Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Orí Ìdúró àti Ti Orí Tẹlifóònù
1, 2. Kí la lè ṣe láti kọ́ àwọn tí ọwọ́ wọn dí lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?
1 Ọwọ́ àwọn èèyàn máa ń dí lákòókò tá a wà yìí. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ nínú wọn ló nífẹ̀ẹ́ sáwọn nǹkan tẹ̀mí. Báwo la ṣe lè fún wọn láwọn nǹkan tí wọ́n nílò nípa tẹ̀mí? (Mát. 5:3) Ọ̀pọ̀ akéde ló ti bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lórí ìdúró tàbí lórí tẹlifóònù. Ṣé ìwọ náà á lè fi ìyẹn kún iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ?
2 Ká tó lè bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, a gbọ́dọ̀ ti múra bá a ṣe máa ṣàlàyé ọ̀nà tá à ń gbà ṣe é fáwọn èèyàn, nígbàkigbà tí àǹfààní ẹ̀ bá yọ. Báwo la ṣe lè ṣe é, ibo la sì ti lè ṣe é?
3. Kí nìdí tá a fi gbọ́dọ̀ ṣàlàyé nípa bá a ṣe ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà àkọ́kọ́ tá a bá bá ẹnì kan pàdé, báwo sì la ṣe lè ṣe é?
3 Lórí Ìdúró: Bó o bá bá ẹni tó nífẹ̀ẹ́ sí ìjíròrò Bíbélì pàdé, ṣe ni kó o kàn ṣí ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tó o mú dání sí ìpínrọ̀ tó o ti múra sílẹ̀ dáadáa, irú bí ìpínrọ̀ àkọ́kọ́ nínú ẹ̀kọ́ 1 nínú ìwé pẹlẹbẹ Béèrè, kó o sì bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò. Ka ìpínrọ̀ náà, béèrè ìbéèrè kẹ́ ẹ sì jọ jíròrò ẹyọ kan tàbí méjì lára ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà nínú ìpínrọ̀ náà. Lọ́pọ̀ ìgbà, kì í gbà ju ìṣẹ́jú márùn-ún sí mẹ́wàá lọ láti ṣèyẹn lórí ìdúró, lẹ́nu ọ̀nà níbẹ̀. Bí ẹni yẹn bá lóun gbádùn ìjíròrò náà, ẹ jọ ṣàdéhùn ọjọ́ tó o máa padà lọ láti tún jíròrò ìpínrọ̀ tó tẹ̀lé e tàbí ìpínrọ̀ méjì pàápàá.—Àbá síwájú sí i lórí bá a ṣe lè kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní tààràtà wà nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti January 2002, ojú ìwé 6.
4. Báwo la ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì orí ìdúró nígbà tá a bá ń ṣe ìpadàbẹ̀wò?
4 A lè lo irú ọ̀nà yìí kan náà láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà tá a bá ń ṣe ìpadàbẹ̀wò. Bí àpẹẹrẹ, o lè fi ìwé pẹlẹbẹ Béèrè hàn án, kó o sì sọ̀rọ̀ lórí orúkọ Ọlọ́run, bó ṣe wà nínú ẹ̀kọ́ 2 ìpínrọ̀ 1 àti 2. Nígbà tó o bá padà lọ, o lè jíròrò àlàyé tí Bíbélì ṣe nípa àwọn ànímọ́ Jèhófà bó ṣe wà nínú ìpínrọ̀ 3 àti 4. Nígbà tẹ́ ẹ bá tún pàdé, o lè jíròrò ìpínrọ̀ 5 àti 6 àtàwọn àwòrán tó wà lójú ìwé 5 láti ṣàlàyé fún un bí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe lè jẹ́ kéèyàn mọ Jèhófà. Kò lè pẹ́ téèyàn fi máa ṣe gbogbo ohun tá a sọ yìí lórí ìdúró, lẹ́nu ọ̀nà.
5, 6. (a) Kí nìdí tó fi lè wu àwọn kan láti ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lórí tẹlifóònù? (b) Báwo la ṣe lè sọ fún onílé nípa ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì orí tẹlifóònù?
5 Lórí Tẹlifóònù: Ó ṣeé ṣe káwọn kan nífẹ̀ẹ́ sí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì orí tẹlifóònù ju pé kẹ́ ẹ pàdé lójúkojú lọ. Ìrírí kan rèé: Nígbà tí arábìnrin kan ń wàásù láti ilé dé ilé, ó pàdé adélébọ̀ kan tọ́wọ́ ẹ̀ máa ń dí gan-an lójoojúmọ́. Ìgbà tí arábìnrin yìí ti wá a délé lọ́pọ̀ ìgbà tí kò bá a ló bá bá a sọ̀rọ̀ lórí fóònù. Adélébọ̀ náà sọ pé òun ò ráàyè láti jíròrò nípa Bíbélì. Arábìnrin wa yẹn fèsì pé: “O lè ní ìmọ̀ kún ìmọ̀ láàárín ìṣẹ́jú mẹ́wàá tàbí mẹ́ẹ̀ẹ́dógún péré tá a bá fi jọ sọ̀rọ̀ lórí tẹlifóònù.” Obìnrin náà ní: “Kò burú, bó bá jẹ́ lórí tẹlifóònù ni, ó yá!” Bí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì orí tẹlifóònù ṣe bẹ̀rẹ̀ láìsọsẹ̀ nìyẹn o.
6 Ǹjẹ́ o lè rí lára àwọn tó ò ń ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ wọn tó máa nífẹ̀ẹ́ sí ìkẹ́kọ̀ọ́ orí tẹlifóònù? O lè dá a bí ọgbọ́n bá a ṣe sọ lókè yìí tàbí kó o kàn sọ pé: “Bẹ́ ẹ bá máa nífẹ̀ẹ́ sí i, a lè jọ máa jíròrò Bíbélì lórí tẹlifóònù. Ǹjẹ́ ó máa lè ṣeé ṣe?” Bá a bá ń wá ọ̀nà tó máa rọrùn fún gbogbo èèyàn láti kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, a ó lè mú kí wọ́n “rí ìmọ̀ Ọlọ́run gan-an.”—Òwe 2:5; 1 Kọ́r. 9:23.