ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 6/11 ojú ìwé 2
  • Ìjẹ́rìí Òpópónà Tó Gbéṣẹ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìjẹ́rìí Òpópónà Tó Gbéṣẹ́
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2011
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Wàásù Ìhìn Rere Náà Níbi Gbogbo
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
  • Ọ̀nà Tuntun Tá A Fẹ́ Máa Gbà Wàásù Láwọn Ibi Tí Èrò Pọ̀ Sí
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2013
  • Ọ̀nà Tuntun Tó Lárinrin Tá A Ó Máa Gbà Wàásù Láwọn Ibi Tí Èrò Pọ̀ Sí
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2014
  • O Ha Ti Gbìyànju Ìjẹ́rìí Ìrọ̀lẹ́ Bí?
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2011
km 6/11 ojú ìwé 2

Ìjẹ́rìí Òpópónà Tó Gbéṣẹ́

1. Ọ̀nà wo la lè gbà tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù?

1 Nígbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù lórí ilẹ̀ ayé, Jésù kò lọ́ tìkọ̀ láti bá àwọn èèyàn tó pàdé lójú ọ̀nà àti láwọn ibòmíì táwọn èèyàn máa ń pọ̀ sí sọ̀rọ̀. (Lúùkù 9:57-61; Jòh. 4:7) Ó fẹ́ jẹ́ iṣẹ́ pàtàkì fún gbogbo èèyàn tó bá lè rí. Lóde òní, ìjẹ́rìí òpópónà jẹ́ ọ̀kan lára ọ̀nà tó dára jù lọ tá a lè gbà ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè ní ọgbọ́n Ọlọ́run. (Òwe 1:20) A máa túbọ̀ ṣàṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ náà tá a bá ń lo ìdánúṣe àti ìfòyemọ̀.

2. Báwo la ṣe lè lo ìdánúṣe tá a bá ń ṣe ìjẹ́rìí òpópónà?

2 Máa Lo Ìdánúṣe: Ó máa ń dáa ká bá ẹnì kọ̀ọ̀kan sọ̀rọ̀ dípò tí a ó fi jókòó tàbí ká dúró síbì kan, ká máa retí pé kí àwọn tó ń kọjá lọ wá bá wa. Rẹ́rìn-ín músẹ́, wo ojú ẹni tó o fẹ́ bá sọ̀rọ̀, fara balẹ̀, kó o sì fọ̀yàyà sọ̀rọ̀. Tó bá jẹ́ ẹ̀yin méjì lẹ jọ ń ṣiṣẹ́, ó dára kẹ́ ẹ bá ẹni ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ sọ̀rọ̀. Ọ̀nà míì tó o tún lè gbà lo ìdánúṣe ni pé kó o gbìyànjú láti pa dà rí àwọn tó bá fi ìfẹ́ hàn. Tó bá ṣeé ṣe, nígbà tẹ́ ẹ bá parí ìjíròrò yín, o lè dọ́gbọ́n béèrè lọ́wọ́ ẹni náà bó o ṣe lè kàn sí i nígbà míì. Àwọn akéde kan máa ń ṣe ìjẹ́rìí òpópónà ní ibì kan náà déédéé, èyí máa ń jẹ́ kí wọ́n lè máa bá àwọn èèyàn kan náà sọ̀rọ̀ léraléra, kí wọ́n lè mú kí ìfẹ́ tí wọ́n ní sí ẹ̀kọ́ òtítọ́ jinlẹ̀ sí i.

3. Báwo la ṣe lè lo ìfòyemọ̀ nígbà tá a bá ń ṣe ìjẹ́rìí òpópónà?

3 Máa Lo Ìfòyemọ̀: Máa lo ìfòyemọ̀ kó o lè mọ ibi tó o máa dúró sí lójú pópó àti ẹni tó o máa bá sọ̀rọ̀. Kò pọn dandan kí á bá gbogbo àwọn tó ń kọjá lọ sọ̀rọ̀. Jẹ́ ẹni tó ní àkíyèsí. Bí àpẹẹrẹ, bí ẹni kan bá ń kánjú, o lè fi sílẹ̀ kó máa bá tiẹ̀ lọ. Tó o bá ń wàásù níbi tí wọ́n ti ń tajà, ńṣe ni kó o fọgbọ́n ṣe é, kí inú má bàa bí ẹni tó ni ibẹ̀. Ohun tó máa dára jù ni pé kó o jẹ́rìí fáwọn èèyàn nígbà tí wọ́n bá fẹ́ kúrò nílé ìtajà, dípò tí wàá fi jẹ́rìí fún wọn nígbà tí wọ́n bá ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ wọlé. Má ṣe yọ sí àwọn èèyàn lọ́nà tó máa dẹ́rù bà wọ́n. Bákan náà, máa lo ìfòyemọ̀ nígbà tó o bá fẹ́ fún ẹnì kan ní ìwé. Bí ẹnì kan kò bá fi bẹ́ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ rẹ, o lè fún un ní ìwé àṣàrò kúkúrú, dípò tí wàá fi fún un ní ìwé ìròyìn.

4. Kí nìdí tí ìjẹ́rìí òpópónà fi ṣàǹfààní tó sì gbádùn mọ́ni?

4 Ìjẹ́rìí òpópónà máa ń jẹ́ ká lè fún ọ̀pọ̀ yanturu irúgbìn òtítọ́ láàárín àkókò kúkúrú. (Oníw. 11:6) A tún lè pàdé àwọn tó jẹ́ pé a lè máà bá nílé nígbà tá a bá ń wàásù láti ilé dé ilé. Ìjẹ́rìí òpópónà máa ń gbádùn mọ́ni, ó sì máa ń so èso rere, o ò ṣe ṣètò láti máa lọ́wọ́ nínú rẹ̀?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́