ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb18 September ojú ìwé 8
  • Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Bá A Ṣe Lè Sọ Ìjíròrò Lásán Di Ìwàásù

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Bá A Ṣe Lè Sọ Ìjíròrò Lásán Di Ìwàásù
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2018
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Máa Bẹ̀rẹ̀ Ìjíròrò Lọ́nà Àìjẹ́-Bí-Àṣà
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2014
  • Sọ Ohun Táwọn Èèyàn Nífẹ̀ẹ́ Sí
    Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn—Máa Sọ Wọ́n Dọmọ Ẹ̀yìn
  • Jẹ́ Kó Máa Yá Ẹ Lára Láti Bá Àwọn Èèyàn Sọ̀rọ̀
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2023
  • Bí A Ṣe Lè Mú Ọ̀nà Tí A Gbà Ń Fọ̀rọ̀ Wérọ̀ Sunwọ̀n Sí I
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
Àwọn Míì
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2018
mwb18 September ojú ìwé 8

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Bá A Ṣe Lè Sọ Ìjíròrò Lásán Di Ìwàásù

Ó ṣeé ṣe fún Jésù láti jẹ́rìí fún obìnrin ará Samáríà yẹn lọ́nà àìjẹ́-bí-àṣà torí pé ó bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò pẹ̀lú obìnrin náà. Báwo làwa náà ṣe lè sunwọ̀n sí i tó bá dọ̀rọ̀ ká bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò pẹ̀lú ẹni tá ò mọ̀ rí?

Jésù ń bá obìnrin ará Samáríà kan sọ̀rọ̀ ní ìdí kànga
  • Jẹ́ kára ẹ yọ̀ mọ́ọ̀yàn, kó o sì máa bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti rẹ Jésù, síbẹ̀ ó dọ́gbọ́n tọrọ omi lọ́wọ́ obìnrin náà, kó lè bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò pẹ̀lú rẹ̀. Tíwọ náà bá fẹ́ bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò, kọ́kọ́ kí ẹni náà pẹ̀lú ọ̀yàyà, lẹ́yìn náà o lè wá sọ̀rọ̀ nípa bójú ọjọ́ ṣe rí tàbí ohun kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣẹlẹ̀. Rántí pé ńṣe lo kàn fẹ́ bá ẹni náà sọ̀rọ̀, torí náà o lè sọ̀rọ̀ nípa kókó èyíkéyìí tẹ́ni náà máa nífẹ̀ẹ́ sí. Tí kò bá dá ẹ lóhùn, má fi ṣèbínú. Tún wá ẹlòmíì tí wàá bá sọ̀rọ̀. Bẹ Jèhófà pé kó fún ẹ nígboyà.​—Ne 2:4; Iṣe 4:29.

  • Máa wá ọ̀nà tó o lè gbà sọ ìhìn rere fáwọn èèyàn, àmọ́ má ṣe kánjú. Má ṣe fipá mú ẹni náà láti bá ẹ sọ̀rọ̀. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó lè má bá ẹni náà lára mu, kó má sì fẹ́ bá ẹ sọ̀rọ̀ mọ́. Má ṣe jẹ́ kó ká ẹ lára tó ò bá láǹfààní láti wàásù fún ẹni náà kí ìjíròrò yín tó parí. Tó bá ṣòro fún ẹ láti wàásù lọ́nà àìjẹ́-bí-àṣà, máa fi kọ́ra láti bá àwọn tí o kò mọ̀ rí sọ̀rọ̀, má wulẹ̀ wàásù fún wọn, ṣáà bá wọn sọ̀rọ̀. [Jẹ́ káwọn ará wo fídíò 1 kẹ́ ẹ sì jíròrò rẹ̀.]

  • Tó o bá fẹ́ wàásù fún ẹnìkan, o lè sọ ohun kan tó o gbà gbọ́ fún ẹni náà, táá sì mú kẹ́ni náà bi ẹ́ ní ìbéèrè láti mọ púpọ̀ sí i. Jésù sọ ọ̀rọ̀ kan tó gbàfiyèsí obìnrin náà, ìdí nìyẹn tó fi bi Jésù ní ìbéèrè. Nígbà tí Jésù fi máa dáhùn ìbéèrè obìnrin yẹn, ó ti bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù ìhìn rere fún un. [Jẹ́ káwọn ará wo fídíò 2 kẹ́ ẹ sì jíròrò rẹ̀, lẹ́yìn náà kẹ́ ẹ wo fídíò 3 kẹ́ ẹ sì jíròrò rẹ̀.]

Àwọn obìnrin méjì ń ju bọ́ọ̀lù síra wọn

Láti bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò dà bí ìgbà téèyàn ju bọ́ọ̀lù sẹ́nì kan. Ó gba pé kéèyàn lẹ́nì kan tó fẹ́ bá sọ̀rọ̀ kó tó lè ṣeé ṣe, kò sì fi bẹ́ẹ̀ ṣòro láti bẹ̀rẹ̀. Tó o bá ti rí ẹni kan tó o fẹ́ bá sọ̀rọ̀, “ju” ọ̀rọ̀ sí i, kó o wá wò ó bóyá ẹ̀ẹ́ lè máa bá ọ̀rọ̀ yín lọ?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́