Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ October 26
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ OCTOBER 26
Orin 200
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
lv-YR àfikún ẹ̀yìn ìwé tó wà lójú ìwé 219 sí 221
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Diutarónómì 11-13
Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
Orin 67
5 min: Àwọn ìfilọ̀.
10 min: Múra Sílẹ̀ Láti Lo Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Ní ṣókí, sọ̀rọ̀ lórí àwọn ìwé ìròyìn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé, kó o sì mẹ́nu ba àwọn àpilẹ̀kọ tó ṣeé ṣe káwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ sí ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín. Ṣàṣefihàn bí òbí kan ṣe ń kọ́ ọmọ rẹ̀ bó ṣe máa múra sílẹ̀ fún iṣẹ́ òjíṣẹ́. Kí òbí náà àti ọmọ rẹ̀ yan àpilẹ̀kọ kan, kí wọ́n jọ yan ìbéèrè àti ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí wọ́n máa lò. Kí ọmọ náà ṣàṣefihàn bó ṣe máa gbé ọ̀rọ̀ rẹ̀ kalẹ̀, kó sì ní kí òbí rẹ̀ fi ọrẹ ṣètìlẹyìn.
10 min: Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Ní káwọn ará sọ àkòrí tí wọ́n ti lò nínú ìwé náà tó gbéṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín. Kí wọ́n sọ ìbéèrè, àwòrán tàbí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí wọ́n máa ń lò nígbà tí wọ́n bá ń fúnni ní ìwé náà. Ṣe àṣefihàn kan.
10 min: Àpótí Ìbéèrè. Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà nínú àpótí náà kó o sì jíròrò wọn.
Orin 70