ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • be ẹ̀kọ́ 48 ojú ìwé 251-ojú ìwé 254 ìpínrọ̀ 2
  • Ọ̀nà Tí Ò Ń Gbà Fèrò Wérò

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọ̀nà Tí Ò Ń Gbà Fèrò Wérò
  • Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Máa Fara Wé Olùkọ́ Ńlá Náà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
  • Ẹ Mú Ìfòyebánilò Dàgbà
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Máa Fòye Báni Lò Bíi Ti Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2023
  • Lílo Ìbéèrè Lọ́nà Tó Múná Dóko
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
Àwọn Míì
Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
be ẹ̀kọ́ 48 ojú ìwé 251-ojú ìwé 254 ìpínrọ̀ 2

Ẹ̀KỌ́ 48

Ọ̀nà Tí Ò Ń Gbà Fèrò Wérò

Kí ló yẹ kí o ṣe?

Ó yẹ kí o lo Ìwé Mímọ́ àti àpèjúwe àti ìbéèrè lọ́nà tó bọ́gbọ́n mu, tó sì máa mú káwọn èèyàn fẹ́ láti fetí sílẹ̀, kí wọ́n sì ronú.

Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì?

Líla ọ̀rọ̀ mọ́lẹ̀ ṣàkó tàbí sísọ̀rọ̀ bí alákatakítí kì í jẹ́ káwọn èèyàn fẹ́ láti fetí sílẹ̀. Àmọ́ sísọ̀rọ̀ lọ́nà tí ń múni ronú jinlẹ̀ máa ń jẹ́ kí ìfọ̀rọ̀wérọ̀ ṣeé ṣe, ó ń jẹ́ káwọn èèyàn lè ronú lé e lórí, á sì jẹ́ kó ṣeé ṣe láti tún rí wọn bá sọ̀rọ̀ lọ́jọ́ míì. Ó lè mú kí wọ́n yí èrò wọn padà pátápátá.

INÚ wa dùn pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń tún ayé wa ṣe. A sì fẹ́ kí ó tún ayé àwọn ẹlòmíràn ṣe pẹ̀lú. Ìyẹn nìkan kọ́ o, a tún mọ̀ pé ìhà táwọn èèyàn bá kọ sí ìhìn rere náà yóò kan bí ọjọ́ ọ̀la wọn yóò ṣe rí. (Mát. 7:13, 14; Jòh. 12:48) Ó wù wá pé kí wọ́n tẹ́wọ́ gba òtítọ́. Àmọ́ ṣá, bí a óò bá kẹ́sẹ járí, kì í ṣe ìgbàgbọ́ lílágbára àti ìtara nìkan ni a óò ní. A óò ní ìfòyemọ̀ pẹ̀lú.

Bí a bá sọ òótọ́ ọ̀rọ̀ jáde lẹ́nu ṣàkó, tí a là á mọ́lẹ̀ pé irọ́ gbuu ni nǹkan tí ẹnì kan gbà gbọ́ tọkàntọkàn, kì í sábàá bọ́ síbi tó dáa lára àwọn èèyàn, kódà bí a tilẹ̀ fi àìmọye ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tì í lẹ́yìn. Bí àpẹẹrẹ, bí a bá kàn bẹnu àtẹ́ lu àwọn àjọ̀dún kan tó lókìkí, tá a sọ pé ọdún abọ̀rìṣà ni, ìyẹn ò ní kí àwọn kan tìtorí ìyẹn ṣíwọ́ ṣíṣe ọdún náà. Àmọ́ fífòyebánilò ni yóò jẹ́ ká túbọ̀ kẹ́sẹ járí. Kí ni fífòyebánilò túmọ̀ sí?

Ìwé Mímọ́ sọ fún wa pé “ọgbọ́n tí ó wá láti òkè . . . lẹ́mìí àlàáfíà, ó ń fòye báni lò.” (Ják. 3:17) Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí a tú sí “fòye báni lò” níhìn-ín túmọ̀ ní ṣangiliti sí “jíjuwọ́sílẹ̀.” Àwọn ìtumọ̀ kan pè é ní “gbígbatẹnirò,” “ṣe ẹ̀tọ́,” tàbí “ní ìpamọ́ra.” Ṣàkíyèsí pé ìfòyebánilò tan mọ́ jíjẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà. Ní Títù 3:2, a mẹ́nu kàn án pa pọ̀ pẹ̀lú ìwà tútù, a sì fi hàn pé òdì kejì rẹ̀ ni jíjẹ́ aríjàgbá. Fílípì 4:5 rọ̀ wá pé ká jẹ́ kí àwọn èèyàn mọ̀ wá sí ẹni tí ‘ń fòye báni lò.’ Afòyebánilò máa ń ro ti irú èèyàn tẹ́nì kan jẹ́ látilẹ̀wá, ipò tó yí onítọ̀hún ká àti ipa tí ọ̀rọ̀ tí òun máa sọ yóò ní lára ẹni tí òun ń bá sọ̀rọ̀. Ó múra tán láti juwọ́ sílẹ̀ bó bá bójú mu láti ṣe bẹ́ẹ̀. Bíbá àwọn èèyàn lò lọ́nà yẹn á jẹ́ kí wọ́n fara balẹ̀ gbọ́ ọ̀rọ̀ wa ní àgbọ́yé nígbà tá a bá ń fèrò wérò pẹ̀lú wọn látinú Ìwé Mímọ́.

Ibi Tó Yẹ Kí O Ti Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀. Lúùkù òpìtàn nì, ròyìn pé nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù wà ní Tẹsalóníkà, ó lo Ìwé Mímọ́, “ó ń ṣàlàyé, ó sì ń fi ẹ̀rí ìdánilójú hàn nípasẹ̀ àwọn ìtọ́ka pé ó pọndandan kí Kristi jìyà, kí ó sì dìde kúrò nínú òkú.” (Ìṣe 17:2, 3) Kíyè sí i pé inú sínágọ́gù àwọn Júù ni Pọ́ọ̀lù ti ṣe èyí. Àwọn tó ń bá sọ̀rọ̀ gbà pé òótọ́ lọ̀rọ̀ inú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù. Ó dáa bó ṣe fi ohun tí wọ́n tẹ́wọ́ gbà bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀.

Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń bá àwọn Gíríìkì sọ̀rọ̀ lókè Áréópágù nílùú Áténì, kò ti orí Ìwé Mímọ́ bẹ̀rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, orí àwọn nǹkan tí wọ́n mọ̀, tí wọ́n sì tẹ́wọ́ gbà ló ti bẹ̀rẹ̀. Ó wá ti orí nǹkan wọ̀nyí bọ́ sórí ọ̀ràn nípa Ẹlẹ́dàá àti ète Rẹ̀.—Ìṣe 17:22-31.

Àìmọye èèyàn ni kò ka Bíbélì kún láyé tá a wà yìí. Ṣùgbọ́n ṣàṣà lẹni tó máa sọ pé wàhálà ilé ayé kò kan òun. Ìyẹn làwọn èèyàn fi ń wá ìgbé ayé rere. Bó o bá kọ́kọ́ fi hàn pé o bìkítà nípa àwọn ohun tó ń bá àwọn èèyàn fínra, tí o sì wá fi ohun tí Bíbélì sọ nípa rẹ̀ hàn wọ́n, irú ìgbatẹnirò bẹ́ẹ̀ lè sún wọn fetí sí ohun tí Bíbélì sọ nípa ète Ọlọ́run fáráyé.

Àwọn ìgbàgbọ́ àti àṣà kan lè wà lára ohun tí akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan jogún lọ́dọ̀ àwọn òbí rẹ̀. Wàyí o, akẹ́kọ̀ọ́ náà wá rí i pé Ọlọ́run kórìíra ìgbàgbọ́ àti àṣà wọ̀nyẹn, ó sì jáwọ́ nínú wọn nítorí ẹ̀kọ́ tó kọ́ nínú Bíbélì. Báwo ni akẹ́kọ̀ọ́ yìí yóò ṣe wá ṣàlàyé ìpinnu tó ṣe yìí fáwọn òbí rẹ̀? Wọ́n lè kà á sí pé àwọn gan-an ló pa tì nítorí pé ó kúrò nínú ẹ̀sìn táwọn bí i sí. Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà lè ronú pé kí òun tó bẹ̀rẹ̀ fífi Bíbélì ṣàlàyé ìdí tí òun fi ṣe ìpinnu yìí, òun á kọ́kọ́ fi àwọn òbí òun lọ́kàn balẹ̀ pé òun nífẹ̀ẹ́ wọn, òun sì bọ̀wọ̀ fún wọn.

Ìgbà Tó Yẹ Kí O Juwọ́ Sílẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọwọ́ Jèhófà ni gbogbo ọlá àṣẹ wà, síbẹ̀ ó ń fòye báni lò gidigidi. Nígbà tí Jèhófà fẹ́ gba Lọ́ọ̀tì àti ìdílé rẹ̀ là kúrò nínú ìparun tó dojú kọ Sódómù, àwọn áńgẹ́lì Jèhófà rọ̀ ọ́ pé: “Sá lọ sí ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá kí a má bàa gbá ọ lọ!” Ṣùgbọ́n Lọ́ọ̀tì bẹ̀bẹ̀ pé: “Bẹ́ẹ̀ kọ́, jọ̀wọ́, Jèhófà!” Ó bẹ̀bẹ̀ pé kí wọ́n jẹ́ kí àwọn sá lọ sílùú Sóárì. Jèhófà gba ti Lọ́ọ̀tì rò, ó jẹ́ kó ṣe bó ti wí; ìyẹn ló fi jẹ́ pé nígbà tí àwọn ìlú ńlá yòókù ṣègbé, a dá ìlú Sóárì sí. Àmọ́, nígbà tó yá, Lọ́ọ̀tì wá ṣe ohun tí Jèhófà kọ́kọ́ sọ fún un. Ó ṣí lọ sí ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá náà. (Jẹ́n. 19:17-30) Jèhófà mọ̀ pé ohun tí òun sọ ló tọ́, ṣùgbọ́n ó mú sùúrù fún Lọ́ọ̀tì títí òye ohun tí òun sọ fi yé Lọ́ọ̀tì.

Ó yẹ kí àwa náà máa fòye báni lò, bí a bá fẹ́ kí àárín àwa àtàwọn ẹlòmíràn gún. Ó lè dá wá lójú gbangba pé ẹni yẹn ni kò tọ̀nà, a sì ti lè ronú kan àwọn ẹ̀rí tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ tí a ó fi gbe ọ̀rọ̀ wa lẹ́sẹ̀. Ṣùgbọ́n nígbà mìíràn, ó sàn kéèyàn má fa ọ̀rọ̀ náà rárá. Fífòyebánilò kò túmọ̀ sí fífi ìlànà Jèhófà báni dọ́rẹ̀ẹ́. O kàn lè dúpẹ́ lọ́wọ́ onítọ̀hún pé ó sọ tinú rẹ̀ jáde, tàbí kí o kàn tiẹ̀ gbójú fo àwọn àṣìṣe tó wà nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ṣíṣàì wonkoko mọ́ àwọn àṣìṣe rẹ̀ á jẹ́ kí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ náà dá lórí ohun tó mọ́yán lórí. Kódà bó bá bẹnu àtẹ́ lu ohun tó o gbà gbọ́, ṣe sùúrù. O lè béèrè ìdí tó fi rò bẹ́ẹ̀. Tẹ́tí sí ìdáhùn rẹ̀. Èyí á jẹ́ kí o mọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀. Èyí tún lè ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún ìjíròrò alárinrin lọ́jọ́ iwájú.—Òwe 16:23; 19:11.

Jèhófà fún èèyàn láǹfààní láti yan ohun tó wù ú. Ó gbà wọ́n láyè láti lo ànímọ́ yìí, bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń ṣì í lò. Gẹ́gẹ́ bí aṣojú Jèhófà, Jóṣúà ròyìn bí Ọlọ́run ṣe bá Ísírẹ́lì lò. Ṣùgbọ́n ó wá fi kún un pé: “Wàyí o, bí ó bá burú ní ojú yín láti máa sin Jèhófà, lónìí yìí, ẹ yan ẹni tí ẹ̀yin yóò máa sìn fún ara yín, yálà àwọn ọlọ́run tí àwọn baba ńlá yín tí wọ́n wà ní ìhà kejì Odò tẹ́lẹ̀ sìn ni tàbí àwọn ọlọ́run àwọn Ámórì ní ilẹ̀ àwọn ẹni tí ẹ̀ ń gbé. Ṣùgbọ́n ní tèmi àti agbo ilé mi, Jèhófà ni àwa yóò máa sìn.” (Jóṣ. 24:15) Iṣẹ́ tá a gbé lé wa lọ́wọ́ lónìí ni láti jẹ́ “ẹ̀rí,” a sì ń fi ìdánilójú jẹ́ ẹ. Àmọ́, a kì í fi túláàsì mú àwọn èèyàn láti gba ọ̀rọ̀ wa gbọ́. (Mát. 24:14) Wọ́n ní ẹ̀tọ́ láti yan ohun tí wọ́n fẹ́. A ò sì gbọ́dọ̀ fi ẹ̀tọ́ yẹn dù wọ́n.

Máa Béèrè Ìbéèrè. Jésù fi àpẹẹrẹ títayọ lélẹ̀ nínú fífèròwérò pẹ̀lú àwọn èèyàn. Ó máa ń gba ti ipò wọn rò. Ó sì máa ń lo àpèjúwe tó máa tètè yé wọn. Ó tún máa ń lo ìbéèrè lọ́nà tó múná dóko. Èyí jẹ́ káwọn èèyàn láǹfààní láti sọ̀rọ̀ kí ohun tó wà lọ́kàn wọn lè hàn síta. Èyí tún jẹ́ kí wọ́n fẹ́ láti gbé ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń jíròrò lọ́wọ́ yẹ̀ wò.

Ọkùnrin kan tó jẹ́ ògbóǹtagí nínú Òfin bi Jésù pé: “Olùkọ́, nípa ṣíṣe kí ni èmi yóò fi jogún ìyè àìnípẹ̀kun?” Jésù kúkú lè dá a lóhùn ní tààràtà. Àmọ́ ó fẹ́ kí ọkùnrin náà sọ tinú rẹ̀. Ó bi í pé: “Kí ni a kọ sínú Òfin? Báwo ni ìwọ ṣe kà á?” Ọkùnrin náà dáhùn lọ́nà tó tọ́. Ṣé torí pé ìdáhùn rẹ̀ tọ́, ọ̀rọ̀ ti parí nìyẹn? Ó tì o. Jésù jẹ́ kí ọkùnrin náà máa bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ. Ìbéèrè tí ọkùnrin náà wá béèrè sì fi hàn pé ó ka ara rẹ̀ sí olódodo. Ó béèrè pé: “Ní ti gidi ta ni aládùúgbò mi?” Dípò kí Jésù bẹ̀rẹ̀ sí ṣàlàyé ohun tí aládùúgbò jẹ́, Jésù ní kí ó gba àkàwé kan rò. Bó bá ṣe pé àlàyé nípa aládùúgbò ni Jésù jókòó tì ni, ọ̀rọ̀ Jésù lè má tà létí ọkùnrin náà, nítorí irú ojú tí àwọn Júù lápapọ̀ fi ń wo àwọn Kèfèrí àtàwọn ará Samáríà. Àkàwé yẹn dá lórí ará Samáríà kan, tó jẹ́ aládùúgbò rere, tó wá ran arìnrìn àjò kan lọ́wọ́ lẹ́yìn tí olè jà á, tí wọ́n tún lù ú. Bẹ́ẹ̀ rèé, àlùfáà àti ọmọ Léfì tó kọ́kọ́ gbabẹ̀ kọjá kọ̀ láti ran ẹni náà lọ́wọ́. Ìbéèrè kékeré kan tí Jésù béèrè jẹ́ kí òye àpèjúwe yẹn yé ọkùnrin náà. Ọ̀nà tí Jésù gbé àlàyé rẹ̀ gbà jẹ́ kí ọ̀rọ̀ náà “aládùúgbò” ní ìtumọ̀ tuntun létí ọkùnrin yìí. (Lúùkù 10:25-37) Ẹ ò rí i pé àpẹẹrẹ yìí dáa láti tẹ̀ lé! Dípò tí yóò fi jẹ́ pé ìwọ nìkan lò ń dá gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ sọ, tí á sì wá dà bíi pé o ò jẹ́ kí ẹni tó ò ń bá sọ̀rọ̀ lo làákàyè rẹ̀, kọ́ bá a ṣe ń lo ìbéèrè àti àpèjúwe tó gbámúṣé láti fi mú kí olùgbọ́ rẹ ronú.

Ṣàlàyé Ìdí Ọ̀rọ̀. Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nínú sínágọ́gù ní Tẹsalóníkà, kì í ṣe pé ó kàn ka ìwé tí àwọn olùgbọ́ rẹ̀ gbà pé ó jẹ́ òótọ́ nìkan ni. Lúùkù ròyìn pé Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé, ó fẹ̀rí tì í, ó sì sọ ìtumọ̀ ohun tó kà. Ìyọrísí rẹ̀ ni pé “àwọn kan lára wọ́n di onígbàgbọ́, wọ́n sì dara pọ̀ mọ́ Pọ́ọ̀lù àti Sílà.”—Ìṣe 17:1-4.

Gbogbo èèyàn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ ló lè jàǹfààní nínú irú ọ̀nà ìfèròwérò bẹ́ẹ̀. Ì báà jẹ́ àwọn ẹbí lò ń jẹ́rìí fún, tàbí àwọn tẹ́ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́ tàbí àwọn tẹ́ ẹ jọ ń lọ síléèwé, tàbí àjèjì kan pàápàá, nígbà tó o bá wà lóde ẹ̀rí, tàbí nígbà tó o bá ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tàbí nígbà tó o bá ń sọ ọ̀rọ̀ tí wọ́n yàn fún ọ láti sọ nínú ìjọ, wọ́n á jàǹfààní níbẹ̀. Nígbà tó o bá ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan, ó lè yé ọ yékéyéké ṣùgbọ́n kí ó má fi bẹ́ẹ̀ yé àwọn ẹlòmíràn. Tó o bá kàn kó àlàyé palẹ̀, àlàyé rẹ tàbí bó o ṣe lo ẹsẹ náà lè dún bíi pé ńṣe lo kàn ń fagídí ṣe àyímọ́. Ǹjẹ́ kò ní dáa kí o fa àwọn ọ̀rọ̀ pàtàkì inú ẹsẹ náà yọ, kí o sì wá ṣàlàyé wọn? Ǹjẹ́ o lè fẹ̀rí ti ọ̀rọ̀ rẹ, bóyá kí o fa irú ẹ̀rí bẹ́ẹ̀ yọ látinú àlàyé tó yí ọ̀rọ̀ náà ká tàbí látinú ẹsẹ mìíràn tó sọ̀rọ̀ lórí kókó yẹn? Ǹjẹ́ àpèjúwe kan lè fi hàn pé ọ̀rọ̀ rẹ bọ́gbọ́n mu? Ǹjẹ́ ìbéèrè lè jẹ́ kí àwùjọ túbọ̀ ronú lórí ọ̀ràn náà? Fífèròwérò lọ́nà yẹn á jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wa tà létí àwọn èèyàn, á sì jẹ́ kí wọ́n máa ronú jinlẹ̀ lórí ohun tá a bá sọ.

BÍ O ṢE LÈ ṢE É

  • Nígbà tó o bá ń ronú lórí bó o ṣe fẹ́ bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ, rántí irú ẹni tí àwọn olùgbọ́ rẹ jẹ́ látilẹ̀wá àti ìṣarasíhùwà wọn.

  • Má sọ pé gbogbo àṣìṣe tó wà nínú ọ̀rọ̀ wọn lo gbọ́dọ̀ gbé jáde.

  • Fi ìdánilójú sọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n tún rántí pé gbogbo èèyàn ló ní òmìnira kan náà tí ìwọ ní láti gba ohun tó wù wọ́n gbọ́.

  • Dípò kíkù gìrì dáhùn ìbéèrè, o lè fi ìbéèrè mìíràn tàbí àwọn àpèjúwe ran oníbèéèrè lọ́wọ́ láti ronú lórí ọ̀ràn náà.

  • Sọ fífèròwérò lórí Ìwé Mímọ́ dàṣà, nípa ṣíṣàlàyé àwọn ọ̀rọ̀ pàtàkì, nípa títọ́ka sí àlàyé tó yí ọ̀rọ̀ náà ká tàbí àwọn ẹsẹ mìíràn tó jẹ́ kí ìtumọ̀ rẹ̀ ṣe kedere, tàbí nípa lílo àpẹẹrẹ tó máa jẹ́ káwọn èèyàn mọ bí wọ́n ṣe lè mú ẹsẹ náà lò.

ÌDÁNRAWÒ: (1) Lẹ́yìn tó o bá jẹ́rìí fún ẹnì kan tó wonkoko mọ́ èrò rẹ̀, ṣe àyẹ̀wò bí ìfọ̀rọ̀wérọ̀ náà ṣe lọ sí. Ẹ̀rí wo lo fi ti ọ̀rọ̀ rẹ lẹ́yìn? Àpèjúwe wo lo lò? Àwọn ìbéèrè wo lo béèrè? Báwo lo ṣe fi hàn pé o gba ipò àtilẹ̀wá onítọ̀hún rò àti bí nǹkan ṣe ń rí lára rẹ̀? Bí èyí ò bá ṣeé ṣe fún ọ lóde ẹ̀rí, gbìyànjú láti fi dánra wò pẹ̀lú akéde mìíràn. (2) Ṣe ìfidánrawò bí o ṣe máa fèrò wérò pẹ̀lú ẹnì kan (ojúgbà rẹ tàbí ọmọdé kan) tí ń gbèrò àtiṣe ohun tí kò tọ́.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́