ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 8/05 ojú ìwé 2-3
  • Àwọn Ìfilọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìfilọ̀
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
km 8/05 ojú ìwé 2-3

Àwọn Ìfilọ̀

◼ Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tá a ó lò lóṣù August: Èyíkéyìí nínú àwọn ìwé pẹlẹbẹ olójú ewé 32 yìí ni kẹ́ ẹ lò: Akoso Naa Ti Yoo Mu Paradise Wá, Ẹmi Awọn Oku—Wọn Ha Le Ran Ọ Lọwọ Tabi Pa Ọ Lara Bi? Wọn Ha Wa Niti Gidi Bi?, Gbádùn Iwalaaye lori Ilẹ Ayé Titilae!, Ìwé Kan Tí Ó Wà fún Gbogbo Ènìyàn, Iwọ Ha Nilati Gbàgbọ́ Ninu Mẹtalọkan Bí?, Ìwọ Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run!, Ki Ni Ète Igbesi-Aye? Bawo Ni Ìwọ Ṣe Le Rí I?, Kí Ní Ń Ṣẹlẹ̀ sí Wa Nígbà Tí A Bá Kú?, Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú, Orukọ Atọrunwa naa Tí Yoo Wà Titilae, Ọlọ́run Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi?, Ọ̀nà Tó Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun—Ṣé O Ti Rí I? àti “Sawo O! Emi Nsọ Ohun Gbogbo Di Ọtun.” September: Ìwé Sún Mọ́ Jèhófà la ó lò. Ẹ sì lè lo ìwé Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì tàbí ìwé pẹlẹbẹ Ẹ Máa Ṣọ́nà bí àfirọ́pò. October: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! ni kẹ́ ẹ lò jálẹ̀ oṣù náà. Báwọn èèyàn bá fìfẹ́ hàn, ẹ jọ̀wọ́ ẹ fún onílé ní ìwé pẹlẹbẹ Béèrè. Bẹ́ ẹ bá sì ń padà lọ, kẹ́ ẹ ní in lọ́kàn láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé. November: Ẹ lo ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà. Báwọn kan bá sọ pé àwọn kì í ṣe òbí, ẹ fún wọn ní ìwé Ìmọ̀ tàbí ìwé àṣàrò kúkúrú náà Ṣé Wàá Fẹ́ Mọ Púpọ̀ Sí I Nípa Bíbélì?

◼ Níwọ̀n bí oṣù October ti ní òpin ọ̀sẹ̀ márùn-ún, ó máa jẹ́ oṣù tó túbọ̀ rọrùn láti ṣiṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́.

◼ Kí alábòójútó olùṣalága tàbí ẹnì kan tó bá yàn ṣàyẹ̀wò àkáǹtì ìjọ ní September 1 tàbí bó bá ti lè yá tó lẹ́yìn náà. Bí ẹ bá ní àkáǹtì mìíràn tẹ́ ẹ̀ ń tọ́jú owó sí fún bíbójútó Gbọ̀ngàn Ìjọba tàbí kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun, kó ṣàyẹ̀wò èyí pẹ̀lú. Bó bá ti ṣe èyí, ẹ ṣèfilọ̀ rẹ̀ fún ìjọ lẹ́yìn tí ẹ bá ti ka ìròyìn ìnáwó ti oṣù tó ń bọ̀.

◼ Ní August 31, 2005 tàbí bí ó bá ti lè yá tó lẹ́yìn náà, kí ẹ ka gbogbo ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ àti ìwé ìròyìn tó wà lọ́wọ́, bá a ti ń ṣe lọ́dọọdún. Ìṣirò yìí jọ èyí tí olùṣekòkáárí ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ máa ń ṣe lóṣooṣù nípa kíka àwọn ìwé náà lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan. Kẹ́ ẹ kọ iye tí wọ́n jẹ́ sórí fọ́ọ̀mù Literature Inventory (S-18). Ẹ ní kí (àwọn) ìránṣẹ́ tó ń bójú tó ìwé ìròyìn sọ àròpọ̀ iye ìwé ìròyìn tó wà lọ́wọ́ fún yín. Kí akọ̀wé ìjọ tó ń ṣe kòkáárí bójú tó ìṣirò ọlọ́dọọdún náà. Akọ̀wé àti alábòójútó olùṣalága ìjọ tó ń ṣe kòkáárí ni kó fọwọ́ sí fọ́ọ̀mù náà. Gbogbo ìjọ tó ń ṣe kòkáárí yóò gba fọ́ọ̀mù Literature Inventory (S-18) mẹ́ta-mẹ́ta. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ fi ẹ̀dà àkọ́kọ́ ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì, ó pẹ́ tán ní September 6. Ẹ tọ́jú ẹ̀dà kejì sínú fáìlì yín. Ẹ lè lo ẹ̀dà kẹta láti fi ṣírò ìwé tó wà lọ́wọ́.

◼ Ike Pẹlẹbẹ Àtẹ́tísí Tuntun Tó Wà:

Sún Mọ́ Jèhófà (ike pẹlẹbẹ mọ́kànlá ló wà nínú rẹ̀)—Gẹ̀ẹ́sì

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́