Fífi Fóònù Wàásù Máa Ń Gbéṣẹ́ Gan-an
1. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé fífi fóònù wàásù jẹ́ apá pàtàkì nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa?
1 Kí nìdí tó fi yẹ ká gbìyànjú láti fi fóònù wàásù? Torí pé ọ̀nà míì ló jẹ́ láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè gba ìmọ̀ pípéye sínú, èyí tó lè mú kí wọ́n rí ìgbàlà. (2 Pét. 3:9) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìwàásù ilé-dé-ilé ni ọ̀nà pàtàkì tá à ń gbà kéde Ìjọba Ọlọ́run, tọkàntọkàn la fi máa ń lo àwọn ọ̀nà míì láti wàásù fáwọn tí kì í fi bẹ́ẹ̀ gbélé.—Mát. 24:14; Lúùkù 10:1-7; Ìṣí. 14:6.
2. Báwo la ṣe ṣètò fífi fóònù wàásù?
2 Bá A Ṣe Ṣètò Rẹ̀: Bá a ṣe ní ìpínlẹ̀ ìwàásù fún ìwàásù ilé-dé-ilé náà la ní ìpínlẹ̀ ìwàásù fún fífi fóònù wàásù. A lè dá nìkan fi fóònù wàásù, tàbí kí ẹni méjì tàbí mẹ́ta jọ ṣe é. Ibi tá a máa lò fún fífi fóònù wàásù gbọ́dọ̀ jẹ́ ibi tí kò ti sí ariwo àti ohun tó lè pín ọkàn níyà. Àwọn kan ti rí i pé ó ṣàǹfààní láti jókòó sídìí tábìlì kan, wọ́n sì máa ń kó Bíbélì àti àwọn ìtẹ̀jáde tí wọ́n máa ń mú dání tí wọ́n bá ń wàásù láti ilé dé ilé sórí tábìlì náà.
3. Kí ló yẹ ká fi sọ́kàn nígbà tá a bá ń fi fóònù wàásù?
3 Bá A Ṣe Lè fi Fóònù Wàásù: Tó o bá ń fi fóònù wàásù, ó yẹ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ tuni lára, kí ọ̀rọ̀ sì yọ̀ mọ́ ẹ lẹ́nu. Àwọn kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í fi fóònù wàásù lè ka ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ wọn jáde lọ́nà tó tuni lára tó sì já geere. Àwọn ọ̀rọ̀ tá a lè fi bẹ̀rẹ̀ ìwàásù tó wà nínú ìwé Bí A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Awọn Ìjíròrò Bibeli Kí A Sì Máa Báa Nìṣó, Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa àti ìwé àṣàrò kúkúrú náà, Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Òtítọ́? lè ṣèrànwọ́ gan-an. Tó o bá fẹ́ múra ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó o máa lò, wá kókó tó o fẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ dá lé, ronú nípa ìbéèrè tó o lè bi onítọ̀hún lórí kókó náà, kó o sì múra sílẹ̀ láti ka ẹsẹ Bíbélì bíi mélòó kan tó dáhùn ìbéèrè náà. Àwọn ìtẹ̀jáde tá a máa ń lò lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé náà la máa lò. Kíyè sí àwọn kókó yìí: Fara balẹ̀, kó o sì rọra máa sọ̀rọ̀. Sọ̀rọ̀ lọ́nà tó fọ̀wọ̀ hàn, ṣe sùúrù, kó o sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ tuni lára, torí pé àwọn nǹkan yìí máa hàn nínú ohùn rẹ bí onítọ̀hún ṣe ń gbọ́ ẹ. Fetí sílẹ̀ bí ẹni tó ò ń bá sọ̀rọ̀ bá ń sọ èrò rẹ̀, jẹ́ kó mọ̀ pé o gbọ́ ohun tó sọ, kó o sì dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ fún àlàyé tó ṣe. Ṣọ́ra láti má ṣe sọ̀rọ̀ nípa ọrẹ tá a máa ń gbà, torí pé àwọn èèyàn lè rò pé ńṣe lò ń dọ́gbọ́n tọrọ owó látorí fóònù.
4. Kí ni fífi fóònù wàásù á jẹ́ ká lè ṣe ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa?
4 Ó lè jẹ́ pé aláàbọ̀ ara lẹni tó o bá sọ̀rọ̀ lórí fóònù, tàbí kó jẹ́ pé ara rẹ̀ kò yá, ó sì lè jẹ́ ẹni tí iṣẹ́ rẹ̀ mú kó ṣòro láti bá nílé nígbà tá a bá ń wàásù láti ilé dé ilé. Àwọn kan wà tó jẹ́ pé àwọn géètì gìrìwò ni wọ́n fi dáàbò bo ilé wọn, táwọn ẹ̀ṣọ́ sì wà níbẹ̀, ńṣe ni wọ́n ti àwọn ilé mìíràn pa táwọn àlejò kò sì lè wọ ibẹ̀ láìgbàṣẹ. Torí náà, ẹ jẹ́ ká sapá gidigidi láti túbọ̀ tẹra mọ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa ká sì ṣe é kúnnákúnná nípa fífi fóònù wàásù, èyí tó jẹ́ ọ̀nà tó gbéṣẹ́ gan-an.