ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 1 Àwọn Ọba 21
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé 1 Àwọn Ọba

      • Ọgbà àjàrà Nábótì wọ Áhábù lójú (1-4)

      • Jésíbẹ́lì fa ikú Nábótì (5-16)

      • Iṣẹ́ tí Èlíjà jẹ́ fún Áhábù (17-26)

      • Áhábù rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ (27-29)

1 Àwọn Ọba 21:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 19:17, 18

1 Àwọn Ọba 21:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 25:23; Nọ 36:7

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    4/2017, ojú ìwé 24

    Ilé Ìṣọ́,

    2/1/2014, ojú ìwé 13

    8/1/1997, ojú ìwé 13

1 Àwọn Ọba 21:5

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “tí ìbànújẹ́ fi bá ẹ̀mí rẹ.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 16:31; 18:4; 19:2; 21:25

1 Àwọn Ọba 21:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mik 2:1; 7:3

1 Àwọn Ọba 21:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ne 9:38; Ẹst 8:8
  • +Di 16:18

1 Àwọn Ọba 21:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 20:16; Di 17:6
  • +Ẹk 22:28
  • +Le 24:16; Jo 10:33

1 Àwọn Ọba 21:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Emọ 5:12; Hab 1:4
  • +2Ọb 9:25, 26; Onw 4:1

1 Àwọn Ọba 21:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Onw 5:8; 8:14; Hab 1:13

1 Àwọn Ọba 21:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 21:7

1 Àwọn Ọba 21:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 17:1

1 Àwọn Ọba 21:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 16:29

1 Àwọn Ọba 21:19

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “gba ohun ìní rẹ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 4:8, 10
  • +Di 5:21; Hab 2:9
  • +1Ọb 22:37, 38; 2Ọb 9:25, 26

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    2/1/2014, ojú ìwé 15

1 Àwọn Ọba 21:20

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “O ti ta ara rẹ.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 18:17; Emọ 5:10
  • +1Ọb 16:30

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    2/1/2014, ojú ìwé 14-15

1 Àwọn Ọba 21:21

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ẹnikẹ́ni tó ń tọ̀ sára ògiri.” Ọ̀rọ̀ Hébérù tí wọ́n fi ń pẹ̀gàn àwọn ọkùnrin.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 10:7, 17
  • +2Ọb 9:7-9

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    2/1/2014, ojú ìwé 15

1 Àwọn Ọba 21:22

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 15:25-29
  • +1Ọb 16:3, 11

1 Àwọn Ọba 21:23

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 9:10, 35

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jeremáyà, ojú ìwé 120-121

1 Àwọn Ọba 21:24

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 14:11; 16:4

1 Àwọn Ọba 21:25

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ta ara rẹ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 16:30
  • +1Ọb 16:31; 2Kr 22:2, 3; Ifi 2:20

1 Àwọn Ọba 21:26

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ó ṣeé ṣe kí ọ̀rọ̀ Hébérù yìí ní í ṣe pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń lò fún “ìgbẹ́,” wọ́n sì máa ń lò ó fún ohun tí wọ́n bá kórìíra.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 23:28; Di 9:5

1 Àwọn Ọba 21:27

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “aṣọ àpò ìdọ̀họ.”

  • *

    Ní Héb., “aṣọ àpò ìdọ̀họ.”

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    2/1/2014, ojú ìwé 15

1 Àwọn Ọba 21:29

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 78:34
  • +2Ọb 9:25, 26; 10:7, 11

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    10/2021, ojú ìwé 3

    Ilé Ìṣọ́,

    2/1/2014, ojú ìwé 15

Àwọn míì

1 Ọba 21:1Joṣ 19:17, 18
1 Ọba 21:3Le 25:23; Nọ 36:7
1 Ọba 21:51Ọb 16:31; 18:4; 19:2; 21:25
1 Ọba 21:7Mik 2:1; 7:3
1 Ọba 21:8Ne 9:38; Ẹst 8:8
1 Ọba 21:8Di 16:18
1 Ọba 21:10Ẹk 20:16; Di 17:6
1 Ọba 21:10Ẹk 22:28
1 Ọba 21:10Le 24:16; Jo 10:33
1 Ọba 21:13Emọ 5:12; Hab 1:4
1 Ọba 21:132Ọb 9:25, 26; Onw 4:1
1 Ọba 21:14Onw 5:8; 8:14; Hab 1:13
1 Ọba 21:151Ọb 21:7
1 Ọba 21:171Ọb 17:1
1 Ọba 21:181Ọb 16:29
1 Ọba 21:19Jẹ 4:8, 10
1 Ọba 21:19Di 5:21; Hab 2:9
1 Ọba 21:191Ọb 22:37, 38; 2Ọb 9:25, 26
1 Ọba 21:201Ọb 18:17; Emọ 5:10
1 Ọba 21:201Ọb 16:30
1 Ọba 21:212Ọb 10:7, 17
1 Ọba 21:212Ọb 9:7-9
1 Ọba 21:221Ọb 15:25-29
1 Ọba 21:221Ọb 16:3, 11
1 Ọba 21:232Ọb 9:10, 35
1 Ọba 21:241Ọb 14:11; 16:4
1 Ọba 21:251Ọb 16:30
1 Ọba 21:251Ọb 16:31; 2Kr 22:2, 3; Ifi 2:20
1 Ọba 21:26Ẹk 23:28; Di 9:5
1 Ọba 21:29Sm 78:34
1 Ọba 21:292Ọb 9:25, 26; 10:7, 11
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
  • 28
  • 29
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
1 Àwọn Ọba 21:1-29

Àwọn Ọba Kìíní

21 Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, ọ̀ràn kan ṣẹlẹ̀ tó dá lórí ọgbà àjàrà Nábótì ará Jésírẹ́lì. Ọgbà náà wà ní Jésírẹ́lì+ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ààfin Áhábù ọba Samáríà. 2 Áhábù sọ fún Nábótì pé: “Fún mi ní ọgbà àjàrà rẹ kí n lè fi ṣe ibi tí màá máa gbin nǹkan sí torí pé ẹ̀gbẹ́ ilé mi ló wà. Màá fún ọ ní ọgbà àjàrà tí ó dára ju ìyẹn lọ láti fi rọ́pò rẹ̀. Tí o bá sì fẹ́, màá fún ọ ní owó rẹ̀.” 3 Àmọ́ Nábótì sọ fún Áhábù pé: “Jèhófà ò ní fẹ́ gbọ́ rárá pé mo fi ogún àwọn baba ńlá mi+ fún ọ.” 4 Torí náà, Áhábù wá sínú ilé rẹ̀, ó dì kunkun, ó sì dorí kodò nítorí èsì tí Nábótì ará Jésírẹ́lì fún un, nígbà tó sọ pé: “Mi ò ní fún ọ ní ogún àwọn baba ńlá mi.” Ó wá dùbúlẹ̀ sórí ibùsùn rẹ̀, ó gbé ojú sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, ó kọ̀, kò jẹun.

5 Jésíbẹ́lì+ ìyàwó rẹ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Kí ló dé tí inú rẹ fi bà jẹ́* débi pé o ò jẹun?” 6 Ó dá a lóhùn pé: “Torí mo sọ fún Nábótì ará Jésírẹ́lì pé, ‘Fún mi ní ọgbà àjàrà rẹ kí n san owó rẹ̀. Tí o bá sì fẹ́, jẹ́ kí n fún ọ ní ọgbà àjàrà míì dípò rẹ̀.’ Àmọ́, ó sọ pé, ‘Mi ò ní fún ọ ní ọgbà àjàrà mi.’” 7 Jésíbẹ́lì ìyàwó rẹ̀ sọ fún un pé: “Ìwọ kọ́ lò ń ṣàkóso lórí Ísírẹ́lì ni? Dìde, jẹun, kí o sì jẹ́ kí inú rẹ dùn. Màá fún ọ ní ọgbà àjàrà Nábótì ará Jésírẹ́lì.”+ 8 Torí náà, ó kọ àwọn lẹ́tà ní orúkọ Áhábù, ó gbé èdìdì ọba+ lé e, ó sì fi àwọn lẹ́tà náà ránṣẹ́ sí àwọn àgbààgbà+ àti àwọn èèyàn pàtàkì tó ń gbé ní ìlú Nábótì. 9 Ó kọ ọ́ sínú àwọn lẹ́tà náà pé: “Ẹ kéde ààwẹ̀, kí ẹ sì ní kí Nábótì jókòó sí iwájú gbogbo àwọn èèyàn náà. 10 Kí ẹ ní kí ọkùnrin méjì tí wọ́n jẹ́ aláìníláárí jókòó síwájú rẹ̀, kí wọ́n sì ta kò ó+ pé, ‘O ti sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run àti sí ọba!’+ Lẹ́yìn náà, kí ẹ mú un jáde, kí ẹ sì sọ ọ́ lókùúta pa.”+

11 Torí náà, àwọn ọkùnrin ìlú rẹ̀, àwọn àgbààgbà àti àwọn èèyàn pàtàkì tó ń gbé ìlú rẹ̀ ṣe ohun tó wà nínú lẹ́tà tí Jésíbẹ́lì fi ránṣẹ́ sí wọn. 12 Wọ́n kéde ààwẹ̀, wọ́n sì ní kí Nábótì jókòó síwájú gbogbo àwọn èèyàn náà. 13 Ni méjì lára àwọn ọkùnrin aláìníláárí bá wọlé, wọ́n jókòó síwájú rẹ̀, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í ta ko Nábótì níwájú àwọn èèyàn náà, wọ́n ní: “Nábótì ti sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run àti sí ọba!”+ Lẹ́yìn náà, wọ́n mú un lọ sí ẹ̀yìn ìlú, wọ́n sì sọ ọ́ lókùúta pa.+ 14 Wọ́n wá ránṣẹ́ sí Jésíbẹ́lì pé: “A ti sọ Nábótì lókùúta pa.”+

15 Gbàrà tí Jésíbẹ́lì gbọ́ pé wọ́n ti sọ Nábótì lókùúta pa, ó sọ fún Áhábù pé: “Dìde, lọ gba ọgbà àjàrà Nábótì ará Jésírẹ́lì,+ tí ó kọ̀ láti tà fún ọ, nítorí Nábótì kò sí láàyè mọ́. Ó ti kú.” 16 Bí Áhábù ṣe gbọ́ pé Nábótì ti kú, ó dìde, ó sì lọ sí ọgbà àjàrà Nábótì ará Jésírẹ́lì láti gbà á.

17 Àmọ́ Jèhófà bá Èlíjà+ ará Tíṣíbè sọ̀rọ̀, ó ní: 18 “Dìde, lọ pàdé Áhábù ọba Ísírẹ́lì tó wà ní Samáríà.+ Ó wà nínú ọgbà àjàrà Nábótì, níbi tí ó ti lọ gbà á. 19 Kí o sọ fún un pé, ‘Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “O ti pa ọkùnrin yìí+ o sì ti sọ nǹkan ìní rẹ̀ di tìrẹ,* àbí?”’+ Kí o wá sọ fún un pé, ‘Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Ibi tí àwọn ajá ti lá ẹ̀jẹ̀ Nábótì, ni àwọn ajá ti máa lá ẹ̀jẹ̀ rẹ.”’”+

20 Áhábù sọ fún Èlíjà pé: “O ti wá mi kàn, ìwọ ọ̀tá mi!”+ Ó dáhùn pé: “Mo ti wá ọ kàn. ‘Nítorí o ti pinnu* láti máa ṣe ohun tó burú lójú Jèhófà,+ 21 màá mú àjálù bá ọ, màá gbá ọ dà nù bí ẹni gbálẹ̀, màá sì pa gbogbo ọkùnrin* ilé Áhábù run,+ títí kan àwọn aláìní àti àwọn aláìníláárí ní Ísírẹ́lì.+ 22 Màá sì ṣe ilé rẹ bí ilé Jèróbóámù+ ọmọ Nébátì àti bí ilé Bááṣà+ ọmọ Áhíjà, nítorí o ti mú mi bínú, o sì ti mú kí Ísírẹ́lì ṣẹ̀.’ 23 Ní ti Jésíbẹ́lì, Jèhófà sọ pé: ‘Àwọn ajá ló máa jẹ Jésíbẹ́lì lórí ilẹ̀ tó wà ní Jésírẹ́lì.+ 24 Èèyàn Áhábù èyíkéyìí tí ó bá kú sí ìlú ni àwọn ajá yóò jẹ, èyí tí ó bá sì kú sí pápá ni àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run yóò jẹ.+ 25 Ó dájú pé kò sí ẹni tó dà bí Áhábù,+ ẹni tó ti pinnu* láti máa ṣe ohun tó burú lójú Jèhófà, ẹni tí Jésíbẹ́lì+ ìyàwó rẹ̀ ń tì gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n. 26 Ó hùwà ìríra tó burú jáì, torí ó tẹ̀ lé àwọn òrìṣà ẹ̀gbin,* bí gbogbo àwọn Ámórì ti ṣe, àwọn tí Jèhófà lé jáde kúrò níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.’”+

27 Bí Áhábù ṣe gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ó fa ẹ̀wù ara rẹ̀ ya, ó sì gbé aṣọ ọ̀fọ̀* wọ̀; ó gbààwẹ̀, ó ń sùn lórí aṣọ ọ̀fọ̀,* ó sì ń rìn kiri nínú ìbànújẹ́. 28 Nígbà náà, Jèhófà bá Èlíjà ará Tíṣíbè sọ̀rọ̀, ó ní: 29 “Ṣé o rí bí Áhábù ṣe rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ nítorí mi?+ Torí pé ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ níwájú mi, mi ò ní mú àjálù náà wá nígbà ayé rẹ̀. Ìgbà ayé ọmọ rẹ̀ ni màá mú àjálù náà wá sórí ilé rẹ̀.”+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́