Ọ̀nà Tuntun Tó Lárinrin Tá A Ó Máa Gbà Wàásù Láwọn Ibi Tí Èrò Pọ̀ Sí
1. Kí la rọ àwọn ìjọ tó ní àwọn ibi tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń gbà kọjá ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wọn pé kí wọ́n máa ṣe?
1 A rọ àwọn ìjọ tó láwọn ibi tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń gbà kọjá ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wọn pé kí wọ́n ṣètò kí ìjọ wọn lọ máa wàásù níbẹ̀ nípa lílo àwọn tábìlì tàbí àwọn àtẹ ìkówèésí tó ṣeé gbé kiri. Tó bá jẹ́ àtẹ ìkówèésí tó ṣeé gbé kiri lẹ lò, kí akéde kan dúró tàbí kò jókòó tì í. Àmọ́, akéde méjì ni kó dúró ti tábìlì tẹ́ ẹ pàtẹ ìwé sí. Kí àwọn tó ń dúró ti àtẹ ìwé náà jẹ́ ọlọ́yàyà, ẹni tó yá mọ́ọ̀yàn, kí ìrísí àti ìṣesí wọn sì fani mọ́ra. Tí ẹnì kan tó ń kọjá lọ bá yà síbi tí wọ́n pàtẹ ìwé sí, ọ̀kan lára àwọn akéde tó wà níbẹ̀ náà lè bẹ̀rẹ̀ sí í bá a fèrò wérò. Ó lè sọ pé: “Ǹjẹ́ ẹ fẹ́ mọ ohun tí Bíbélì sọ nípa àkòrí yìí.” Akéde kan tàbí méjì mí ì lè wà nítòsí ibi tí ẹ pàtẹ ìwé sí, kí wọ́n máa jẹ́rìí lọ́nà àìjẹ́-bí-àṣà.
2. Sọ ìrírí kan tó jẹ́ ká rí ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa wàásù níbi tí èrò pọ̀ sí tá a pàtẹ ìwé wa sí.
2 Ọ̀nà ìwàásù tuntun níbi tí èrò pọ̀ sí ti mú ká ní ọ̀pọ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ọmọ ilé ẹ̀kọ́ gíga kan pinnu láti ṣe ìwádìí nípa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àmọ́ kò mọ ibi tí Gbọ̀ngàn Ìjọba wà. Ní ọ̀sẹ̀ tó tẹ̀ lé e, ó tajú kán rí tábìlì tá a pàtẹ ìwé sí nínú ọgbà ilé ìwé rẹ̀. Ó bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ní báyìí, ọmọ ilé ẹ̀kọ́ gíga ìgbà yẹn ti ṣèrìbọmi, òun náà sì ti ń kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù láwọn ibi tí èrò pọ̀ sí.
3. Kí làwọn kan sọ nípa ọ̀nà tuntun tá a gbà ń wàásù láwọn ibi tí èrò pọ̀ sí?
3 Arábìnrin kan tó kópa nínú ọ̀nà tuntun tá a gbà ń wàásù níbi tí èrò pọ̀ sí sọ pé: “Àwọn kan máa ń wá sídìí àtẹ ìkówèésí wa láti gba àwọn ìwé ìròyìn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde. Àwọn mí ì ò tiẹ̀ tí ì gbọ́ nípa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà rí. Mo lè sọ pé ọ̀nà tó dáa gan-an nìyí láti bá ọ̀pọ̀ èèyàn sọ̀rọ̀.” Arábìnrin mí ì sọ pé: “Ọ̀nà tuntun tó lárinrin lèyí jẹ́ torí pé ńṣe làwọn èèyàn á wá bá ọ kódà bí wọn ò tiẹ̀ fi bẹ́ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ rẹ, wọ́n ṣáà fẹ́ mọ ohun tá à ń ṣe níbẹ̀.”
4. Kí nìdí tó fi dáa ká máa pàtẹ àwọn ìwé wa síbì kan pàtó, ní ọjọ́ kan pàtó àti ní àkókò kan náà lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀?
4 Ó dáa ká máa pàtẹ àwọn ìwé wa síbì kan pàtó, láwọn ọjọ́ kan pàtó àti ní àkókò kan náà lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Èyí á jẹ́ kí àwọn èèyàn dojúlùmọ̀ àwọn ìwé tá à ń pàtẹ, yóò sì jẹ́ kí ara tù wọ́n láti wá bi wá ní ìbéèrè tàbí kí wọ́n gba àwọn ìwé wa. Ṣé ìjọ tó ò ń dara pọ̀ mọ́ ti ṣètò ìwàásù láwọn ibi tí èrò pọ̀ sí? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ìwọ náà lè kópa nínú ọ̀nà ìwàásù tó gbádùn mọ́ni tó sì ń kẹ́sẹ járí tí a gbà ń “polongo ìjọba Ọlọ́run káàkiri.”—Lúùkù 9:60.