ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w99 7/15 ojú ìwé 26-28
  • Àwọn Ẹni Ọ̀wọ́n Ń Bẹ ní Namibia!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ẹni Ọ̀wọ́n Ń Bẹ ní Namibia!
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ìsọ̀rí
  • Bí Wíwa Kùsà Nípa Tẹ̀mí Ṣe Bẹ̀rẹ̀
  • Àwọn Òṣìṣẹ́ Alákòókò Kíkún Dé
  • Dídán Àwọn Òkúta Ṣíṣeyebíye Náà
  • A Nílò Àwọn Olùwakùsà Nípa Tẹ̀mí
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
w99 7/15 ojú ìwé 26-28

Àwọn Ẹni Ọ̀wọ́n Ń Bẹ ní Namibia!

NAMIBIA tẹ́ rẹrẹ dé nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ kìlómítà [1,500] ní apá gúúsù ìwọ̀ oòrùn etíkun Áfíríkà. Ògèlètè yanrìn tí afẹ́fẹ́ gbá jọ, àwọn òkè olókùúta, àti pẹ̀tẹ́lẹ̀ onítaàrá tó lọ salalu ló wà ní gbogbo etíkun orílẹ̀-èdè yìí. Àwọn òkúta iyebíye tó jẹ́ onírúurú àwọ̀ wà ní àwọn etíkun olókùúta wẹ́wẹ́ ti ilẹ̀ Namibia. Kódà nígbà mí-ìn èèyàn lè rí dáyámọ́ǹdì níbẹ̀. Àmọ́, orílẹ̀-èdè yìí ní ohun mìíràn tó tún ṣeyebíye ju àwọn òkúta wọ̀nyí lọ. Namibia ní àwọn ẹni ọ̀wọ́n—àwọn èèyàn tó wá láti onírúurú àwùjọ orílẹ̀-èdè.

Àwọn èdè kan tó jọra wọn, tí wọ́n ń pè ní èdè Khoisan, làwọn tó gbé ní Namibia ní ìjímìjí ń sọ. Ohùn wọn tó ń dún bí ẹni pọ́nnu tókí ń jẹ́ ká tètè dá wọn mọ̀. Lára àwọn tó ń sọ èdè Khoisan lónìí ni àwọn Damara adúmáadán, àwọn èèyàn rébété tí wọ́n jẹ́ apọ́nbéporẹ́, àwọn tí wọ́n ń pè ní Nama, àti àwọn gbajúgbajà ògbójú ọdẹ tí wọ́n ń jẹ́ Bushman. Ọ̀pọ̀ ẹ̀yà àwọn aláwọ̀ dúdú ló tún ti wá sí Namibia ní àwọn ọ̀rúndún àìpẹ́ yìí. Àwọn wọ̀nyí wà ní ìsọ̀rí àwùjọ orílẹ̀-èdè mẹ́ta: àwọn Ovambo (ẹ̀yà tó pọ̀ jù lọ ní Namibia), àwọn Herero, àti àwọn Kavango. Ọ̀rúndún kọkàndínlógún ni àwọn ará Yúróòpù bẹ̀rẹ̀ sí gbé ní Namibia. Àwọn aṣíwọ̀lú bẹ̀rẹ̀ sí dé lẹ́yìn ìgbà táa ṣàwárí dáyámọ́ǹdì nínú iyanrìn tó wà ní aṣálẹ̀ náà.

Àwọn olùgbé Namibia jẹ́ ẹni ọ̀wọ́n nítorí pé wọ́n jẹ́ apá kan ayé aráyé tí Ọlọ́run fún ní Ọmọ rẹ̀, tó sì tipa bẹ́ẹ̀ ṣí ọ̀nà ìyè àìnípẹ̀kun sílẹ̀. (Jòhánù 3:16) Ọgọ́rọ̀ọ̀rún ará Namibia tí wọ́n wá láti inú ọ̀pọ̀ ẹ̀yà ló ti tẹ́wọ́ gba ìhìn iṣẹ́ ìgbàlà náà báyìí. A lè pe àwọn wọ̀nyí ní ẹni ọ̀wọ́n nítorí pé wọ́n wà lára “àwọn ohun fífani-lọ́kàn-mọ́ra tí ń bẹ nínú gbogbo orílẹ̀-èdè” tí a ń kó jọ sínú ilé ìjọsìn Jèhófà nísinsìnyí.—Hágáì 2:7.

Bí Wíwa Kùsà Nípa Tẹ̀mí Ṣe Bẹ̀rẹ̀

Ọdún 1928 ni wíwa kùsà nípa tẹ̀mí bẹ̀rẹ̀ ní Namibia. Lọ́dún yẹn ni ẹ̀ka ọ́fíìsì Watch Tower Society ti Gúúsù Áfíríkà fi ọ̀kẹ́ méjì àbọ̀ [50,000] ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ránṣẹ́ sáwọn èèyàn tó wà káàkiri orílẹ̀-èdè náà. Lọ́dún kejì, arábìnrin kan tó jẹ́ Kristẹni ẹni àmì òróró, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Lenie Theron, láti Gúúsù Áfíríkà, lọ síbẹ̀ láti lọ bẹ àwọn tó fìfẹ́ hàn wò. Láàárín oṣù mẹ́rin tó tẹ̀ lé e, òun nìkan ṣoṣo dá rìnrìn àjò káàkiri orílẹ̀-èdè ńlá yìí, ó sì fi ẹgbàata [6,000] ìwé tí ń ranni lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sóde lédè Afrikaans, Gẹ̀ẹ́sì, àti German. Gbogbo iṣẹ́ yìí kò já sásán.

Fún àpẹẹrẹ, gbé ọ̀ràn Bernhard Baade, olùwakùsà kan nílùú Germany, yẹ̀ wò. Lọ́dún 1929, ó rí ẹrù ẹyin gbà látọ̀dọ̀ àgbẹ̀ kan, àmọ́ ojú ìwé ìtẹ̀jáde Watch Tower kan ní ọkùnrin ọ̀hún fi pọ́n ẹyin kọ̀ọ̀kan. Bernhard fi ìháragàgà ka ojú ìwé kọ̀ọ̀kan náà, ó sì fẹ́ mọ ẹni tó kọ ìwé náà. Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, ó dé ojú ìwé tó kẹ́yìn, níbi tó ti rí àdírẹ́sì Watch Tower Society ti Germany. Ni Berhhard bá kọ̀wé béèrè fún ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ sí i, bó ṣe di ará Namibia àkọ́kọ́ tó rí òtítọ́ nìyẹn.

Àwọn Òṣìṣẹ́ Alákòókò Kíkún Dé

Lọ́dún 1950, àwọn míṣọ́nnárì mẹ́rin táa ti dá lẹ́kọ̀ọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ Watchtower Bible School of Gilead gúnlẹ̀ sí Namibia. Nígbà tó fi máa di 1953, àwọn míṣọ́nnárì ti di mẹ́jọ. Lára wọn ní Dick àti Coralie Waldron, tọkọtaya ará Australia tí wọ́n ṣì ń fi tòótọ́tòótọ́ sìn níhìn-ín títí di àkókò yìí. Ọ̀pọ̀ olùpòkìkí Ìjọba náà lákòókò kíkún láti Gúúsù Áfíríkà àti láti òkè òkun ló ti wá lọ́wọ́ nínú ìwakùsà nípa tẹ̀mí yìí ní Namibia. A tún ti rán àwọn míṣọ́nnárì mìíràn, àti àwọn akẹ́kọ̀ọ́yege ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́, sí Namibia.

Kókó mìíràn tó ti jẹ́ kí ìdàgbàsókè tẹ̀mí ní Namibia yá bẹ́ẹ̀ ni títúmọ̀ àti títẹ àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jáde ní àwọn èdè pàtàkì-pàtàkì, bí èdè Herero, Kwangali, Kwanyama, Nama/Damara, àti Ndonga. Láti ọdún 1990 ni ọ́fíìsì rèterète kan tó jẹ́ ti ìtumọ̀ èdè àti ilé fún àwọn òṣìṣẹ́ alákòókò kíkún tí wọ́n yọ̀ǹda ara wọn, ti wà ní olú ìlú orílẹ̀-èdè náà, Windhoek. Karen Deppisch, tí òun pẹ̀lú ọkọ rẹ̀ ti jọ ṣiṣẹ́ ajíhìnrere alákòókò kíkún ní onírúurú àgbègbè ní Namibia, sọ pé: “Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ló máa ń yà lẹ́nu nígbà tí a bá fi ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a tẹ̀ ní èdè tiwọn lọ̀ wọ́n, pàápàá nígbà tó bá jẹ́ pé ìwọ̀nba ìwé díẹ̀ ló wà nírú èdè bẹ́ẹ̀.”

Dídán Àwọn Òkúta Ṣíṣeyebíye Náà

Atẹ́gun tó ń fẹ́ rìrì àti iyanrìn tí atẹ́gùn náà ń gbé lọ síwá sẹ́yìn láìmọye ìgbà ti sọ àwọn òkúta ṣíṣeyebíye tó wà ní Namibia di èyí tí ń dán yinrinyinrin. Ṣùgbọ́n, irú ohun tí ń ṣẹlẹ̀ lọ́nà ti ìṣẹ̀dá bẹ́ẹ̀ kò lè mú àwọn ẹni ọ̀wọ́n jáde. Ó ń béèrè ìsapá kí àwọn ẹ̀dá ènìyàn aláìpé tó lè “bọ́ ògbólógbòó àkópọ̀ ìwà sílẹ̀,” kí wọ́n sì gbé àkópọ̀ ìwà Kristi tuntun wọ̀. (Éfésù 4:20-24) Fún àpẹẹrẹ, bíbọlá fún àwọn baba ńlá tó ti kú jẹ́ àṣà tó rinlẹ̀ gan-an láàárín ọ̀pọ̀ ẹ̀yà àwọn ará Namibia. Àwọn mẹ́ńbà ìdílé, àti àwọn aládùúgbò sábà máa ń ṣenúnibíni sí àwọn tí kò bá ṣe ohun tó jẹ mọ́ ìjọsìn baba ńlá. Nígbà táwọn èèyàn bá kẹ́kọ̀ọ́ láti inú Bíbélì pé àwọn òkú “kò mọ nǹkan kan,” ìdánwò dé nìyẹn. (Oníwàásù 9:5) Lọ́nà wo?

Ẹlẹ́rìí kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Herero ṣàlàyé, ó ní: “Ìpèníjà ńlá lò jẹ́ láti ṣègbọràn sí òtítọ́. Mo gbà kí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa wá bá mi kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ṣùgbọ́n ó pẹ́ kí n tó lè máa fi àwọn nǹkan tí mò ń kọ́ sílò. Lákọ̀ọ́kọ́, mo ní láti wádìí dáadáa bóyá ẹ̀mí mi dè bí mo bá kọ̀ láti ṣe ohun tí àṣà wa ń béèrè. Fún àpẹẹrẹ, màá ní láti wakọ̀ gba àwọn àgbègbè kan kọjá ní Namibia tí mi ò ni dúró láti fi òkúta sórí ibojì tàbí kí n ṣí fìlà mi láti fi hàn pé mo júbà àwọn òkú. Díẹ̀díẹ̀, ó wá dá mi lójú pé irun kan kò ní tu lára mi bí n kò bá jọ́sìn àwọn baba ńlá tó ti kú. Mi ò lè sọ bí inú mi ṣe dùn tó pé Jèhófà ti bù kún ìsapá mi láti ran ìdílé mi àti àwọn olùfìfẹ́hàn mìíràn lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́!”

A Nílò Àwọn Olùwakùsà Nípa Tẹ̀mí

Kó tó di pé àwọn míṣọ́nnárì dé lọ́dún 1950, ẹyọ ẹnì kan ṣoṣo ló jẹ́ akéde ìhìn rere ní Namibia. Iye akéde ń pọ̀ sí i ṣáá ni, wọ́n ti di márùn-ún dín lẹ́gbẹ̀rún báyìí [955]. Síbẹ̀, iṣẹ́ ṣì wà láti ṣe. Àní àwọn àgbègbè kan wà tí a kò tí ì fọwọ́ kàn. Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe fún ọ láti wá sìn níbi tí àìní fún àwọn onítara olùpòkìkí Ìjọba gbé pọ̀? Bó bá ṣeé ṣe fún ọ, dákun, wá sí Namibia kóo wá ràn wá lọ́wọ́ láti wá bá wa wá àwọn òkúta ṣíṣeyebíye nípa tẹ̀mí, kóo sì bá wa dán wọn, kí wọ́n lè máa dán yinrinyinrin.—Fi wé Ìṣe 16:9.

[Àwòrán ilẹ̀/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

ÁFÍRÍKÀ

NAMIBIA

[Àwọn àwòrán]

Namibia jẹ́ orílẹ̀-èdè kan tó kún fún àwọn òkúta ṣíṣeyebíye tó wuni

[Àwọn Credit Line]

Àwòrán ilẹ̀: Mountain High Maps® Copyright © 1997 Digital Wisdom, Inc.; Dáyámọ́ǹdì: Nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda onínúure Namdek Diamond Corporation

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Gbogbo ẹ̀yà tó wà ní Namibia là ń wàásù ìhìn rere náà fún

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]

Ǹjẹ́ o lè sìn níbi tí àìní fún àwọn olùpòkìkì Ìjọba náà gbé pọ̀?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́