Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ June 27
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ JUNE 27
Orin 123 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
bt orí 5 ìpínrọ̀ 17 sí 22 (25 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Sáàmù 52-59 (10 min.)
Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run (20 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
10 min: Àwọn Ìfilọ̀. “Wákàtí Mélòó Ni Kí N Ròyìn?” Alàgbà ni kó sọ àsọyé yìí. Lẹ́yìn àsọyé náà, lo àwọn àbá tó wà lójú ìwé 4 láti ṣe àṣefihàn béèyàn ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní Saturday àkọ́kọ́ lóṣù July. Fún àwọn ará ní ìṣírí láti lọ́wọ́ nínú rẹ̀.
10 min: Múra Sílẹ̀ Láti Lo Àwọn Ìwé Ìròyìn Lóṣù July. Ìjíròrò. Fi ìṣẹ́jú kan tàbí méjì sọ̀rọ̀ lórí ohun tó wà nínú àwọn ìwé ìròyìn náà. Lẹ́yìn náà, yan àpilẹ̀kọ méjì tàbí mẹ́ta, kó o wá ní kí àwọn ará sọ àwọn ìbéèrè àti ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí wọ́n lè fi gbé ọ̀rọ̀ wọn kalẹ̀. Ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo ìtẹ̀jáde kọ̀ọ̀kan.
15 min: Máa Lo Ọgbọ́n Nígbà Tó O Bá Ń Wàásù. Ìjíròrò tá a gbé ka ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ojú ìwé 197 sí ojú ìwé 200, ìpínrọ̀ 1. Ṣe àṣefihàn kan, tó fi hàn bí akéde kan kò ṣe lo ọgbọ́n nígbà tó ń fèsì ọ̀rọ̀ tí wọ́n sábà máa ń fi bẹ́gi dínà ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín. Lẹ́yìn náà, kó o wá ṣe àṣefihàn míì nípa bí àkéde náà ṣe fi ọgbọ́n dáhùn ọ̀rọ̀ kan náà.
Orin 92 àti Àdúrà