ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 8/05 ojú ìwé 3
  • Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
km 8/05 ojú ìwé 3

Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run

Àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ wọ̀nyí la óò gbé yẹ̀ wò nínú àtúnyẹ̀wò aláfẹnusọ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ní ọ̀sẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ní August 29, 2005. Alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ yóò darí àtúnyẹ̀wò yìí fún ọgbọ̀n ìṣẹ́jú, èyí tá a gbé ka àwọn iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ tá a ṣe ní ọ̀sẹ̀ July 4 sí August 29, 2005. [Àkíyèsí: Níbi tí a kò bá ti tọ́ka sí ibi tí a ti mú ìdáhùn jáde lẹ́yìn ìbéèrè kan, o ní láti ṣe ìwádìí fúnra rẹ láti wá ìdáhùn sí ìbéèrè náà.—Wo ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 36 àti 37.]

ÀNÍMỌ́ Ọ̀RỌ̀ SÍSỌ

1. Tá a bá ń sọ ohun tó jẹ́ ìrètí wa fáwọn ẹlòmíràn, báwo la ṣe lè jẹ́ kí ‘ìfòyebánilò wa di mímọ̀ fún gbogbo ènìyàn,’ kí sì nìdí tó fi ṣe pàtàkì? (Fílí. 4:5; Ják. 3:17) [be-YR ojú ìwé 251 ìpínrọ̀ 1 sí 3 àti àpótí]

2. Báwo ni mímọ ìgbà tí kò yẹ ká rin kinkin mọ́ èrò ara wa ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣàṣeyọrí nínú bíbá àwọn tá à ń bá sọ̀rọ̀ lò? [be-YR ojú ìwé 252, ìpínrọ̀ 5 sí ojú ìwé 253, ìpínrọ̀ 1 ]

3. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká lo ìbéèrè lọ́nà tó múná dóko nígbà tá a bá fẹ́ mú kí ẹnì kan ronú lórí kókó kan? [be-YR ojú ìwé 253 ìpínrọ̀ 2 àti 3]

4. Kí ọ̀rọ̀ wa bàa lè yí àwọn èèyàn lọ́kàn padà, àwọn nǹkan wo ló yẹ ká fi sọ́kàn? [be-YR ojú ìwé 255 ìpínrọ̀ 1 sí 4 àti àpótí; ojú ìwé 256 ìpínrọ̀ 1 àti àpótí]

5. Kí ló yẹ ká fi sọ́kàn tá a bá ń lo àfikún ẹ̀rí láti fi hàn pé ọ̀rọ̀ tí Ìwé Mímọ́ sọ bọ́gbọ́n mu? [be-YR ojú ìwé 256 ìpínrọ̀ 3 sí 5 àti àpótí]

IṢẸ́ AKẸ́KỌ̀Ọ́ KÌÍNÍ

6. Àwọn ẹ̀rí tó ṣe kedere wo ló fi hàn pé Jésù wá sáyé rí? [w03-YR 6/15 ojú ìwé 4 sí 7]

7. Báwo ni ‘ẹnu àwọn adúróṣánṣán ṣe máa ń dá wọn nídè,’ báwo sì nilé àwọn olódodo á ṣe “máa bá a nìṣó ní dídúró”? (Òwe 12:6, 7) [w03-YR 1/15 ojú ìwé 30 ìpínrọ̀ 1 sí 3]

8. Bó ti jẹ́ pé kì í ṣe àwọn òfin má-ṣu-má-tọ̀ ló wà nínú Bíbélì, báwo la ṣe lè ‘róye ohun tí ìfẹ́ Jèhófà jẹ́?’ (Éfé. 5:17) [w03-YR 12/1 ojú ìwé 21 ìpínrọ̀ 3 sí ojú ìwé 22 ìpínrọ̀ 2]

9. Àwọn ìlànà Bíbélì wo ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti kojú ipò òṣì? [w03-YR 8/1 ojú ìwé 5 ìpínrọ̀ 3 sí 6]

10. Kí ló yẹ kí àpẹẹrẹ bí Jèhófà ṣe ń fúnni lọ́fẹ̀ẹ́ sún wa láti ṣe? (Mát. 10:8) [w03-YR 8/1 ojú ìwé 20 sí 22]

BÍBÉLÌ KÍKÀ Ọ̀SỌ̀Ọ̀SẸ̀

11. Kí ni ọwọ̀n méjì tí wọ́n ń pè ní Jákínì àti Bóásì tó wà níbi àbáwọlé tẹ́ńpìlì Sólómọ́nì fi hàn? (1 Ọba 7:15-22)

12. Ṣé bí Sólómọ́nì ṣe fún Hírámù ọba ìlú Tírè ní ogún ìlú nílẹ̀ Gálílì bá Òfin Mósè mu? (1 Ọba 9:10-13)

13. Ẹ̀kọ́ wo ni ìwà àìgbọ́ràn tí ẹnì kan tó jẹ́ “ènìyàn Ọlọ́run” hù kọ́ wa? (1 Ọba 13:1-25)

14. Ọ̀nà wo ni Ásà ọba Júdà gbà fi hàn pé òun ní ìgboyà, ẹ̀kọ́ wo nìyẹn sì kọ́ wa? (1 Ọba 15:11-13)

15. Ọ̀nà wo lohun tó ṣẹlẹ̀ láàárín Áhábù ọba àti Nábótì gbà fi ewu tó wà nínú kéèyàn máa káàánú ara rẹ̀ hàn? (1 Ọba 21:1-16)

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́