ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 7/13 ojú ìwé 4-6
  • Ọ̀nà Tuntun Tá A Fẹ́ Máa Gbà Wàásù Láwọn Ibi Tí Èrò Pọ̀ Sí

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọ̀nà Tuntun Tá A Fẹ́ Máa Gbà Wàásù Láwọn Ibi Tí Èrò Pọ̀ Sí
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2013
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ọ̀nà Tuntun Tó Lárinrin Tá A Ó Máa Gbà Wàásù Láwọn Ibi Tí Èrò Pọ̀ Sí
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2014
  • Wàásù Ìhìn Rere Náà Níbi Gbogbo
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
  • Àwọn Ọ̀nà Tá À Ń Gbà Wàásù Ìhìn Rere
    A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà
  • Ìjẹ́rìí Òpópónà Tó Gbéṣẹ́
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2011
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2013
km 7/13 ojú ìwé 4-6

Ọ̀nà Tuntun Tá A Fẹ́ Máa Gbà Wàásù Láwọn Ibi Tí Èrò Pọ̀ Sí

1. Àpẹẹrẹ wo ni àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ fi lélẹ̀?

1 Àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ wàásù láti ilé dé ilé, wọ́n sì tún wàásù ní gbangba. (Ìṣe 20:20) Bí àpẹẹrẹ, wọ́n wàásù ní tẹ́ńpìlì, níbi tí wọ́n mọ̀ pé èrò pọ̀ sí. (Ìṣe 5:42) Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù wà ní ìlú Áténì, ojoojúmọ́ ló máa ń wàásù fún àwọn èèyàn lọ́jà. (Ìṣe 17:17) Lóde òní, ìwàásù ilé-dé-ilé ṣì ni ọ̀nà tó ṣe pàtàkì jù tá a gbà ń kéde ìhìn rere náà. Àmọ́, a tún máa ń lọ wàásù láwọn ibi tí wọ́n ń gbé ọkọ̀ sí, níbi ìṣòwò, níbi ìgbafẹ́, ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà táwọn èèyàn ti ń lọ tí wọ́n ń bọ̀ àti láwọn ibòmíì tá a ti lè rí àwọn èèyàn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a retí pé tó bá ṣeé ṣe, ó yẹ kí gbogbo akéde máa wàásù láwọn ibi tí èrò pọ̀ sí, ọ̀pọ̀ nínú wa tún máa láǹfààní láti kópa nínú ọ̀nà tuntun méjì tá a fẹ́ máa gbà wàásù láwọn ibi tí èrò pọ̀ sí.

2. Ọ̀nà tuntun wo la gbìyànjú wò láti fi wàásù lóṣù November 2011?

2 Àkànṣe Ìwàásù Láwọn Ìlú Tí Èrò Pọ̀ Sí: Bá a ṣe sọ nínú Ìwé Ọdọọdún 2013, lójú ìwé 16 àti 17, lóṣù November 2011, a gbìyànjú ọ̀nà tuntun kan wò láti fi wàásù níbi tí èrò pọ̀ sí ní ìlú New York, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. A to àwọn ìwé wa ní onírúurú èdè sórí tábìlì àtàwọn ohun tó ṣeé gbé kiri, a sì gbé e sí àwọn ibi tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń gbà kọjá láàárín ìgboro. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ló ń kọjá níbẹ̀ lójoojúmọ́, títí kan àwọn tó ń gbé láwọn ilé tó ní odi àti géètì gàgàrà àtàwọn tí a kì í fi bẹ́ẹ̀ bá nílé. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló sì tipa bẹ́ẹ̀ gbọ́ ìhìn rere. Láìpẹ́ yìí, láàárín oṣù kan péré, ẹgbẹ̀rún mẹ́ta àti mẹ́tàdínlẹ́gbẹ̀rin [3,797] ìwé ìròyìn làwọn èèyàn gbà, wọ́n sì tún gba ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ dín mẹ́rìnlá [7,986] ìwé ńlá. Kódà, ọ̀pọ̀ àwọn tó ń kọjá níbẹ̀ ló sọ pé ká wá máa kọ́ àwọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Lájorí ìdí tá a fi ṣètò ọ̀nà ìwàásù tuntun yìí ni láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, torí náà àwọn ará máa ń tètè fi àdírẹ́sì àwọn èèyàn tí wọ́n bá pàdé ránṣẹ́ sí ìjọ tó wà nítòsí àwọn èèyàn náà, kí wọ́n lè bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

3. Báwo ni ètò Ọlọ́run ṣe fẹ́ kí ọ̀nà tuntun tá a gbà wàásù yìí gbòòrò tó?

3 Torí pé ọ̀nà tuntun tá a gbà wàásù yìí kẹ́sẹ járí, ètò Ọlọ́run fẹ́ ká bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe irú àkànṣe ìwàásù yìí kárí ayé láwọn ìlú tí èrò pọ̀ sí. Ẹ̀ka ọ́fíìsì orílẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kan ló máa yan àwọn ìlú tí wọ́n ti máa ṣe àkànṣe ìwàásù náà. Irú àwọn ìlú bẹ́ẹ̀ máa jẹ́ ibi tí ibùdókọ̀ pọ̀ sí tàbí ibi tí àwọn ọ́fíìsì tàbí ilé pọ̀ sí, táwọn èèyàn sì ń lọ tí wọ́n ń bọ̀. Ẹ̀ka ọ́fíìsì máa kàn sí àwọn ìjọ tó bá máa kópa, wọ́n sì máa fún wọn ní ìtọ́ni púpọ̀ sí i. Ní ọ̀pọ̀ ibi tí wọ́n ti ṣe irú àkànṣe ìwàásù yìí, àwọn aṣáájú-ọ̀nà déédéé àtàwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe ni wọ́n sábà máa ń lò, àmọ́ láwọn ibòmíì, àwọn aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ pẹ̀lú máa ń kópa nínú iṣẹ́ náà.

4. Báwo la ṣe ń ṣe àkànṣe ìwàásù láwọn ìlú tí èrò pọ̀ sí?

4 Bá A Ṣe Ń Ṣe É: Àwọn tó ń ṣe àkànṣe ìwàásù láwọn ìlú tí èrò pọ̀ sí sábà máa ń dúró kí àwọn tó ń kọjá lọ lè yà sọ́dọ̀ wọn níbi tí wọ́n gbé tábìlì náà sí. Wọ́n á sì sọ fún ẹni tó bá wá sí ìdí tábìlì náà pé kó mú ìwé tó bá wù ú. Inú àwọn aṣáájú-ọ̀nà yìí máa ń dùn láti dáhùn ìbéèrè táwọn èèyàn bá ní látinú Bíbélì. Báwọn èèyàn bá gba ìwé níbẹ̀, wọn kì í sọ pé kí wọ́n mú ọrẹ wá. Àmọ́ bí ẹni náà bá béèrè nípa bí a ṣe ń rí owó ná sórí iṣẹ́ ìwàásù tí à ń ṣe, wọ́n lè ṣàlàyé fún un pé tó bá fẹ́, ó lè fi ọrẹ ránṣẹ́ sí èyíkéyìí lára àwọn àdírẹ́sì tó wà nínú ìwé náà. Tí àyè bá wà, wọ́n lè bi ẹni náà pé: “Ṣé o máa fẹ́ ká wá ẹ wá sílé?” tàbí kí wọ́n sọ pé, “Ǹjẹ́ o mọ̀ pé a tún máa ń kọ́ àwọn èèyàn lékọ̀ọ́ Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́?”

5. Àǹfààní wo ni tọkọtaya kan ti rí lẹ́nu iṣẹ́ yìí?

5 Ọ̀nà tuntun tá a gbà wàásù yìí ti mú èrè wá gan-an. Tọkọtaya kan sọ pé: “Ojoojúmọ́ tá a bá dúró sí ìdí tábìlì wa, tá a sì rí ọ̀pọ̀ èèyàn tó ń kọjá, ṣe ló máa ń rán wa létí bí iṣẹ́ ìwàásù tí à ń ṣe kárí ayé ṣe gbòòrò tó. Bá a ṣe ń rí ọ̀pọ̀ èèyàn tó ń lọ tó ń bọ̀, tá a sì ń ronú lórí bí Jèhófà ṣe ń bójú tó ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn ti jẹ́ ká túbọ̀ rọ̀ mọ́ ìpinnu wa pé a kò ní jẹ́ kí ohunkóhun ṣe pàtàkì sí wa ju iṣẹ́ ìwàásù lọ. A máa ń wò ó pé Jèhófà ń wo ọkàn àwọn èèyàn tó ń kọjá lọ́dọ̀ wa kó lè pe àwọn tó fẹ́ ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Ìgbà yìí gan-an la rí i pé a túbọ̀ sún mọ́ àwọn áńgẹ́lì tá a jọ ń ṣiṣẹ́ ìwàásù.”

6. (a) Ètò wo làwọn ìjọ kan ṣe láti máa wàásù níbi tí èrò pọ̀ sí? Báwo ni ètò yìí ṣe yàtọ̀ sí àkànṣe ìwàásù láwọn ìlú tí èrò pọ̀ sí? (b) Báwo ni àwọn ìjọ ṣe lè fọwọ́ sowọ́ pọ̀ láti ṣe iṣẹ́ yìí?

6 Ètò Tí Ìjọ Kọ̀ọ̀kan Lè Ṣe Láti Wàásù Níbi Tí Èrò Pọ̀ Sí: Láfikún sí àkànṣe ìwàásù láwọn ìlú tí èrò pọ̀ sí, ọ̀pọ̀ ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà tún ṣètò tuntun kan ní ìpínlẹ̀ ìwàásù ìjọ wọn. Wọ́n ṣètò pé kí àwọn akéde gbé tábìlì tàbí ohun tó ṣeé gbé kiri kalẹ̀ síbi tí èrò pọ̀ sí ní ìpínlẹ̀ ìwàásù ìjọ wọn. Ètò tí ìjọ kọ̀ọ̀kan ṣe yìí yàtọ̀ sí èyí tí ẹ̀ka ọ́fíìsì ń ṣe fún àkànṣe ìwàásù láwọn ìlú tí èrò pọ̀ sí. Nínú àkànṣe ìwàásù láwọn ìlú tí èrò pọ̀ sí, ẹ̀ka ọ́fíìsì ló máa ń yan àwọn ìlú tí wọ́n ti máa ṣe iṣẹ́ náà, àwọn akéde láti onírúurú ìjọ ló sì jọ máa ń kópa nínú rẹ̀.—Wo àpótí tá a pe àkọlé rẹ̀ ní, “Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ Ṣe Pàtàkì.”

7. Níbi tó bá ṣeé ṣe, báwo ni àwọn alàgbà ṣe lè ṣètò ìwàásù níbi tí èrò pọ̀ sí ní ìpínlẹ̀ ìwàásù ìjọ wọn?

7 Àwọn alàgbà á kọ́kọ́ wò ó bóyá àwọn ibi tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń gbà kọjá wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wọn, wọ́n á sì pinnu bóyá káwọn ṣètò kí ìjọ wọn lọ máa wàásù níbẹ̀. Lára àwọn ibi tẹ́ ẹ lè gbé tábìlì tàbí àwọn ohun tó ṣeé gbé kiri sí ni àwọn ibùdókọ̀ ńláńlá, ojúde ìlú, ibi ìgbafẹ́, òpópónà tí àwọn èèyàn ti ń lọ tí wọ́n ń bọ̀, ibi ìtajà, iléèwé, ibi tí wọ́n ti ń wọkọ̀ òfurufú tàbí rélùwéè àtàwọn ibi tí wọ́n ti máa ń ṣe ayẹyẹ ọdọọdún. Ó máa dáa kí tábìlì náà máa wà ní ibì kan pàtó, láwọn ọjọ́ kan pàtó ní àkókò kan náà. A tún ti kíyè sí pé ibi tí oríṣiríṣi ilé ìtajà pọ̀ sí ló máa ń dáa ká gbé tábìlì sí dípò iwájú ilé ìtajà kan ṣoṣo tó jẹ́ pé ńṣe làwọn èèyàn kàn máa ń gbájú mọ́ ohun tí wọ́n bá wá. Láwọn ibì kan, irú bí ojú ọ̀nà tí kò fẹ̀ tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń gbà kọjá, ohun tó ṣeé gbé kiri ló dáa jù ká to àwọn ìwé wa sí dípò tábìlì. Àwọn alàgbà lè tẹ àwọn èpo ẹ̀yìn ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! àti ti ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni jáde látorí ìkànnì wa. A dìídì ṣe àwọn èpo ẹ̀yìn ìwé yìí síbẹ̀ kẹ́ ẹ lè tẹ̀ ẹ́ sórí bébà fẹ̀rẹ̀gẹ̀dẹ̀, kẹ́ ẹ sì lè lò ó fún ìwàásù níbi tí èrò pọ̀ sí. Kí àwọn tó bá ń kópa nínú iṣẹ́ yìí tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn tó ń ṣe àkànṣe ìwàásù láwọn ìlú tí èrò pọ̀ sí, kí wọ́n sì tẹ̀ lé ìtọ́ni tí alábòójútó iṣẹ́ ìsìn bá fún wọn. Bí ẹ bá sì gba àdírẹ́sì lọ́wọ́ ẹni tí kì í gbé ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín, ẹ tètè kọ ọ̀rọ̀ tó yẹ sínú fọ́ọ̀mù padà-lọ-ṣèbẹ̀wò, ìyẹn Please Follow Up (S-43) kí ẹ sì fún akọ̀wé ìjọ yín.

8. Tí kò bá sí irú ìṣètò yìí nínú ìjọ wa, àwọn àǹfààní wo ló tún lè ṣí sílẹ̀ fún wa láti wàásù?

8 O Lè Máa Wàásù Níbi Tí Èrò Pọ̀ Sí: Àwọn ìjọ míì lè ṣàìní ibi tí wọ́n lè gbé tábìlì tàbí ohun tó ṣeé gbé kiri sí láti máa fún àwọn èèyàn ní ìwé ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wọn torí àwọn tó ń kọjá níbẹ̀ lè máà tó nǹkan. Síbẹ̀, àwọn akéde irú àwọn ìjọ bẹ́ẹ̀ ṣì lè sapá láti máa wàásù láwọn ibi tí èrò pọ̀ sí. Tó o bá mọ àwọn ibi ìtajà tó wà ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà, ọjà tàbí ilé ìtajà kan térò máa ń pọ̀ sí, ibùdókọ̀ tàbí ibi ìgbafẹ́, ibi tí àwọn èèyàn máa ń kóra jọ sí tàbí ibi tí wọ́n ti máa ń ṣe ayẹyẹ ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín, a jẹ́ pé o ṣì lè wàásù níbi tí èrò pọ̀ sí nìyẹn.

9. Kí nìdí tó fi yẹ ká fọwọ́ pàtàkì mú wíwàásù fáwọn èèyàn níbi gbogbo tá a bá ti lè rí wọn?

9 Ìfẹ́ Jèhófà ni pé “kí a gba gbogbo onírúurú ènìyàn là, kí wọ́n sì wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.” (1 Tím. 2:4) Torí náà, à ń sa gbogbo ipá wa láti rí i pé a wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fún ọ̀pọ̀ èèyàn kí òpin tó dé. (Mát. 24:14) Ṣùgbọ́n, kò rọrùn láti bá ọ̀pọ̀ èèyàn nílé láwọn ibì kan. Síbẹ̀, a ṣì lè rí wọn bá sọ̀rọ̀ tá a bá bá wọn pàdé níta. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ìwàásù láwọn ibi tí èrò pọ̀ sí yìí nìkan ni ibi tí ẹlòmíì ti máa láǹfààní láti gbọ́ ìhìn rere náà. Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa wàásù fún àwọn èèyàn níbi gbogbo tá a bá ti lè rí wọn, ká sì tipa bẹ́ẹ̀ ṣàṣeparí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa ní kíkún.—2 Tím. 4:5.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 5]

Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ Ṣe Pàtàkì

A gbọ́ pé àwọn akéde kan láti ìjọ tó wà nítòsí ara wọn máa ń lọ wàásù níbi tí èrò pọ̀ sí ní òpópónà kan náà, níbi ìgbọ́kọ̀sí kan náà àti láwọn ibi ìṣòwò kan náà tàbí ibùdókọ̀ àti ibi ìgbafẹ́ kan náà. Àwọn akéde láti ìjọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ sì ti fún àwọn èèyàn ní ìwé láwọn ibi tá a mẹ́nu kàn yìí. Èyí ti mú kó dà bí ìgbà tí à ń yọ àwọn tá à ń wàásù fún níbẹ̀ lẹ́nu, kódà bí àwọn akéde yìí ò bá tiẹ̀ lọ síbẹ̀ nígbà kan náà. Torí náà, tá a bá ń wàásù níbi tí èrò pọ̀ sí, ìpínlẹ̀ ìwàásù ìjọ wa ló sábà máa ń dáa jù pé ká ti máa ṣiṣẹ́.

Bí àwọn akéde bá fẹ́ lọ wàásù ní ìpínlẹ̀ ìwàásù ìjọ míì, kí wọ́n sọ fún alábòójútó iṣẹ́ ìsìn wọn kó lè sọ fún alábòójútó iṣẹ́ ìsìn ìjọ tó ni ìpínlẹ̀ ìwàásù yẹn kó lè fún wọn láyè. Tí àwọn ìjọ tó ń sọ èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ bá jọ ń wàásù ní ìpínlẹ̀ kan náà, kí àwọn alábòójútó iṣẹ́ ìsìn àwọn ìjọ náà jọ sọ̀rọ̀ kí wọ́n lè ṣètò ìwàásù náà lọ́nà tí kò fi ní múnú bí àwọn tá à ń wàásù fún. Bí ìfọwọ́sowọ́pọ̀ tó dánmọ́rán bá wà, ohun gbogbo máa ṣẹlẹ̀ “lọ́nà tí ó bójú mu àti nípa ìṣètò.”—1 Kọ́r. 14:40.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́