà lọ́wọ́ ní Bẹ́tẹ́lì Igieduma. Nítorí èyí, a ò ní ṣiṣẹ́ lórí ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ èyíkéyìí tí àwọn ìjọ bá béèrè láwọn ọjọ́ wọ̀nyí.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́