ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 4/15 ojú ìwé 1
  • Máa Ra Àkókò Tí Ó Rọgbọ Pa Dà Lẹ́nu Iṣẹ́ Òjíṣẹ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Máa Ra Àkókò Tí Ó Rọgbọ Pa Dà Lẹ́nu Iṣẹ́ Òjíṣẹ́
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2015
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ǹjẹ́ Ò Ń Ṣe Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Láṣeyanjú?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2019
  • Lo Àkókò Rẹ Lọ́nà Gbígbéṣẹ́
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1999
  • Ọ̀nà Tuntun Tá A Fẹ́ Máa Gbà Wàásù Láwọn Ibi Tí Èrò Pọ̀ Sí
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2013
  • Iṣẹ́ Ìwàásù Láti Ilé dé Ilé
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2015
km 4/15 ojú ìwé 1

Máa Ra Àkókò Tí Ó Rọgbọ Pa Dà Lẹ́nu Iṣẹ́ Òjíṣẹ́

Lọ́dún iṣẹ́ ìsìn 2014, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lo ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó bílíọ̀nù méjì [1,945,487,604] wákàtí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Ẹ̀rí tó ṣe kedere sì nìyẹn jẹ́ pé a ti pinnu láti gbájú mọ́ iṣẹ́ ìsìn Jèhófà! (Sm. 110:3; 1 Kọ́r. 15:58) Nígbà tó jẹ́ pé “àkókò tí ó ṣẹ́ kù ti dín kù,” ǹjẹ́ a lè túbọ̀ máa fọgbọ́n lo àkókò wa lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ ká bàa lè wàásù fún àwọn èèyàn púpọ̀ sí i?—1 Kọ́r. 7:29.

Tá a bá fẹ́ ra àkókò tí ó rọgbọ pa dà lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, ó gba pé ká máa ronú nípa àkókò tá a lè rí ọ̀pọ̀ èèyàn bá sọ̀rọ̀. Bí àpẹẹrẹ, tó bá jẹ́ pé o sábà máa ń lọ́wọ́ nínú apá kan lẹ́nú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa fún wákàtí kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, tó sì jẹ́ pé o kì í rẹ́ni bá sọ̀rọ̀, ǹjẹ́ o lè ṣe àwọn àyípadà kan táá jẹ́ kó o lè máa rí èèyàn púpọ̀ sí i bá sọ̀rọ̀? Òótọ́ ni pé bí nǹkan ṣe rí ní àdúgbò kan lè yàtọ̀ sí ti ibòmíì. Àmọ́ tá a bá lè tẹ̀ lé àwọn àbá tá a máa gbé yẹ̀ wò báyìí, ó máa jẹ́ ká lè lo àkókò wa lọ́nà tó túbọ̀ dára, kó má bàa di pé ńṣe la kàn ń “gbá afẹ́fẹ́.”—1 Kọ́r. 9:26.

  • Ìwàásù Ilé-Dé-Ilé: Láti ọ̀pọ̀ ọdún wá, iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé ni ọ̀pọ̀ akéde fi máa ń bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn lójúmọ́. Àmọ́ nígbà tó jẹ́ pé ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń lọ sí ibi iṣẹ́ ní àárọ̀, ǹjẹ́ o lè gbìyànjú láti ṣe ìwàásù ilé-dé-ilé lọ́wọ́ ìrọ̀lẹ́, nígbà tí ọ̀pọ̀ èèyàn máa wà nílé tí ara wọn á sì balẹ̀? Lọ́wọ́ àárọ̀ tàbí lọ́wọ́ ìrọ̀lẹ́, ìjẹ́rìí òpópónà tàbí láwọn ibi ìtajà lè sèso rere.

  • Ìjẹ́rìí Láwọn Ibi Tí Èrò Pọ̀ Sí: A lè gbé tábìlì àtàwọn ohun tó ṣeé tì kiri sáwọn ibi tí èrò pọ̀ sí ní ìpínlẹ̀ ìwàásù ìjọ wa. (Wo Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa July 2013, ojú ìwé 5.) Tó bá ṣẹlẹ̀ pé èrò ò fi bẹ́ẹ̀ wọ́ lọ wọ́ bọ̀ ní àdúgbò kan bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́, Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn ìjọ lè pinnu pé ká gbé tábìlì tàbí àwọn ohun tó ṣeé tì kiri náà lọ sí àdúgbò míì tí èrò pọ̀ sí dáadáa.

  • Ìpadàbẹ̀wò àti Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì: Ǹjẹ́ o lè ṣètò láti máa ṣe ìpadàbẹ̀wò àti ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì láwọn àkókò tí àwọn apá míì nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa kì í fi bẹ́ẹ̀ méso jáde? Bí àpẹẹrẹ, tó bá jẹ́ pé o máa ń rí àwọn èèyàn bá sọ̀rọ̀ dáadáa lẹ́nú iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé ní àárọ̀ Sátidé, ǹjẹ́ o lè ṣètò láti ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́sàn-án tàbí nírọ̀lẹ́? Tó bá jẹ́ pé ìpadàbẹ̀wò lẹ fẹ́ lọ ṣe, ṣe a lè pín àwọn tí wọ́n bá ní ìpadàbẹ̀wò sí apá ibì kan náà pa pọ̀ kí wọ́n bàa lè ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́?

Òótọ́ ni pé nígbàkigbà tá a bá kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù, a máa ń ròyìn àkókò tá a lò, àmọ́ ayọ̀ wa máa ń kún sí i tí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa bá méso jáde. Tó o bá rí i pé lílọ́wọ́ nínú apá kan lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa kò fi bẹ́ẹ̀ gbéṣẹ́ tó láwọn àkókò kan, tún gbìyànjú apá míì. Bẹ Jèhófà, “Ọ̀gá ìkórè” náà pé kó tọ́ ẹ sọ́nà kó o lè ra àkókò tí ó rọgbọ pa dà lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ!—Mát. 9:38.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́