Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ April 20
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ APRIL 20
Orin 3 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cl orí 23 ìpínrọ̀ 10 sí 18 (30 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: 1 Sámúẹ́lì 23-25 (8 min.)
No. 1: 1 Sámúẹ́lì 23:13-23 (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Kí Ni Bíbélì Ṣèlérí Nípa Ọjọ́ Ọ̀la?—igw ojú ìwé 16 ìpínrọ̀ 1 sí 3 (5 min.)
No. 3: Ìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Ronú Kí A Tó Sọ̀rọ̀—Òwe 16:23 (5 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
ẸṢIN Ọ̀RỌ̀ OṢÙ YÌÍ: Ẹ máa rìn gẹ́gẹ́ bí ọlọgbọ́n nípa “ríra àkókò tí ó rọgbọ padà.”—Éfé. 5:15, 16.
15 min: “Bá A Ṣe Lè Jẹ́rìí Nípa Lílo Àwọn Ohun Tá A Fi Ń Pàtẹ Àwọn Ìwé Wa.” Ìjíròrò. Ṣe àṣefihàn yìí: Akéde méjì wà nídìí tábìlì tàbí ohun tó ṣeé tì kiri. Àkéde àkọ́kọ́ kàn rẹ́rìn-ín músẹ́ sí ẹni tó ń kọjá lọ, kò ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ. Lẹ́yìn náà, akéde kejì rẹ́rìn-ín músẹ́ sí ẹlòmíì tó ń kọjá lọ, bí onítọ̀hún ṣe ń sún mọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀, akéde yìí bi í ní ìbéèrè kan, ó sì fi ọ̀yàyà bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò pẹ̀lú rẹ̀. Báwo la ṣe lè lo ohun tá a rí nínú àṣefihàn yìí kódà nígbà tí a kò bá lo ohun tá a fi ń pàtẹ àwọn ìwé wa?
15 min: Ṣe Ohun Tó Máa Jẹ́ Kí Ayọ̀ àti Iyì Ọjọ́ Ìgbéyàwó Rẹ Pọ̀ Sí I. Ìjíròrò tó dá lórí Ilé Ìṣọ́ October 15, 2006, ojú ìwé 28 sí 31. Ẹ lè jíròrò àwọn ìbéèrè yìí: (1) Ní pàtàkì, ojúṣe ta ló jẹ́ láti bójú tó gbogbo ohun tó bá wáyé níbi ìgbéyàwó, títí kan àwẹ̀jẹ àwẹ̀mu? (1 Kọ́r. 11:3) (2) Tó bá dọ̀rọ̀ ìwọṣọ àti ìmúra, báwo ni ìyàwó ṣe lè múra lọ́nà tó ń buyì kún ọjọ́ ìgbéyàwó wọn? (1 Tím. 2:9; 1 Pét. 3:3, 4) (3) Kí nìdí tí kò fi bọ́gbọ́n mu pé kí tọkọtaya lọ yáwó láti fi ṣètò àwẹ̀jẹ àwẹ̀mu?—Òwe 22:7; Róòmù 13:8; 1 Tím. 6:6.
Orin 70 àti Àdúrà