Iṣẹ́ Ìwàásù Láti Ilé dé Ilé
1. Ìbéèrè wo ló jẹ yọ lórí iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé, kí sì nìdí?
1 “Àwọn tó ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ títan Òtítọ́ kálẹ̀ lóríṣiríṣi ọ̀nà á gbà pé lákòókò tá a wà yìí, iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé nípasẹ̀ ìtẹ̀jáde tá a pè ní MILLENNIAL DAWN ló tíì jẹ́ ọ̀nà tó dáa jù láti wàásù Òtítọ́.” Gbólóhùn yìí tó jáde nínú Zion’s Watch Tower ti July 1, 1893, lédè Gẹ̀ẹ́sì tẹnu mọ́ bí iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé ṣe dáa tó. Kárí ayé làwọn èèyàn ti mọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé. Ǹjẹ́ ó ṣì bóde mu láti máa wàásù láti ilé dé ilé níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ṣe ló túbọ̀ ń ṣòro sí i láti bá àwọn èèyàn nílé láwọn ilẹ̀ kan?
2. Ibo ló wà nínú Ìwé Mímọ́ pé ó tọ́ ká máa wàásù láti ilé dé ilé?
2 Ó Bá Ìwé Mímọ́ Mu Ó sì Ṣe Kókó: Inú Ìwé Mímọ́ la ti rí i pé a gbọ́dọ̀ wàásù láti ilé dé ilé. Jésù sọ fún àádọ́rin àwọn ọmọ ẹ̀yin rẹ̀ pé kí wọ́n lọ ní méjì méjì sí ilé àwọn èèyàn. (Lúùkù 10:5-7) Kò pẹ́ sígbà tí Jésù kú tí Bíbélì fi sọ nípa àwọn ọmọ ẹ̀yin rẹ̀ pé: “Ní ojoojúmọ́ nínú tẹ́ńpìlì àti láti ilé dé ilé ni wọ́n sì ń bá a lọ láìdábọ̀ ní kíkọ́ni àti pípolongo ìhìn rere.” (Ìṣe 5:42) Bákan náà, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ́ àwọn èèyàn tìtaratìtara láti ilé dé ilé.—Ìṣe 20:20.
3. Kí ni díẹ̀ lára àwọn àǹfààní tó wà nínú iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé?
3 Lọ́jọ́kọ́jọ́, iṣẹ́ ìwàásù láti ilé dé ilé ṣì jẹ́ ọ̀nà kan pàtàkì láti gbà tan ìhìn rere kálẹ̀. Ó máa ń jẹ́ kó rọrùn fún wa láti “wá” ẹni yíyẹ rí lọ́nà tó tọ́ àti létòlétò. (Mát. 10:11) Ara àwọn èèyàn sábà máa ń balẹ̀ bá a bá bá wọn nínú ilé. Bá a bá rí wọn bá sọ̀rọ̀ lójú kójú, tá a gbọ́ ohùn wọn sétí, tá à ń wojú wọn tá a sì rí àyíká wọn, ó máa ń jẹ́ ká lè fòye mọ ohun tó wù wọ́n àti ohun tó jẹ wọ́n lógún. Ọ̀pọ̀ ìgbà ló máa ń jẹ́ ká ní àǹfààní láti mú kí ìjíròrò náà gbòòrò.
4. Ọ̀nà wo la lè gbà ṣe é tí iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé á fi túbọ̀ máa sèso?
4 Ṣe Àwọn Ètò Tó Bá Yẹ: Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù múra tán láti ṣe ìyípadà tó bá yẹ “nítorí ìhìn rere.” (1 Kọ́r. 9:23) Ì bá dáa báwa náà bá lè yí bá a ṣe ń lo àkókò wa padà ká bàa lè wàásù lákòókò tó ṣeé ṣe láti bá àwọn èèyàn nílé, bóyá lọ́wọ́ ìrọ̀lẹ́, lópin ọ̀sẹ̀ tàbí nígbà ọlidé. Tọ́jú àkọsílẹ̀ àwọn tí kò bá sí nílé, kó o sì tún wá wọn lọ láwọn ọjọ́ míì láàárín ọ̀sẹ̀ tàbí láwọn ìgbà míì lọ́jọ́ yẹn.
5. Báwo la ṣe lè jẹ́ káwọn tí wọ́n ní àìlera kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé?
5 Kódà, àwọn tí wọ́n ní àìlera lè kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé. Bó bá ṣeé ṣe, a lè jẹ́ kírú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ tẹ̀ lé wa nígbà tá a bá ń wàásù láwọn ilé tó ti rọrùn fún wa láti wàásù ká sì rí i pé a ò fi iṣẹ́ ọ̀hún ni wọ́n lára. Arábìnrin kan wà tí ò lè mí dáadáa, ilé kan ṣoṣo ló ti lè wàásù láàárín ọgbọ̀n ìṣẹ́jú. Àmọ́ nígbà táwọn ará jẹ́ kó kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù náà, ayọ̀ ẹ̀ pọ̀ jọjọ, ara ẹ̀ sì yá gágá!
6. Kí nìdí tá a fi gbọ́dọ̀ sọ iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé di apá tá à ń ṣe déédéé nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa?
6 Bá a ṣe ń wàásù láti ẹnu ọ̀nà dé ẹnu ọ̀nà là ń rí ọ̀pọ̀ àwọn ẹni-bí-àgùntàn. Nígbà tí arákùnrin kan kanlẹ̀kùn, ẹni tó wà nínú ilé ní: “Wọlé o. Mo mọ̀ irú ẹni tó o máa jẹ́. Ẹnu àdúrà ni mo wà pé kí Ọlọ́run rán ẹnì tó máa ràn mí lọ́wọ́ sí mi tó o fi dẹ́nu ọ̀nà mi. Ọlọ́run ti gbọ́ àdúrà mi ló ṣe rán ẹ wá.” Ọ̀pọ̀ ẹ̀rí fi hàn pé Jèhófà ń tì wá lẹ́yìn lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé. (Mát. 11:19) Nítorí náà, pinnu láti sọ iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé di apá tó ò ń ṣe déédéé nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ.