ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 6/99 ojú ìwé 4
  • Lo Àkókò Rẹ Lọ́nà Gbígbéṣẹ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Lo Àkókò Rẹ Lọ́nà Gbígbéṣẹ́
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1999
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìpàdé fún Iṣẹ́ Ìsìn Pápá
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2009
  • Máa Ra Àkókò Tí Ó Rọgbọ Pa Dà Lẹ́nu Iṣẹ́ Òjíṣẹ́
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2015
  • Gbéṣẹ́ Nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
  • Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Pápá Tó Ń Gbéni Ró, Tó Ń Múni Gbára Dì, Tó sì Ń Mú Ká Wà Létòlétò
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2015
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1999
km 6/99 ojú ìwé 4

Lo Àkókò Rẹ Lọ́nà Gbígbéṣẹ́

1 Àkókò kan náà ni gbogbo èèyàn ní tó lè lò lọ́sẹ̀ kọ̀ọ̀kan. Èyí táa bá yà sọ́tọ̀ fún títan ìhìn rere náà kálẹ̀ ṣeyebíye ní pàtàkì nítorí àkókò táa lò nínú iṣẹ́ tí ń gbẹ̀mí là ni. (Róòmù 1:16) A ń fi ìmọrírì wa hàn fún èyí nípa mímúra sílẹ̀ dáadáa fún iṣẹ́ ìsìn táa wéwèé, títètè dé síbi ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn, kí a sì lọ lọ́gán sí ìpínlẹ̀ wa. Ṣe la óò máa wàásù dípò fífi àkókò ṣòfò níbi ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn. Níwọ̀n bí Jèhófà ti kọ́ wa pé “ohun gbogbo ni ìgbà tí a yàn kalẹ̀ wà fún,” a gbọ́dọ̀ lo àkókò tí a ti yà sọ́tọ̀ fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ lọ́nà gbígbéṣẹ́ ní ti gidi.—Oníw. 3:1.

2 Fọgbọ́n Lo Àkókò Rẹ: A máa ń rí ọ̀pọ̀ ìbùkún gbà nígbà tí a bá ń fi ìdúróṣinṣin tẹ̀ lé ìtòlẹ́sẹẹsẹ tí ó ń jẹ́ ká lè máa lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá déédéé. Bó ṣe sábà máa ń rí, ìyọrísí rere táa bá ní nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ máa ń sinmi lórí iye àkókò táa bá lò nínú iṣẹ́ ìsìn. Nípa yíyí bí a ṣe ń ṣe nǹkan padà díẹ̀, a ha lè ya àkókò púpọ̀ sí i sọ́tọ̀ fún iṣẹ́ ìsìn pápá bí? Bí àpẹẹrẹ, lẹ́yìn pípín ìwé ìròyìn lọ́jọ́ Saturday, ǹjẹ́ a lè lo àkókò díẹ̀ láfikún láti ṣe àwọn ìpadàbẹ̀wò mélòó kan? Bí a bá ti lo àkókò díẹ̀ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá lọ́jọ́ Sunday, ǹjẹ́ a lè lo àkókò díẹ̀ láti ṣe àwọn ìpadàbẹ̀wò tàbí láti darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú? Ṣé a lè ṣe púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ ilé dé ilé wa nípa ṣíṣe ìjẹ́rìí òpópónà? Lọ́nà yìí tàbí òmíràn, a lè mú kí iṣẹ́ ìsìn wa sunwọ̀n sí i.

3 Nígbà táa bá wà lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́, a lè máa fi àkókò ṣíṣeyebíye ṣòfò bí a ò bá kíyè sára. Àmọ́ ṣáá o, nígbà tí ojú ọjọ́ kò bá bára dé, ó lè dára pé ká wá ibòji tàbí ilé kan dúró sí. Ṣùgbọ́n, lọ́pọ̀ ìgbà, a lè lo àkókò yẹn fún wíwàásù tàbí kíkọ́ àwọn ẹlòmíràn ní òtítọ́. Ṣé a lè dúró ní ilé ẹnì kan tó ń fìfẹ́ hàn tàbí ọ̀kan lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa?

4 Ní àwọn ọdún lọ́ọ́lọ́ọ́, o túbọ̀ ń ṣòro láti bá àwọn èèyàn nílé. Láti kojú ìṣòro yìí, ọ̀pọ̀ akéde máa ń ṣe iṣẹ́ ìjẹ́rìí ilé dé ilé wọn lákòókò tó yàtọ̀ síra wọn. Èé ṣe tí o kò fi gbìyànjú jíjẹ́rìí ní ọ̀sán tàbí ìrọ̀lẹ́?

5 Ó sàn jù pé kí a má máa bá ara wa tàkúrọ̀sọ nígbà tí a bá ń ṣe iṣẹ́ òpópónà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ dúró lọ́tọ̀ọ̀tọ̀ kí ẹ sì tọ àwọn èèyàn lọ kí ẹ lè bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò pẹ̀lú wọn. Nípa báyìí, ẹ óò lè lo àkókò yín lọ́nà tó túbọ̀ gbéṣẹ́ sí i, ẹ óò sì rí ìdùnnú púpọ̀ sí i láti inú iṣẹ́ náà.

6 Lo Àǹfààní Tó Bá Ṣí Sílẹ̀ Láti Jẹ́rìí: Nígbà tí onílé kan sọ fún Ẹlẹ́rìí kan pé òun ò fẹ́ gbọ́ ìwàásù, Ẹlẹ́rìí náà bi í bóyá ẹlòmíràn wà nínú ilé tí òun lè bá sọ̀rọ̀. Èyí yọrí sí jíjíròrò pẹ̀lú baálé ilé náà, ẹni tó ti dùbúlẹ̀ àìsàn fún ọ̀pọ̀ ọdún tí kò sì lè kúrò lórí ibùsùn. Ìrètí tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ ìfẹ́ tó ní nínú ìwàláàyè dọ̀tun. Kò pẹ́ tára rẹ̀ fi yá, ó bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí àwọn ìpàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, ó sì ń ṣàjọpín ìrètí tuntun tó ṣẹ̀ṣẹ̀ rí pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn!

7 Arábìnrin kan tó jẹ́ ọ̀dọ́langba lo àbá tí a dá pé ká máa lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìsìn pápá ṣáájú àkókò fún Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ. Lẹ́nu ọ̀nà tó kọ́kọ́ yà, ó rí ọmọdébìnrin ọlọ́dún mẹ́tàlá kan tó tẹ́tí sílẹ̀ dáadáa tó sì gba ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́. Lọ́jọ́ kejì, ní ilé ẹ̀kọ́, arábìnrin kékeré yìí rí ọmọdébìnrin yẹn kan náà. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà, arábìnrin kékeré yìí sọ fún ọmọdébìnrin yẹn pé òun fẹ́ bá a kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì gbà bẹ́ẹ̀.

8 Mú Kí Àkókò Tí O Bá Lò Jójúlówó: Nínípìn-ín déédéé nínú iṣẹ́ ìsìn pápá ń ràn wá lọ́wọ́ láti mú òye wa dàgbà nínú bí a ṣe ń sọ ìhìn rere náà. Ǹjẹ́ o lè mú kí bí o ṣe ń bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò lẹ́nu ọ̀nà sunwọ̀n sí i nípa lílo ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó túbọ̀ gbéṣẹ́? Ǹjẹ́ o lè di olùkọ́ tó túbọ̀ já fáfá nígbà tí o bá ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé? Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, yóò ṣeé ṣe fún ọ láti mú kí àkókò tí o bá lò nínú iṣẹ́ ìsìn gbéṣẹ́ ní gidi, yóò sì mú kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ túbọ̀ máa méso jáde.—1 Tím. 4:16.

9 Níwọn bí “àkókò tí ó ṣẹ́ kù ti dín kù,” ó yẹ kí ìgbésí ayé wa kún fún àwọn iṣẹ́ Kristẹni. (1 Kọ́r. 7:29) Yíya àkókò sọ́tọ̀ fún iṣẹ́ ìwàásù ni ó yẹ kí ó jẹ́ ohun àkọ́múṣe. Ẹ jẹ́ kí a máa nípìn-ín tó jọjú nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́, kí a sì máa fi ìtara ṣe é. Àkókò jẹ́ ohun iyebíye àgbàyanu tí Jèhófà fún wa. Máa fi ọgbọ́n lò ó nígbà gbogbo, kí o sì mú kó gbéṣẹ́.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 4]

Ṣàgbéyẹ̀wò Àwọn Àbá Wọ̀nyí:

◼ Tètè dé síbi ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn.

◼ Bó bá ṣe bọ́gbọ́n mu sí, mú kí àwùjọ tí ń jẹ́rìí kéré.

◼ Yẹra fún jíjáfara láti dé ìpínlẹ̀ yín.

◼ Ẹ ṣiṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ yín nígbà tí ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn èèyàn bá wà nílé.

◼ Dá ṣiṣẹ́ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan tí kò bá léwu láti ṣe bẹ́ẹ̀.

◼ Ṣe ìpadàbẹ̀wò níbi tó sún mọ́ ìpínlẹ̀ tí ẹ ti ṣe iṣẹ́ ilé dé ilé.

◼ Mú kí ọwọ́ rẹ dí nínú iṣẹ́ ìsìn nígbà tí àwọn ẹlòmíràn tí ẹ jọ jáde bá pẹ́ lẹ́nu ọ̀nà kan.

◼ Lo àkókò tí o fi ṣíwọ́, nítorí ojú ọjọ́ tí kò bára dé, lọ́nà tó ṣàǹfààní.

◼ Nígbàkígbà tó bá ṣeé ṣe àti bí àyíká ipò bá ṣe rí, lò ju wákàtí kan lọ.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́